Gba woro-woro, iya rẹ n gbadun ni yara, gba woro-woro!

Spread the love

Orin ti wọn n kọ ni Naijiria nigba kan ree, orin gba-woroworo. Iṣere ọmọde ni wọn n pe ni woroworo, awọn abiyamọ lo maa n ra a ki ọmọ wọn le ri nnkan fi ṣere. Bi ọmọde kan ba wa to n daamu iya rẹ, to n ke ti ko jẹ ki obinrin naa ṣe ohun to fẹẹ ṣe, iṣere ọmọde yii ni wọn yoo gbe le e lọwọ, woroworo! Nibi to ti n fi kinni naa ṣere, to fi n pariwo, ni yoo ti gbagbe sun lọ, iya rẹ yoo si raaye ṣe gbogbo ohun to ba fẹẹ ṣe. Ariwo to gba ilu kankan, paapaa lọdọ awọn oniroyin, ni pe nitori Ọṣinbajo ni wọn ko ṣe gbe fulaagi ẹgbẹ APC le ẹni ti Amosun fẹ lọwọ, to jẹ Dapọ Abiọdun, ọmọ Rẹmo bii ti Igbakeji Aarẹ naa ni wọn fun. Wọn ni awọn APC ni ohun ti Igbakeji Aarẹ yii ba fẹ lawọn gbọdọ ṣe, nitori ipo pataki lo wa ninu ijọba. Ẹ gbọ, ṣe iyẹn lo fi ipo pataki ti Ọṣinbajo wa ninu ijọba Buhari han, ki oun ati Gomina Ibikunle Amosun jọ maa fa nnkan mọ ara wọn lọwọ yẹn ni yoo jẹ ka mọ pe ọkunrin naa lagbara loootọ. Iru agbara wo niyẹn. Ṣebi agbara naa lo bọ sodi yii, ti Amosun loun ko ni i jẹ ki wọn dibo fun Dapọ Abiọdun gẹgẹ bii gomina, ṣugbọn oun yoo jẹ ki wọn dibo fun Buhari gẹgẹ bii aarẹ, ati oun funra oun gẹgẹ bii sẹnetọ, lorukọ ẹgbẹ APC. Iwa basejẹ, daleru-daleru wo lo tun ju bẹẹ lọ. Apọnle wo ni Ọṣinbajo funra rẹ si ri gba ninu iyẹn. Bo tilẹ jẹ pe alaṣeju ni Amosun, iwa ẹni ti i kọ idi sita to n tọ sinu ile lo si n hu, imura lati ba ti ẹgbẹ to gbe e wọle jẹ ni ipinlẹ Ogun lo mura si, sibẹ, ko si ohun to le mu Ọṣinbajo niyi loju awọn araalu ju ohun ti ijọba Buhari ba tori rẹ ṣe ninu eto idagbasoke si ilẹ Yoruba lọ. Ebi n pa wa, titi ti a n tọ lojoojumọ bajẹ, o n pa wa, ko si ilọsiwaju kan ti a le tọka si, ko si nnkan rere kan ti Ọṣinbajo gba lọwọ awọn eeyan yii wa fun wa, ẹni kan waa ni wọn fun un ni gomina ipinlẹ Ogun, ẹni to ba fẹ ni ko mu wa. Ṣe ọrọ niyẹn, ṣe nnkan gidi kan niyẹn. Asiko ibo to n bọ la oo mọ ẹni ti agbara wa lọwọ rẹ, boya Amosun alaṣeju ni abi Ọṣinbajo alainikan-an-ṣe, abi awọn araalu tawọn mejeeji n fiya jẹ. Ẹ ṣa jokoo sibẹ kẹ ẹ maa tan ara yin, o digba naa na.

 

 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.