Francis ji ọkada n’Ibadan, nibi to ti n gbe e sa lọ lo ti lasidẹnti

Spread the love

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọrọ Yoruba kan lo sọ pe Ọlọrun igba kan lo maa n pẹ ko too dajọ, ṣugbọn laye ode oni, loju ẹsẹ lo n ṣedajọ aṣebi. Bẹẹ gẹgẹ lo ṣe gba ọna iyanu mu ọmọ Ibo kan to n jẹ Francis Chukwudi laarin iṣẹju bii mẹta lẹyin to fipa gba ọkada lọwọ ọlọkada n’Ibadan.

Francis ti ko ju ẹni ọdun  mejilelogun (22) lọ pẹlu ọrẹ ẹ kan to n jẹ Tobi ni wọn jọ da ọlọkada naa duro ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ti iyẹn si gbe wọn lai mọ pe ogbologboo ole ni wọn.

Ọna adugbo ti ero ki i pọ si ni wọn ni ki ọlọkada yii gbe awọn lọ. Bi wọn ṣe de ojú-ọlọmọ-ò-tó-o ni wọn sọ fun un pe ko sọ awọn kalẹ, ọmọ Hausa naa ko si ti i duro tan ti wọn ti rọjo iya fun un, ti wọn si fipa gba alupupu to fi n ṣiṣẹ aje lọwọ ẹ.

Ṣugbọn nibi ti wọn ti n fi ọkada ọhun sare buruku lọ ni wọn ti lasidẹnti loju ọna laarin igboro, ti Francis ko si le da dide nilẹ nitori ti eegun ẹsẹ rẹ ti da. Ati oun ati ọkọda ti wọn ji gbe, Tobi ko duro wo eyikeyii ninu wọn nilẹ to fi sa lọ ni tiẹ, ṣe afọwọfọnna kan ki i gbọwọ duro.

Nigba ti akọroyin wa n fọrọ wa a lẹnu wo, afurasi ole yii ṣalaye bi oun ati Tobi ṣe jale ọhun ati ọna tọwọ awọn ọlọpaa gba tẹ oun, o ni, “Tobi lo ni ki n jẹ ka lọọ jale ọkada. A waa da ọlọkada duro ni Mọkọla, (n’Ibadan), lọ si Oke Itunu. Loju ọna la ti gba ọkada lọwọ ẹ. Lilu la lu u ka too gba ọkada lọwọ ẹ, ki i ṣe pe a ni nnkan ija lọwọ.

“Tobi lo gun ọkada yẹn lẹyin ta a gba a tan. Nibi ta a ti n gbe e sa lọ la ti lasidẹnti lori biriiji ni Mọkọla. Tobi waa sa lọ.

“Ọlọkada kan to n kọja lọ ni mo bẹ pe ko jọwọ, ran mi lọwọ nibi ti mo jokoo si nigba ta a lasidẹnti. O gbe mi lọ si ile mi.

 “Ọlọkada to gbe mi lọ sile atawọn to n ṣe aajo mi nibi ti mo ti lasidẹnti ko mọ boya emi ni mo ni ọkada tabi emi kọ, wọn ṣaa gbe e lọ si agọ ọlọpaa.

“Mo n tọju ara mi lọwọ ninu ile lawọn ọlọpaa de. Awọn eeyan Hausa ta a ja lole ni wọn lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa ni teṣan. Mo ro pe ọlọkada to gbe mi lọ sile lo pada lọ si agọ ọlọpaa lati ba mi gba maṣinni mi wa sile, ko mọ pe awọn to ni maṣinni ti lọọ fẹjọ sun ni teṣan, bi awọn ọlọpaa ṣe waa mu mi nile niyẹn.

Mo kọkọ purọ fun wọn pe mi o ki i ṣe ole. Ṣugbọn wọn pe ọlọkada ta a ja lole lati waa pade mi ni teṣan lati tako mi.”

Gẹgẹ bi iwadii awọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale ni ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso CSP Oluṣọla Arẹmu ṣe fidi ẹ mulẹ, afurasi ole yii wa lara awọn adigunjale to n yọ awọn olugbe Ibadan lẹnu, o si ti ba wọn kopa ninu ọpọ idigunjale ṣaaju ọkada ti wọn tori ẹ mu un.

Francis funra ẹ fidi eyi mulẹ nigba to jẹwọ f’ALAROYE pe aimọye igba loun ti ba awọn akẹgbẹ oun lọọ ja awọn eeyan lole ọkọ ayọkẹlẹ atawọn dukia mi-in.

Ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun to pera ẹ lọmọ bibi ilu Nyala, nipinlẹ Enugu, yii ṣalaye pe “ọrẹ mi kan to n jẹ Boy (Peter Izuchukwu Adike) lo mu mi loọ jale akọkọ. O ni oun mọ adugbo ta a ti fẹẹ jale yẹn daadaa, ati pe iya ta a fẹẹ lọọ ja lole nikan lo n da gbe inu ile yẹn.

“Emi pẹlu ẹ la jọ lọ ṣiṣẹ yẹn. Bi obinrin yẹn ṣe ri i lo pariwo ẹ nitori iya yẹn da a mọ. Boy waa ni ko panu ẹ mọ. Lẹyin naa la fi aṣọ so iya yẹn lọwọ ati ẹsẹ, ka too ko gbogbo ẹru ta a fẹẹ ko nibẹ.”

Wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ lọkunrin ọmọ Ibo yii pẹlu awọn akẹgbẹ ẹ fẹran lati maa fipa gba lọwọ awọn eeyan ti wọn ba lọọ ka mọle. Bẹẹ ni wọn maa n fipa ba obinrin ti wọn ba ba nibẹ laṣepọ ki wọn too lọ. Ṣugbọn jagunlabi sọ pe oun ki i ba wọn lọwọ ninu ọro a n fipa ba obinrin sun ni toun.

O ni, “iya yẹn sọ fun awọn ọlọpaa pe a ba oun sun, ṣugbọn mi o mọ nipa ẹ nitori iwaju ile yẹn lemi duro si, mo n ṣọ ita boya awọn eeyan n bọ. Ohun ti mo kan mọ ni pe lẹyin ta a ko ẹru tan, Boy lọọ wẹ nileewẹ iya yẹn. Mo ni ki lo de to n wẹ ni iru ibẹ yẹn, o ni oun ni lati wẹ ka too kuro nibẹ.

Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Shina Olukolu, fidi ẹ mulẹ pe ṣaaju lọwọ awọn agbofinro ti tẹ Peter Izechukwu Adike (Boy) ọkan ninu awọn akẹgbẹ Francis nidii idigunjale, pẹlu meji ninu awọn ti wọn n ta ẹru ti wọn ba ji ko fun. Orukọ awọn yẹn ni Abdul-Rahmon Ibrahim ati Salisu Abubakar.

Bẹẹ ni CP Olukolu ṣeleri lati gbe awọn mejeeji lọ sile-ẹjọ fun ẹsun idigunjale, ifipabanilopọ atawọn iwa ọdaran mi-in ti iwadii fidi ẹ mulẹ pe wọn ti hu ṣaaju.

(46)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.