Foonu ti Sodeeq ji l’Oṣogbo ladajọ fi ran an lẹwọn oṣu mẹfa

Spread the love

Mudashiru Sodeeq, ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn lo ti farahan niwaju adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo, lori ẹsun pe o ji foonu ti owo rẹ din diẹ lẹgbẹrun lọna ogoji Naira (#36,500).

 

Ṣe ni Sodeeq n ṣẹju pako ninu gbaga ile-ẹjọ to duro si, bẹẹ lo si n tẹwọ pẹbẹ lati bẹ adajọ pe ki wọn ṣiju aanu wo oun, oun ko ni i ṣan aṣọ iru ẹ ṣoro mọ.

 

Bi wọn ṣe ka ẹsun ile-fifọ ati ole-jija ti wọn fi kan an si i leti, kia lo ni oun jẹbi, niwọn igba ti ko kuku ni agbẹjọro kankan to n gbẹnusọ fun un, o ni ṣe ni kile-ẹjọ ṣaanu oun.

 

Ṣaaju ni agbefọba to n wadii ọrọ Sodeeq, Ọlayiwọla Rasaq ti sọ funle-ẹjọ pe ninu oṣu kọkanla, ọdun to kọja, ni olujẹjọ lọ si agbegbe Oke-Abeṣu, niluu Oṣogbo, nibi to ti lọọ huwa naa.

 

Ọlayiwọla ṣalaye pe Sodeeq wọ sọọbu Lasisi Muideen lọjọ naa, nibi to ti ji foonu Infinix kan, o tun mu kaadi foonu to jẹ ẹgbẹrun mejila Naira ati owo to le ni ẹgbẹrun mọkanla Naira. Apapọ nnkan to ji ọhun si din diẹ lẹgbẹrun lọna ọgọta Naira, eleyii to nijiya labẹ abala irinwo o di mẹwaa (390) ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.

 

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Majisreeti naa, Mary Awodele, pạṣe pe ki Sodeeq lọọ faṣọ penpe roko-ọba fun oṣu mẹfa gbako, tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna mẹwaa Naira.

 

Ninu iroyin mi-in, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti wọ Yakubu Saheed, ẹni ogoji ọdun, lọ sile-ẹjọ lori ẹsun pe o ji tẹlifiṣan ati kọmputa alaagbeka lotẹẹli kan niluu Oṣogbo.

 

Saheed ni wọn lo wọnu otẹẹli Mingles to wa lagbegbe Kọju Foam, nibi to ti ji tẹlifisan Plasma mẹta, eyi ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna irinwo (400) Naira ati kọmputa alaagbeka ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna marunlelogoji Naira.

 

Arabinrin Ṣoyẹmi Bọsẹ to jẹ agbefọba lori ẹsun naa sọ funle-ẹjọ pe Sunday Okunọla ati Amusa Lukman lo ni awọn nnkan ti Saheed ji lootẹẹli yii, ijiya si wa fun iru ẹṣẹ bẹẹ ninu ori kẹrinlelọgbọn, abala kọkanla, iwe ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.

 

Agbẹjọro fun olujẹjọ, A.O. Emmanuel, rọ ile-ẹjọ lati faaye beeli silẹ fun Saheed pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.

 

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Olubunmi Ajanaku faaye beeli silẹ fun olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira ati oniduuro meji ni iye kan naa.

 

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọgunjọ, oṣu keji, ọdun yii

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.