Fẹla gbe motọ, oun atawọn iyawo ẹ, wọn ko matiraasi ati pilo, wọn ni ọdọ Ọbasanjọ lawọn fẹẹ maa gbe bayii o

Spread the love

Loootọ ni Fẹla jokoo si Ikẹja lẹyin to ti Ghana de, ṣugbọn nnkan ko rọgbọ fun ọkunrin olorin naa rara ni. Awọn iyawo lo lọ rẹpẹtẹ yii, awọn oṣere lo pọ jabura yii, bẹẹ gbogbo wọn jọ n gbe oju kan naa ni. Awọn ibi ti wọn iba ti maa ṣere ti iba mu owo wọle, ijọba ologun igba naa ko jẹ, wọn ko si fi Fẹla ati awọn ọmọ rẹ lọrun silẹ, bi wọn ti n le wọn nibi ni wọn n le wọn lọhun-un, o jọ pe wọn ti pinnu lati ba ti ọkunrin oṣere naa jẹ patapata. Eyi to waa mu inira pupọ dani fun Fẹla ni pe owo ti ile-ẹjọ sọ pe ki ijọba san fun un, wọn ko san an fun un. Ṣe Adajọ Dosunmu ti dajọ pe ki wọn fun ọkunrin olorin naa ni nnkan to jọju, ki ijọba sanwo fun un, ki wọn si san ẹsan awọn nnkan rẹ ti wọn ti bajẹ, paapaa ile rẹ ti wọn dana sun fun un, ṣugbọn ijọba ko dahun, wọn ko ṣe bii ẹni ti yoo san kọbọ kan fun Fẹla.
Boya bo ba jẹ wọn sanwo fun un, ti wọn si ba a tun ile rẹ ṣe, boya nnkan iba dẹrun fun ọkunrin naa, yoo si sinmi lati maa ba ijọba fa wahala. Nigba ti wọn ko waa sanwo fun un yii nkọ, ti ko si si owo ti yoo maa fi gbọ bukata oriṣiiriṣii to wa ni iwaju rẹ, ti iṣẹ aje to n ṣe ko si tun lọ deede nitori ti ijọba n di i lọwọ nidii awọn okoowo rẹ to mọ-ọn ṣe, iyẹn naa si ni iṣẹ orin. Ohun ti ijọba n sọ ni pe nibi ti Fẹla ba wa ati awọn ọmọ rẹ, ija maa n ṣẹlẹ nibẹ, wọn si maa n huwa ipanle to maa n mu ipalara wa fawọn eeyan, awọn ko si fẹ ohun ti yoo ba aye awọn ọmọde ati ọdọ jẹ lawujọ. Irọ ni awọn ijọba ṣọja yii n pa o, wọn mọ pe ki i ṣe bẹẹ lọrọ ri, loootọ awọn ọmọ Fẹla le, ṣugbọn wọn ki i tọ ẹni ti ko ba tọ wọn, bẹẹ ni wọn ki i jale, otẹẹli tabi ile wọn ti wọn ba wa naa ni wọn maa n gbe, wọn ki i deede jade sita.
Nnkan tilẹ ti yatọ pata fun awọn obinrin rẹ, nitori wọn ki i mura bii ọmọọta, tabi bii ọmọ Fẹla lasan mọ, niṣe ni wọn n mura bii iyawo tootọ, ti awọn naa yoo si maa rin pẹlu idara-ẹni-loju to lagbara, ọkan wọn balẹ, wọn si mọ pe ko si ọkunrin kan to le ṣe mẹẹsi sawọn, nitori awọn ko jẹ ọmọ Fẹla mọ, Misis Anikulapo Kuti, lawọn n jẹ, iyawo Fẹla lawọn. Imura iyawo ile ni wọn n mu bi wọn ba n jade, yatọ si ti wọn ba n lọ si ode ere wọn ti wọn yoo wọ aṣọ penpe penpe bii aṣọ eṣinṣin, aṣọ ijo lasan si ni. Bo ba ṣe pe nigba naa ni Fẹla ri owo tọju awọn iyawo rẹ ni, ti awọn iyawo rẹ naa si ṣiṣẹ ti wọn jọ n ṣe ti wọn gba owo to ba kan wọn, aye awọn ọmọ naa yoo yipada si daadaa, nitori wọn ti n huwa ti gbogbo iyawo ile n hu. Amọ ko si owo rara, wọn ko raaye ṣe iṣẹ aje wọn. Iyẹn lo tun jẹ ki Fẹla binu lọjọ kan.
Ni ọjọ kọkanla, oṣu kẹrin, ọdun 1978, Fẹla tun mura lati ba ijọba Ọbasanjọ fa wahala gidi. Ohun to ṣẹlẹ ni pe Fẹla n ṣe fiimu kan lọwọ nigba ti wọn fi lọọ dana sun ile rẹ yii, orukọ fiimu naa ni ‘Black President’. O ti ṣe fiimu naa de ọna jinjin, o si ti nawo lori rẹ gan-an. Awọn ṣọja ti wọn waa dana sun ile rẹ yii ji lara fiimu yii, wọn si dana sun awọn mi-in, wọn ṣa ba gbogbo ohun to ti na owo iyebiye le lori yii jẹ. Nigba naa, fiimu ṣiṣe ki i ṣe owo kekere rara, ṣe aye ko ti i laju to bayii, ki i ṣe aye fidio, ko si si ẹni ti i lọ soko fiimu bi ko ba si owo nla lọwọ rẹ. Nitori pe Fẹla lowo lọwọ lo ṣe dana kinni naa, o si ti ya fiimu naa ni Ghana, wọn ya a ni Naijiria, awọn oyinbo rẹpẹtẹ ni wọn ya a, awọn pupọ ninu awọn oyinbo yii ni wọn si n ba Fẹla kakakiri ibi gbogbo to ba n lọ.
Owo kekere kọ ni lati maa ko awọn oyinbo rin nigba ti a n sọ yii, ṣugbọn bẹẹ ni wọn pọ lọdọ Fẹla lati ya fiimu yii, ti kaluku si n gba owo wọn. Ko too di inu oṣu keji, ọdun 1977, ti wọn sun ile Fẹla yii, wọn ti ya fiimu naa tan, ki wọn pa gbogbo rẹ pọ ko di odidi lo ku, afi bi ajalu yii ṣe ṣẹlẹ. Akọkọ ni pe iṣoro wa lati ya fiimu mi-in nitori owo rẹpẹtẹ ti yoo na wọn, awọn oyinbo ti wọn ya ti akọkọ nkọ, ṣe wọn yoo tun ko wọn pada wa ni, ta ni yoo si sanwo rẹ. Lọna keji, ọdun meloo ni yoo tun na wọn nigba ti wọn ti lo bii ọdun meji aabọ nibi ti wọn ti n ya ti akọkọ yii. Ṣugbọn kinni kan ni, ọkan wa ninu awọn fiimu yii ti wọn ti ṣe lodidi, to jẹ ki wọn kan ṣe atunṣe diẹ diẹ si i lo ku, Fẹla si ro pe ti oun ba ri iyẹn, awọn yoo da ọgbọn si i. Eleyii gan-an ko si ninu awọn ti wọn dana sun, o jọ pe awọn ṣọja naa gbe e lọ ni.
Lẹyin ti ile-ẹjọ ti waa dajọ, ti Fẹla si reti titi ti ko si ẹni to pe e lati ile ijọba, ti ẹni to sọ pe oun yoo fun un lowo tabi ba a tun ile rẹ ṣe, tabi ẹni to beere pe ko waa ṣalaye ohun to sọnu ninu ile naa gan-an ki awọn le ba a wa a, ti ko sẹni to wi nnkan kan fun un ṣaa, Fẹla fi ibinu dide lọjọ kan, wọn gba bọọsi mẹrin, gbogbo awọn ọmọ rẹ si kun inu bọọsi naa bamubamu, bẹẹ ni oun naa gbe kaa kan, awọn eeyan tun kun inu kaa naa, n ni wọn ba kọri si ọdọ Ọbasanjọ ni ile ijọba l’Ekoo, Dodan Barracks, ni Ikoyi, nibẹ nigba naa, wọn ni awọn n lọọ ba Ọbasanjọ lalejo, bi yoo ba pa awọn ko pa awọn, ko si ohun ti awọn n ṣe laye nigba ti awọn ko ba ri ile gbe, ti awọn ko si ri fiimu ti awọn fi owo rẹpẹtẹ ṣe. Wọn ni lọjọ naa lawọn yoo gba fiimu awọn lọwọ Ọbasanjọ, lọjọ naa lawọn yoo si gba owo ti Adajọ Dosunmu ni kijọba ẹ san fawọn.
Lati Ikẹja lawọn motọ naa ti gbera, wọn si n tẹle ara wọn lọwọọwọ bi wọn ti n lọ. Awọn motọ ti wọn kọ Fẹla sara wọn lo jẹ ki awọn eeyan mọ pe Fẹla atawọn ọmọ rẹ lo tun n lọ yii o, awọn eeyan si n sare jade waa wo bawọn motọ naa ṣe n lọ. Gbajumọ ati okiki Fẹla ati awọn ọmọ rẹ si pọ nigba naa debii pe gbogbo awọn onimotọ ti wọn ba lọna ni wọn n bila fun wọn pe ki wọn kọja, bo tilẹ jẹ pe wọn ko fọn fere yaa-fun-un yaa-fun-un bii ti awọn ọlọpaa, ti wọn ko si fi agidi le ẹnikẹni. Awọn motọ kọọkan ti wọn le tẹle wọn naa n tẹle wọn, wọn fẹẹ mọ ibi ti Fẹla tun n lọ, wọn sa ti mọ pe bi awọn ti ri oun atawọn ọmọ rẹ yii, ati imura ti wọn mu, ki i ṣe ode ere ni wọn n lọ, ibi ti wọn ba si n lọ, awọn naa yoo debẹ, nitori wọn mọ pe Fẹla ki i ṣe ẹran rirọ, ki i ṣe ẹni ti i ṣe ileri ti ko ni i mu un ṣẹ, o kan jẹ pe wọn ko mọ iru ileri to ṣe lasiko yii ni.
Amọ nigba ti wọn n lọ, ti wọn sare titi ti wọn ko duro, ti awọn ti wọn tẹle wọn ri i pe ọna Ọbalende ni wọn ya si, ti wọn si n lọ taara si baraaki awọn ṣọja ni Dodan, awọn ti wọn ko laya akẹbọjẹ sa pada sẹyin, wọn ni awọn ko ni i waa fi ara gbọta lojiji, wọn ni ọdọ awọn ṣọja ni Fẹla tun n lọ. O fẹrẹ da bii pe awọn onijangbọn meji ti wọn wa l’Ekoo ni asiko naa niyẹn, Fẹla ati awọn ṣọja, nibikibi ti wọn ba ti pade ara wọn, bii igba ti irin meji pade ni, ariwo yoo ṣẹlẹ nibẹ ṣaa ni. Iyẹn lawọn ti wọn mọ iba ara wọn ṣe yaa sa pada, wọn ni Ọlọrun ma jẹ ki ọrọ tawọn ko mọwọ, tawọn ko mẹsẹ di tawọn. Ṣugbọn awọn ti wọn laya, ti wọn si fẹẹ ṣe oju mi to, awọn yẹn o pada o. Ohun ti wọn ṣe ni pe wọn gbe motọ wọn sa si ẹgbẹ kan, wọn si fẹsẹ rin sitosi ẹnu ọna baraaki awọn ṣọja naa, wọn fẹẹ mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ.
Ohun to ṣẹlẹ ni pe nigba ti wọn yoo tilẹ fi de Dodan Barack yii, ojo nla kan ti sọ kalẹ, ojo naa si n rọ waa waa waa ni. Ṣugbọn Fẹla ati awọn ọmọ rẹ ko tori rẹ duro, bẹẹ ni awọn ti wọn tẹle wọn ko si dakẹ, wọn wa ninu ẹnu ọna baraaki yii, wọn ko jẹ ki motọ mi-in wọle, nitori niṣe ni wọn di oju ọna pinpin. Awọn ṣọja ti wọn n ṣọ ẹnu ọna naa jade, awọn ṣa duro ninu ojo, wọn si da akoto wọn bori, wọn na ibọn wọn sọọọkan, o jọ pe wọn fẹẹ bẹrẹ si i yinbọn nitori ko si sifilian, iyẹn araalu kan, ti i lori laya ti yoo lọọ duro sẹnu ọna baraaki awọn ologun. Ṣugbọn awọn naa kan na an sọọọkan nibẹ ni, wọn ko yin in o, bẹẹ ni wọn ko si ṣi geeti ti wọn yoo ba wọle. Awọn ṣọja ti wọn wa nitosi ti wọn ko si lẹnu ọna paapaa tori bojo, wọn ti gbọ pe Fẹla ti de si baraaki awọn, o loun fẹẹ ri Ọbasanjọ, afi ki wọn ṣi geeti foun.
Awọn ṣọja paapaa funra wọn ko yee fi ọwọ lu ọwọ, wọn n sọ pe, “Na soja dis man fọ be, he too bold!” Wọn ni iṣẹ ṣọja lo yẹ ki Fẹla maa ṣe, o ti laya pupọ ju, orin to n kọ yẹn ki i ṣe ọna ẹ rara, ṣọja lo tọ si i. Bẹẹ ni awọn ti ko si nibẹ naa n waa ba wọn, ko si pẹ ti ẹnu ọna baraaki lọhun-un fi kun fun awọn ṣọja ti wọn waa woran Fẹla. Awọn to jẹ ọga ni ẹnu geeti ti sọ fawọn ọjẹ-wẹwẹ wọn pe ki wọn ma yinbọn o, ki wọn ma si ba wọn ja, ki wọn jẹ ki awọn lọ sinu ile ki awọn lọọ gbọ ọrọ lẹnu awọn ọga awọn pata. Ko sẹni to mọ ẹni ti wọn lọọ ri ninu wọn, ko sa pẹ ti ọga agba kan fi jade, toun si wa tẹrin-tẹrin, to ba Fẹla sọrọ bii ọmọluabi, niṣe lo si bẹri fun un nigba to n ki i. O ni ki Fẹla bọ silẹ wa, Fẹla loun ko bọ silẹ, ko sọ ohun ti yoo ba ba oun sọ ninu motọ oun nibẹ, oun ko raaye ẹjọ, bẹẹ ni oun ko wa lati ba ṣọja kankan ṣọrẹ, nitori ọrẹ aja pẹlu ẹkun ko ni i wọ nibi kankan.
Nigba ti ṣọja yii ri i pe Fẹla fẹẹ maa gboju ija, o sọ fun un pe oun ko ba tija wa rara, oun fẹ ki awọn jọ sọrọ ọmọluabi ni. Ọkunrin naa ni awọn ọga oun lo ran oun, alaye ti wọn si sọ foun ni pe ki oun ri i, ki oun si beere ohun to n wa, bo ba jẹ nnkan ti awọn le da a lohun si ni, ki wọn da a lohun kia, bo ba si jẹ ọrọ naa ko si lọwọ awọn, ki awọn mọ ibi ti wọn yoo ti yanju rẹ. Nigba naa ni Fẹla sọ fun un pe ṣe ijọba ko mọ pe o yẹ ki awọn ti waa san owo ti ile-ẹjọ ni ki wọn san foun fun oun ni, abi ọjọ wo ni oun yoo duro da, bẹẹ ni oun fẹẹ gba ẹru oun ti wọn ji ko lọ, paapaa fiimu orin ti oun n ṣe lọwọ. Ni ọkunrin ṣọja naa ba tun rẹrin-in, o sọ fun Fẹla pe gbogbo ọrọ to ba jẹ mọ ẹjọ rẹ, ati ohun ti yoo gba, ati ẹtọ ti wọn yoo ṣe fun un, o ni ko si lọdọ awọn ṣọja, tabi ijọba apapọ, ọwọ ijọba Eko lo wa, wọn si ti fa gbogbo rẹ le wọn lọwọ.
Nibẹ ni ọkunrin ọga ṣọja yii ti ni ki Fẹla maa lọ taara si ọdọ ọga ọlọpaa pata ni ipinlẹ Eko, oun ni yoo ṣeto naa fun un ati gbogbo ohun to ba tọ si wọn. Ọga ṣọja naa ni ki ọrọ naa le da a loju, bo ba fẹ ki oun tẹle wọn lọ, oun yoo ba wọn debẹ, lati ri i pe wọn ri ẹni to yẹ ki wọn ri. Fẹla tun loun ko fẹ bẹẹ, o ni oun ko fẹ irin oun ati ṣọja, oun ko fẹ ọrẹ apapandodo ti wọn fẹẹ maa ba oun ṣe, ki wọn san owo oun foun, ki wọn da ile oun pada foun, ki wọn ba oun gbe fiimu oun, ki kaluku si maa ba tirẹ lọ ni. Ọga ṣọja naa tun rẹrin-in , o ni ki Fẹla ṣa ma binu, nitori awọn ko ni i ba a ja mọ, ija awọn ti pari, ko jẹ ki awọn maa ṣọrẹ, ọrẹ lo dara ki awọn ṣe, ki awọn le jọ tun ilu ṣe. Fẹla ni oun ti sọ toun, oun ko ni ọrẹ kan ti oun fẹẹ ba ṣọja ṣe, ki kaluku maa ṣe tirẹ lọtọ ni. Ṣugbọn o paṣẹ fawọn ọmọ ẹ, o ni ki wọn jẹ ki awọn lọ.
N ni wọn ba tun ko rẹirẹi o, nigba naa, ojo si ti da. Awọn ọrẹ ati awọn olufẹ rẹ ti wọn gbọ pe Fẹla ti wa ni Dodan Barack ti gbe motọ tiwọn naa wa, awọn yii si tẹle wọn bi wọn ti tun yi ori mọto pada, wọn ni awọn n lọ si ọdọ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, ko si si ọlọpaa kan tabi ṣọja ti yoo tun da awọn duro mọ. Awọn oniroyin naa ti de, wọn ni Fẹla o ni i gba, gbogbo ohun ti yoo ba si ṣe naa yoo ṣoju awọn. Irin-ajo ti Fẹla rin lọ si ọdọ awọn Ọbasanjọ ki i ṣe kekere, nitori kinni kan wa ti oun ati gbogbo awọn ọmọ rẹ ṣe. Nigba ti wọn n lọ, niṣe ni wọn gbe ẹni dani,wọn si fi odidi mọto kan ko matiraasi, wọn ni awọn yoo maa sun sibẹ ni, iyẹn niwaju ile Ọbasanjọ tabi ọfiisi rẹ ninu Dodan Baracks, tabi ki awọn kuku jokoo si ẹnu geeti awọn ṣọja nibẹ, ki awọn ma ṣe aye awọn. O jọ pe ibẹru iyẹn lo jẹ ki awọn ṣọja naa fọgbọn le wọn.
Nigba ti wọn de Lion Building, l’Ekoo, nibẹ, nibi ti olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa Eko wa, nibi ti kọmisanna wọn si ni ọọfiisi rẹ si, niṣe lo da bii pe awọn yẹn ti mura silẹ de wọn, ti wọn fẹẹ gba alejo daadaa. Awọn ọga ọlọpaa bii mẹta ni wọn ti duro si ẹnu ọna, awọn ọlọpaa wẹwẹ naa si wa nibẹ, wọn ko si gbe ibọn tabi mu ohun ija dani, bi awọn mọto Fẹla si ti de ni wọn ti sare ṣilẹkun fun wọn, ti awọn ọga ọlọpaa ti wọn n duro de e naa si pade rẹ, ti wọn fẹẹ bọ ọ lọwọ. Ko bọ wọn lọwọ, awọn naa si kawọ wọn sẹyin, ṣugbọn ko le binu nitori ọwọ ati ọna ti wọn fi pade rẹ, o ri i pe awọn ọlọpaa naa fẹ alaafia, oun naa si fẹẹ fi han pe eeyan daadaa loun, oun ki i ṣe onijangbọn bawọn ọlọpaa ṣe n fẹ ki gbogbo aye mọ nipa oun. Ni wọn ba ni ko maa bọ ko waa wọle, pe ọga ọlọpaa Eko, U J. Usen, ti n duro de e. Nibẹ ni wahala mi-in ti fẹẹ ṣẹlẹ.
Wahala to fẹẹ ṣẹlẹ ni pe Fẹla ni oun ati awọn maneja oun pẹlu awọn iyawo oun lawọn yoo wọle lọọ ri ọga ọlọpaa naa, awọn ọga olọpaa naa ni iyẹn ko le ṣee ṣe, ko si aaye ti yoo gba gbogbo awọn iyawo rẹ ati awọn maneja rẹ ninu ọọfiisi ọga ọlọpaa yii. Fẹla ni wọn ki i ṣe ẹni ti yoo jokoo, wọn yoo duro ni, ko si si ohun to kan aaye ninu ọrọ ilẹ yii, ibi to ba gba oun, dandan ni ko gba awọn iyawo oun, tabi awọn ọlọpaa yii ko mọ pe agbalagba ọkunrin kan ki i fi iyawo rẹ silẹ ni, ibi to ba n lọ ni wọn jọ n lọ. Awọn ọlọpaa ni bo ba jẹ iyawo kan ni, awọn iba jẹ ki wọn wọle, ṣugbọn iyawo mẹtadinlọgbọn ko ṣee ko wọ ibi ipade lẹẹkan. Nigba naa ni ọga kan pe Fẹla sẹyin, o si sọrọ wuyẹ fun un, ohun to sọ naa ni pe oun ati ọga ọlọpaa ni wọn fẹẹ ṣepade, wọn o si ni i gbadun ara wọn bi ero ba ti pọ ju nibẹ, ko jẹ ki awọn iyawo rẹ duro de e, ki oun si lọọ ri ẹni to fẹẹ ri i.
Fẹla ni o daa, ṣugbọn awọn maneja meji yoo tẹle oun, ati olori awọn iyawo oun, awọn yooku le jokoo si ita ọfiisi kọmisanna, oun yoo si wọle lọọ ba a. Awọn ọlọpaa naa ni iyẹn daa, ni wọn ba jẹ ki Fẹla wọle, awọn iyawo rẹ si lọọ jokoo sinu motọ. N loun ati ọga ọlọpaa Eko pata ba jọ jokoo ipade, ko si sẹni to mọ ohun ti wọn n sọ, afi nigba to jade. Ọga ọlọpaa naa sọ fun Fẹla pe fiimu to n sọ ọrọ rẹ ko si lọdọ awọn, eyi to wa lọwọ awọn ni fiimu rẹkọọdu tuntun to ṣẹṣẹ ṣe, awọn ko fẹ ki fiimu naa wọgboro, nitori o le da wahala silẹ ni, ṣugbọn bo ba mu iwe to fi kọ kinni naa wa, ti awọn ba yẹ ẹ wo, awọn yoo kan sọ fun un pe ko yọ awọn ibi kan kuro ni, yoo si maa ba iṣẹ rẹ lọ. O ni awọn ọlọpaa gan-an kọ lo ko fiimu yii kuro, awọn ọlọpaa inu ni, ṣugbọn awọn le wa a jade. Bo ba si jẹ ti owo ati ohun ti ile-ẹjọ n wi ni, ọga ọlọpaa yii ni aṣẹ gomina lawọn n reti, ti awọn ba ti ri aṣẹ lọdọ gomina, awọn yoo ṣe ohun to ba yẹ ki oun ṣe.
Nigbẹyin, Fẹla jade lọdọ awọn ọlọpaa, o si kilọ fun wọn pe ki wọn ṣe nọma, ki wọn ṣe eto, bi wọn ko ba ṣe bẹẹ, wọn yoo tun gburoo oun laipẹ rara. Ṣugbọn nnkan mi-in ṣẹlẹ ni ọjọ kẹta ti Fẹla kuro lọdọ awọn ọlọpaa yii, ajalu gidi ni: Iya Fẹla ku lojiji!

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.