Gbenga Daniel di adari ipolongo fun Atiku

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ogun tẹle, Ọtunba Gbenga Daniel, ti di alaakoso agba fun eto ipolongo igbakeji aarẹ tẹlẹ lorileede yii, Alaaji Abubakar Atiku.

Ninu lẹta ti Atiku ko, to si buwo lu lo ti kede pe daniel ni yoo wa nidii gbogbo eto to ba je mo ipolongo, ikede, bi owo yoo se wole fun lilo egbe, bi won yoo se na an ati awon ti yoo kopa ninu eto idibo abele. Eleyii ko yo kiko awon alatileyin re jọ sile.

Atiku ni oun gbe igbese lati yan an nitori iriri ti okunrin naa ni. O salaye pe yoo wulo pupo fun egbe ipolongo oun, bee ni yoo si din wahala oun ku, yoo si fun oun lanfaani lati se awon nnkan mi inn nigba ti eto oselu ba fona soju.

Ni nnkan bii ọsẹ meloo kan sẹyin ni Alaaji Abubakar Atiku wa ṣe ipade pọ pẹlu Ọtunba Gbenga Daniel nile ẹ to wa ni Ṣagamu, nibi tawọn olori ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba ti peju pesẹ.

(38)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.