Gbajabiamila, è é ṣe?

Spread the love

Bi ile igbimọ aṣofin to wa lode bayii ba kógbásílé lọdun to n bọ, nigba naa ni yoo di ẹẹkẹrin ti Fẹmi Gbajabiamila lati agbegbe Suurulere, l’Ekoo, ti n lọ sile igbimọ naa, iyẹn ni pe o ti lo ọdun mẹrindinlogun gbako nile igbimọ aṣofin. Iyẹn lo ṣe ya awọn mi-in lẹnu pe o ti tun fi orukọ ara rẹ silẹ pe oun tun fẹẹ lọ lẹẹkanrun-un, lawọn kan ba dide lati adugbo rẹ pe ṣe ẹnu rẹ nikan ni wọn n ba re Ọyọ ni, diẹ to ninu nnkan oni-nnkan, eyi toun naa ṣe to, ko lọọ jokoo, ko wa iṣẹ mi-in ṣe. Ṣebi lọọya loun naa, ṣe oun ko fẹẹ lọ si kootu lọọ rojọ rara ni, afi ko jokoo si ile igbimọ aṣofin nibi ti yoo ti maa gba miliọnu miliọnu, tẹnikan ko si ni i gbọ nnkan kan. Ṣe ẹ ri i, bo ba jẹ ilu oyinbo ni, eeyan le lo ogun ọdun, ko lo ọgbọn ọdun paapaa, nitori lọdọ tiwọn, iṣẹ ilu ni wọn n ṣe. Owo ti aṣofin ibẹ n gba, owo awọn oṣiṣẹ ijọba onipo kekere ni. Iyẹn lo ṣe jẹ pe awọn ti wọn ba fẹẹ ṣiṣẹ ilu tootọ ni wọn n lọ sibẹ, ki i ṣe owo ni wọn n ba lọ. Amọ ti Naijiria ko ri bẹẹ, oun ni orilẹ-ede to jẹ awọn aṣofin ibẹ lo n gba owo julọ ni gbogbo agbaye, ko sẹni ti yoo de ile aṣofin ti Naijiria ti yoo fẹẹ jade mọ, bẹẹ ni ki i ṣe nitori ofin ti wọn fẹẹ ṣe, tabi nitori ifẹ araalu ti wọn kuku ni to bẹẹ, nitori owo to n jade nibẹ ni. Owo to to owo lo n jade nibẹ, owo ti awọn eeyan naa ko le ri nidii iṣẹ mi-in laelae, nigba ti eeyan ba n ṣe iṣẹ ti ki i ṣe iṣẹ aṣelaagun, to si n gba bii miliọnu mẹẹẹdogun laarin oṣu kan. Nibi iṣẹ wo leeyan ti fẹẹ ri owo oṣu tabi ere to to bẹẹ gba! Kaluku lo ti waa mọ pe ijẹ lasan ni ipo oṣelu ni Naijiria, iyẹn naa lẹnikan ko ṣe gbọdọ sọ pe dandan ni ki oun ku sibẹ, awọn to ku naa gbọdọ jẹun. Itiju ni yoo jẹ fun Fẹmi Gbajabiamila nigba ti awọn kan ba n ba a ja laduugbo rẹ pe eyi to ṣe to, nitori bi wọn ko ba wi fun un, o yẹ ki oun naa ti mọ, oun funra rẹ paapaa iba si ṣe daadaa bo ba jẹ o ti ṣeto ẹni ti oun yoo fa kalẹ lati ọdọ wọn. Ṣugbọn awọn oloṣelu tiwa ki i ṣe bẹẹ, ko sẹnikan ti i foyin sẹnu ti i tutọ ẹ danu, ko soloṣelu ti yoo fi ibi to ti n gba miliọnu miliọnu silẹ fẹnikan. Ṣugbọn ki Fẹmi wa iṣẹ mi-in ṣe, eyi toun naa ṣe nibẹ yẹn to gẹẹ.

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.