Franca to ji miliọnu kan aabọ ọga ẹ gbe l’Ekoo lọjọ to bẹrẹ iṣẹ ti wa lahaamọ

Spread the love
Franca Amaha, ọmọ-ọdọ to ji owo ọga ẹ l’Ekoo

Adefunkẹ Adebiyi

Iwa gbewiri ti ọmọbinrin kan to n jẹ Franca Amaha hu si ọga ẹ to gba a siṣẹ ọmọọdọ ni Surulere ti sọ ọ dero atimọle bayii, awọn agbofinro ti i mọ gbaga latoṣu to kọja to ti huwa ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ṣẹṣẹ mu Franca, Kọmandi ọlọpaa nipinlẹ Eko ṣẹṣẹ foju ẹ han sode lọsẹ to kọja yii ni.

Gẹgẹ bi alaye awọn agbofinro, ọmọ ọdun mẹrinlelogun pere ni Franca, ṣugbọn bo ṣe kere to yii lo gbona ninu ole jija, to bẹẹ to fi jẹ pe lọjọ to bẹrẹ iṣẹ ọmọọdọ lọdọ obinrin kan ti wọn n pe ni Taiye, ni Masha, Surulere, nipinlẹ Eko, lo ti ji owo nla gbe ninu yara iyẹn. Bẹẹ, ẹgbọn Taiye to de lati ilu oyinbo lọjọ naa lo ni owo ọhun.

Gẹgẹ bi ọmọbinrin yii funra ẹ ṣe ṣalaye, o ni ki i ṣe igba akọkọ oun ree toun yoo ṣe ọmọọdọ l’Ekoo, o loun ti ba obinrin kan ṣiṣẹ ri n’Isọlọ, to jẹ ọga oun naa foun sileewe poli ipinlẹ Eko, pe koun ṣe Diploma nibẹ.

O loun ti n kawe ọhun lọ o, oun n fi apa kan ṣe ọmọọdọ naa, ṣugbọn nigba to ya lobinrin naa ti i ṣe iyawo ọga ọlọpaa nigba kan, Mike Okiro, bẹrẹ si i binu soun, to si maa n fi gbogbo igba sọ pe oun n pẹẹ de ju lati ileewe, oun ko ṣiṣẹ ile daadaa mọ.

Ọrọ to n sọ soun naa lara oun ko gba, boun ṣe binu kuro nibẹ niyẹn lẹyin ọdun meji, loun ba lọọ n ṣiṣẹ aṣẹwo, eyi si jẹ ọdun 2014 toun kọkọ wa s’Ekoo lati ilu awọn ti i ṣe Cross River, Calabar.

Ọmọbinrin yii ṣalaye pe nigba tawọn ara abule awọn gbọ pe aṣẹwo loun n ṣe l’Ekoo, wọn binu, awọn ẹgbọn oun si ni koun maa pada bọ kia, boun ṣe pada sabule niyẹn, toun lọọ n ṣiṣẹ oko.

O loun tun wa s’Ekoo lẹyin igba naa, oun tun ṣe ọmọọdọ n’Ikorodu, oun tun pada siluu awọn ko too di pe oun tun de pada lọdun yii, toun si lọọ ba ọkunrin kan to n jẹ Frank pe ko ba oun waṣẹ ọmọọdọ. O ni Frank lo mu oun lọọ ba ẹnikan ti wọn n pe ni Ade, iyẹn lo si fa oun le ọga oun to n jẹ Taiye yii lọwọ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun yii.

‘Ayederu orukọ ni mo fi silẹ lọdọ ẹni to ba mi waṣẹ, bẹẹ naa ni mo ṣe fun ọga mi naa lorukọ ti ki i ṣe temi. Bi mo ṣe de ọdọ ọga tuntun yii lo ti ṣalaye fun mi nipa ara ẹ, ẹsẹkẹsẹ ni mo si ti ni i lọkan pe mo maa gbe e lowo nla sa lọ tabi ki n ji ohunkohun to ba ṣaa maa lowo lori lọdọ ẹ.

‘Ọsan ọjọ yẹn naa la lọọ gbe ẹgbọn ẹ to de lati ilu oyinbo, mo tẹle ọga mi de papakọ ofurufu. Ninu yara alejo to ko awọn baagi ẹ si ni mo ti tu awọn ẹru naa ti mo ji awọn owo ilu oyinbo to wa nibẹ. Mo ṣẹ Dọla ọlọgọrun-un kan, mo ṣe irun mi nibẹ, mo si ra bata tuntun.

‘Mo ṣẹ awọn owo yooku n’Ikoyi, mo si ko o si akaunti mi.  Mo fẹẹ fowo yẹn toju iya mi ti ara ẹ ko ya ni, ohun to jẹ ki n jale niyẹn. Ẹ ba mi bẹ wọn, mi o ni i ṣe bẹẹ mọ’

Bẹẹ ni Franca to pe ara e ni Esther fọgaa atawọn to ba a waṣẹ sọ.’

Ajah, nile ọkan ninu awọn ọrẹ ẹ, lawọn ọlọpaa ti ri Franca mu lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ti n wa a. Kootu ni ọrọ naa yoo kangun si, ẹwọn si nijiya ọmọọdọ to jale naa, gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe sọ.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.