Francis lo n ba awọn eeyan wa ọmọ ọdọ l’Ekoo, oun naa lo n kọ wọn ki wọn maa ji ẹru ọga wọn

Spread the love

Adefunkẹ Adebiyi

Bi ẹnikẹni ba nilo ọmọ ọdọ lawọn agbegbe bii Ikẹja, Ọjọta, Oṣodi, Surulere abi ibi yoowu to ba ṣaa ti jẹ Mainland, nipinlẹ Eko, ọkunrin kan wa to maa n pese wọn fawọn to nilo wọn, Francis Okputu lo n jẹ. O kan waa jẹ pe bo ṣe n ba wọn wa ọmọ ọdọ naa lo n kọ awọn ọmọ ọhun bi wọn yoo ṣe ja awọn ọga wọn lole owo ati goolu, ohun to ṣe laipẹ yii tawọn RRS fi mu un n’Iyana Ipaja niyẹn.

Ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni Francis, iṣẹ alagbafọ lo n ṣe tẹlẹ gẹgẹ boun funra ẹ ṣe wi. Nigba ti bukaata rẹ kọja ohun ti agbafọ le ka lo bẹrẹ okoowo biba awọn eeyan mu ọmọ ọdọ wa lati ilẹ Ibo.

Owo akọkọ tawọn ọmọ ọdọ naa ba gba lọdọ ọga wọn, Francis yoo gba idaji nibẹ, ọmọ naa yoo si maa gba odidi owo ẹ lọ lẹyin igba yẹn.

Nibi tawọn eeyan ti mọ ọn de ninu iṣẹ ọmọ ọdọ yii, awọn eeyan to ku diẹ kaato fun maa n mu ọmọ wa fun un funra wọn, Francis yoo si ba wọn wa ile ọga to lowo lọwọ ti ọmọ naa yoo ti maa ṣe ọmọọdọ lọ. O kere tan, laarin ọdun kan, ọmọọdọ mẹẹẹdogun lo ni oun maa n bawọn eeyan wa.

Ole to mu mọ ọn lawọn eeyan ko ti i mọ nipa ẹ, afi nigba to mu ọmọbinrin kan, Joy Onoz, wa lati ilẹ Ibo pe ko maa waa ṣiṣẹ lọdọ obinrin olowo kan laipẹ yii.

Joy bẹrẹ iṣẹ lọdọ ọga ẹ yii, ṣugbọn ko pẹ to bẹrẹ iṣẹ naa lo pe Francis pe ọga oun yii ko fẹran oun, bi yoo ṣe da oun pada sibi toun ti wa lo n wa. O ni ki Francis waa ba oun wa nnkan ṣe si i. Nigba naa ni Francis ni anfaani lati mọ pe olowo gidi lọgaa Joy, o si bẹrẹ si i wa ọna ti yoo fi wọle si i lara nipaṣẹ ọmọ yii.

Lọjọ ti Francis yoo kọ ọmọ yii pe ko ji owo ọga ẹ ati goolu foun kawọn si jọ pin in, niṣe lo paṣẹ fun ọmọbinrin naa pe ko gbọdọ sọ oyinbo boun ṣe n pe e lori foonu yii o, titi toun yoo fi pari ohun toun fẹẹ ba a sọ, ede ilu awọn ni ko fi maa da oun loun, ki ẹnikẹni ma baa gbọ ohun toun n ba a sọ. Nitori awo lohun toun fẹẹ sọ fun un naa.

Ohun to sọ fọmọ ọdọ naa ni pe ko wa ọna ti yoo fi ji goolu ọga ẹ, ko si ji owo Dọla rẹpẹtẹ si i, ko mu fọto mama naa si i pẹlu. Ko ko wọn waa ba oun n’Iyana Ipaja, nibi tawọn yoo ti jọ pin in. O fi kun un fun un pe mama naa ko ni i ba a wijọ kankan o, nitori oun ti ṣeto bi igbagbe yoo ṣe mu iya yii pẹlu fọto ẹ yẹn, ti ko tiẹ ni i ranti beere goolu ẹ lọwọ Joy, koda to ba mọ pe oun lo ji i pẹlu owo.

Ṣugbọn ọmọ ọdọ naa ko fẹẹ ṣe bẹẹ fọga to ni ko fẹran oun tẹlẹ yii, bi iya naa yoo ṣe fẹran ẹ lo n wa, iyẹn lo ṣe lọọ sọ ohun ti Francis sọ fun un fun mama olowo. Wọn fọrọ naa to ọlọpaa leti, Joy si ṣe akọsilẹ ohun ti ẹni to ba a waṣẹ ni ko ṣe lọdọ awọn agbofinro.

Lati ri abaniwaṣẹ yii mu ṣinkun, ọga Joy ko goolu fun un pẹlu owo Dọla, o ni ko lọọ pade Francis n’Iyana-Ipaja, iyẹn naa si kuku ti n duro de e nibẹ, ko mọ pe awọn RRS ti wọn ti gbọ sọrọ naa wa nitosi, nibi to ti n gbowo ati goolu ni wọn ti mu un.

Iye owo goolu ti Joy ko lọ fun Francis jẹ ẹgbẹrun lọna irinwo ataabọ Naira (450,000). Owo Dọla to si tẹwọ gba jẹ mẹẹẹdogun($15), gbogbo ẹ naa lawọn ọlọpaa ba lọwọ ẹ bi wọn ṣe n mu un.

Nitori ohun to ṣẹlẹ yii, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Zubairu Muazu, ti kilọ fawọn eeyan ti wọn n gba ọmọ ọdọ lati maa ṣọra ṣe ni gbogbo ọna, ki wọn si mọ ẹni to fẹẹ ba wọn mu ọmọ ọdọ wa daadaa. O ni ki wọn maa huwa daadaa sawọn ọmọ ọdọ, kawọn ọmọ naa le ṣe daadaa si wọn pada.

Ni ti Francis Otukpu, ko ni i pẹ foju bale-ẹjọ bi wọn ṣe wi.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.