Fẹla fẹẹ gbowo lọwọ ijọba, Ọbasanjọ ni ijọba oun ko lowo, Wọn ni adajọ ni yoo ba wọn da a

Spread the love

Awọn ti wọn n ṣejọba ki i ṣe eeyan daadaa. Boya ologun ni wọn, bo si jẹ sifilian, iyẹn awọn ti wọn ko wọ aṣọ ṣọja, ikan naa ni wọn, ijọba nijọba yoo maa jẹ. Wọn fi abuku olorombo kan ijọba Ọbasanjọ, iyen nigba ti awọn igbimọ agbaye dide si ọrọ Fẹla, ti wọn si ni ohun ti ijọba naa ṣe fun un ko daa. Ki i ṣe iyẹn nikan ni wọn wi, wọn ni awọn ti ṣetan lati gbọ ẹjọ naa, ki awọn funra awọn si mọ boya Fẹla jẹbi, tabi ijọba ṣọja lo jẹbi ni. Họwu! Ṣe bi eeyan ba n kọrin ti ko dun, oun naa yoo kuku maa fi eti ara rẹ gbọ ọ. Awọn naa mọ pe ohun ti awọn ṣe ko daa, wọn si mọ pe agbara ipa lawọn lo fun Fẹla, ati pe bi ọrọ naa ba de ojutaye tootọ, ko si ibi ti awọn yoo gbe ẹjọ naa de ti wọn ko ni i da awọn lẹbi. Nitori bẹẹ ni wọn ṣe tete wa wọrọkọ ṣe ada nigba ti wọn gbọ pe awọn Amnesty International, awọn adajọ aye, fẹẹ da si ẹjọ Fẹla.

Wọn ti sare ranṣẹ si awọn adajọ pe awọn ṣọja yoo waa jẹ ẹjọ, awọn yoo si fi ara awọn silẹ fun gbogbo ohun ti awọn lọọya ba fẹẹ bi awọn ni ile-ẹjọ. Ṣugbọn bi wọn ṣe ṣe bẹẹ tan, awọn ọlọpaa ti yoo gbe ẹjọ naa kalẹ ti bẹrẹ eto buruku kan labẹlẹ, ohun ti wọn si n ṣe naa yoo ba ẹjọ Fẹla jẹ kanlẹkanlẹ. Awọn ọlọpaa nikan ni wọn mọ, ati ijọba to ran wọn niṣẹ. Ohun ti wọn n ṣe ni pe gbogbo awọn ọmọlẹyin Fẹla, iyẹn awọn ọmọbinrin Fẹla ti wọn le jẹrii daadaa, awọn ti awọn ṣọja na, awọn ti wọn ta nipaa, awọn ti wọn fi tipatipa ba sun, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ si i mu gbogbo wọn lọkọọkan. Ki i ṣe pe wọn n mu wọn ti mọle o, wọn n ja wọn kuro lẹyin Fẹla ni. Nigba ti wọn ti kọkọ ti wọn mọle lakọọkọ ni wọn ti gba adirẹsi ọpọlọpọ wọn, ti wọn beere ibi ti baba ati iya wọn n gbe, tabi awọn ẹbi wọn, ṣe awọn ọmọ Fẹla ko mọ ohun ti wọn fẹẹ fi i ṣe.

Ohun tawọn ọlọpaa ṣe ni lati ranṣẹ sawọn eeyan naa, iyẹn awọn obi awọn ọmọ ẹyin Fẹla. Bi wọn ti ṣe ṣe fawọn ọkunrin wọn naa niyẹn, yatọ sawọn ti wọn ti giran-an sẹyin ẹ, to jẹ agbara ọlọpaa tabi ihalẹ wọn ko jọ wọn loju. Ko si ọmọbinrin ti wọn ranṣẹ si iya tabi baba rẹ tawọn yẹn o ni i sare wa, bi wọn ba si ti de ni wọn yoo fa awọn ọmọ naa le wọn lọwọ, pẹlu ikilọ gidi pe ti awọn ba tun ri ọmọ naa lẹyin Fẹla, tabi ti awọn ba gburoo ọmọ naa nibi kan, awọn ko ni i beere ẹjọ kan lọwọ rẹ, ẹwọn ni yoo lọ, ẹwọn ọdun meje si ni. Ta ni yoo gbọ pe wọn yoo ju ọmọ oun sẹwọn ọdun meje ti ko ni i ki ori ọmọ naa bọ abẹ, tabi ọmọ wo ni yoo gbọ pe wọn yoo sọ oun si ẹwọn ọdun meje ti oun naa ko ni i gbe jẹẹ. Ohun to mu ọpọ awọn ọmọlẹyin Fẹla igba naa pada si ile iya wọn ree, afi awọn kọọkan ti wọn ti dagba toju i bọ.

Ohun ti wọn ṣe n ṣe gbogbo eyi ni pe nigba ti ẹjọ naa ba bẹrẹ, Fẹla ko ni i ri ẹlẹrii gidi kan mu wa. Abi nigba ti wọn ba ni wọn ba awọn kan sun ti ko ba si ẹni ti yoo jade pe wọn ba oun sun ni tipatipa, tabi nigba ti wọn ba ni wọn lu awọn kan ti wọn ko ba ri eeyan ti yoo sọ pe wọn lu oun loootọ ni. Bẹẹ, ọrọ ile-ẹjọ, ọrọ ẹri ni. Bi ile-ẹjọ ko ba ri ẹri to to ẹri, wọn ko ni i da ọdaran kan lẹbi, wọn yoo sọ pe ko maa lọ, ọwọ yoo tun tẹ ẹ nigba mi-in ni. Ohun ti ofin sọ ni pe o san ki awọn da ọdaran mẹwaa silẹ ko maa lọ nigba ti awọn ko ba ri ẹri gidi lati fi de wọn mọle, ju ki awọn waa sọ alaiṣẹ kan sẹwọn lọ nitori ẹri eke tabi ọrọ agbọsọ lasan. Ohun ti awọn ọlọpaa yii gboju le ree, wọn ti mọ pe bi awọn ti n le awọn ẹlẹrii jinna si Fẹla yii, bẹẹ naa ni yoo ṣe ṣoro ki awọn adajọ too da awọn lẹbi, tabi ki wọn too bu ijọba Ọbasanjọ.

Ati pe ni gbogbo igba ti ọrọ yii n lọ, abi ka ni lati igba ti wọn ti ja ti wọn wọ ile Fẹla yii, Iya Fẹla funra rẹ ko gbadun, ọsibitu lo wa, tabi ko lọ sọhun-un loni-in ki wọn gbe e pada wale lọla, bo ba tun di ọtunla ki wọn tun da a pada sibẹ, wahala to ba a naa ti sọ ọ di foni-ku-fọla-dide obinrin. Ṣe oun naa ki i kuku i ṣe ọmọde, o ti dagba nigba naa, o ti le lọmọ aadọrin ọdun (70 years), oun naa kan jẹ obinrin kan to lagbara ni, nitori bo ti dagba to yii naa lo n fa ijangbọn to, iyẹn lawọn eeyan si ṣe n sọ pe oun lawọn ọmọ rẹ fi ijangbọn fifa jọ. Ṣugbọn ọtọ ni ohun ti awọn ọlọpaa ti wọn n palẹ ẹjọ mọ fẹẹ lo ọrọ aiya-ara Iya Fẹla yii fun, awọn fẹẹ lo o lati fi sọ fawọn adajọ pe ara iya naa ko ya, lati igba to pẹ, pe ki i ṣe lọjọ ti wọn dana sun ile Fẹla ni kinni naa ṣẹṣẹ bẹrẹ, pe o ti pẹ ti aarẹ agba ti n ṣe e, ọrọ to ba si sọ ko ni i ṣee tẹle rara.

Ṣugbọn gbogbo bi awọn ọlọpaa ati ijọba ologun ti n ṣe nni, awọn Fẹla ko jẹ ki iyẹn ko irẹwẹsi ba wọn, awọn naa ni ẹri ti wa nilẹ, fọto wa, bẹẹ ni awọn eeyan pọ rẹpẹtẹ ti wọn yoo lọ, ko si iye ti wọn le mu ninu awọn ọmọ oun ti yoo ba ẹjọ naa jẹ. Fẹla tilẹ sọ pe aja kan ki i ja ọmọ lẹyin ẹkun, o ni awọn ti awọn ọlọpaa n halẹ mọ, ti wọn n da pada sọdọ awọn to bi wọn, awọn ọmọ to ṣẹṣẹ de ọdọ awọn ni, awọn yẹn ko ti i mọ ẹni ti wọn n pe ni Fẹla ati ohun ti Fẹla duro fun. Awọn ti wọn mọ Fẹla, ti wọn si mọ iduro rẹ ko ni i pada lẹyin rẹ, koda ko ṣe ọkunrin tabi obinrin ni. Eleyii ni Fẹla ati lọọya rẹ di mu, ohun ti wọn si gbe lọ si iwaju adajọ to pe wọn pe ki wọn wa niyẹn, nitori awọn ṣọja ti sọ pe awọn naa ṣetan lati jẹjọ, ati pe nibikibi ti Fẹla ba ti fẹ lawọn yoo ti pade rẹ. Ọjọ karun-un, oṣu kẹsan-an, ọdun 1977, ni wọn lọ sile-ẹjọ naa.

Ṣe ẹni to ba mọ ọna naa leeyan yoo tẹle bii orin awọn musulumi, Braithwaite ti mọ ohun ti awọn adajọ yoo sọ pe ki oun ṣe, oun naa ko si ṣẹṣẹ duro ki adajọ maa da oun sọtun-un sosi, o ti ṣe e ko too debẹ. Afidafiidi ni, ibura ti yoo fi beere ohun to fẹ ki awọn adajọ ṣe. Eyi ni adajọ yoo tẹle ti yoo fi paṣẹ, bi ko ba si tagiiri, awo ko hu ni o, bi ko ba si afidafiiti, adajọ ko ni aṣẹ kan ti yoo pa. Ni Braithwaite ba ṣe afidafiiti yii, o si sọ bi gbogbo ohun ti awọn Fẹla ti kọ, o ni ki adajọ tete fun awọn ni ọjọ ti wọn yoo bẹrẹ ẹjọ naa. O sọ ọrọ ti awọn ọmọ Fẹla tawọn ọlọpaa n gbe sa lọ, o sọ ti iya rẹ, o ni iya naa ti dagba, ọmọ ọdun mejilelaaadọrin (72) ki i ṣe ọdun kekere mọ, ohun to si ṣẹlẹ si i ti kan ọpọlọ rẹ debii pe ki i ṣe gbogbo ọrọ lo ku to n ranti mọ, ẹẹkọọkan lo n ranti ohun to ṣẹlẹ, bo ba si ti ya, yoo gbagbe ni.

Braithwaite ni ohun ti awọn ṣe fẹ ki ẹjọ naa tete pari niyi, ko ma di pe yoo di rẹdẹrẹdẹ bii ere oṣupa, ti ẹnikẹni ko si ni i le da si i mọ, tabi ti ọpọ eeyan ko ni i mọ bi ọrọ naa ti ṣẹlẹ gan-an. Wọn ni awọn ti mọ awọn ti ọrọ naa kan, nigba ti wọn si ti ni awọn yoo waa jẹjọ, ko le mọ rara. Ki ṣọja ṣa ba awọn wa olori awọn ṣọja, iyẹn Yakubu Danjuma, ki wọn ba wọn wa ọga awọn ṣọja to wa ni Albati Barracks, Ọgagun Adedayọ ati Ọgagun Dauda, pẹlu awọn ṣọja meji ti gbogbo wahala yii bẹrẹ lori wọn. Lọọya awọn Fẹla yii ni bi ẹsẹ awọn yii ba ti pe, lẹsẹkẹsẹ ni gbogbo aye yoo rojutuu si ọrọ to wa nilẹ yii, nitori oju wọn ni ohun gbogbo ṣe ṣẹlẹ, awọn ni wọn si wa nidii ọrọ naa, gbogbo awọn ṣọja to wa lati jo ile Fẹla, ti wọn fipa ba awọn ọmọ ọlọmọ sun, ti wọn si sọ iya Fẹla lati oke si isalẹ, awọn to ran wọn niyẹn.

Tunji Braithwaite ni ofin ati idajọ a maa laaanu alaini tabi ẹni ti wọn n fiya jẹ. O ni bi adajọ ba ri awọn Fẹla, yoo mọ pe iya to n jẹ wọn ko kere rara. O ni lati igba ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ ni wọn ko ti ri ibi to dara gbe, bii ka sun ibi ti ko tẹ ni lọrun, bii ka lọ sọdọ ọrẹ ati ile ẹbi lawọn eeyan naa n ṣe kiri. Bẹẹ, awọn eeyan yii ti kuro ni iru ipo bẹẹ, nitori wọn ti ṣiṣẹ ṣiṣẹ, wọn si ti ni owo lati fi ṣe iwọnba ohun ti yoo mu aye wọn dẹrun. Ṣugbọn awọn ti wọn jo ile wọn nina, ti wọn si sun awọn ohun-ini wọn ninu oṣu keji ọdun naa ba gbogbo nnkan ti wọn ti fi owurọ wọn ṣe jẹ, wọn si sọ ẹbi naa di alarinkiri. Gbogbo ohun ti wọn si ṣe yii, awọn ṣọja naa lo ṣe e, awọn olori wọn lo si ran wọn. Ko si ohun meji ti yoo dara ju ki awọn adajọ dajọ gidi, ki awọn Fẹla le ri owo wọn gba pada, ki ijọba san miliọnu mẹẹẹdọgbọn ti wọn lawọn fẹẹ gba fun wọn lo daa ju lọ.

Ooto si ni, nnkan ko rọrun rara fun awọn eeyan naa lati igba ti ijamba naa ti ṣẹlẹ nile wọn. Owo ojumọ ni Fẹla n na, nitori lojoojumọ ni yoo ṣere, bi ko si ṣere, wọn yoo ta ọja oriṣiiriṣii nile rẹ, awọn ọmọ rẹ yoo wa nibẹ ti wọn yoo maa jo, awọn eeyan yoo maa wa ti wọn yoo maa nawo, ti wọn yoo si maa raja, ko si si igba ti eeyan debẹ ti ko ni i ri faaji ṣe, nibi faaji ti wọn si n ṣe yii, nibẹ ni owo Fẹla ti n jade ni tirẹ, nitori gbogbo igba ni owo n wọle fun wọn. Ṣugbọn ki i ṣe Fẹla nikan naa lo n gba owo yii, awọn oṣiṣẹ wa nibẹ bii rẹrẹ, awọn ontaja naa pọ ti wọn yoo wa sibẹ lojoojumọ, ati ojo ati ẹẹrun, ile alakan ki i gbẹ ni. Ẹni to n ri owo to to bayii, to si n na an, to ni irinṣẹ lọpọlọpọ ti wọn fi n ṣere, to si ni mọto loriṣiiriṣii, to waa di ẹni ti wọn sun gbogbo irinṣẹ ere rẹ, ti wọn si sun gbogbo mọto to n gbe kiri.

Bii igba pe Fẹla ko ni mọto kankan ni, awọn ọrẹ rẹ lo ku ti wọn n gbe e ni mọto kiri, bii ka sun otẹẹli, ka sun ile ọrẹ loun naa si n ṣe kiri. Iya rẹ to wa ni ọsibitu ko tun mu nnkan dẹrun, nitori ko le ṣe ko ma de ọdọ iya naa ri i. Ninu ile ti wọn jo yii, nibẹ ni ọsibitu adani ti aburo rẹ ni wa, iyẹn Dokita Beko Ransome Kuti. Ki i ṣe awọn araale wọn nikan lo n ṣe iṣẹ iwosan fun nibẹ, gbogbo awọn eeyan adugbo naa pata ni. Bẹẹ ni awọn eeyan nla nla maa n wa lati igboro, ati ọna jinjin, ti wọn yoo waa gba itọju lọdọ aburo Fẹla. Ohun to fa a ti wọn fi n wa bẹẹ ni pe ọkunrin naa mọ iṣẹ pupọ, iṣẹ dokita oyinbo naa ye e ju ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ lọ. Yatọ si eyi, awọn irinṣẹ igbalode lo ko sinu ọsibitu kekere to wa nile Fẹla yii, ko si si iṣẹ iwosan ti ko le sare ṣe nibẹ, eyi ti apa rẹ ko ba si ka, yoo gbe e lọ si Luutu to ti n ṣiṣẹ pẹlu ijọba.

Nigba naa, ofin fi aaye gba ki dokita ni ọsibitu kekere mi-in ti yoo maa ṣiṣẹ rẹ laarin ilu, ti yoo le maa fi ran awọn ti wọn ba wa ni adugbo ati itosi rẹ lọwọ. Ohun ti aburo Fẹla yii n ṣe niyẹn. Ṣugbọn wọn jo ọsibitu naa mọle, wọn si jo awọn irinṣẹ to wa nibẹ mọ ọn. Eyi lo ṣe jẹ nnkan to bajẹ ninu ile Fẹla ko ṣee ka tan, owo rẹpẹtẹ lo jona, yoo si ṣoro ki wọn too le ko awọn nnkan to wa nibẹ jọ pada, eyi ni awọn eeyan naa si ṣe sọ pe miliọnu mẹẹẹdọgbọn owo Naira igba naa ni wọn yoo fun awọn. Owo nla ni owo naa, o si daju pe bi ijọba ba ni owo naa lọwọ paapaa, wọn ko ni i san an fun Fẹla. Ṣugbọn Fẹla mọ pe bi adajọ ba le ni ki wọn san owo naa foun, bi wọn ko san gbogbo rẹ, wọn yoo san diẹ nibẹ. Ṣugbọn ki i ṣe owo gan-an lo n dun ọkunrin olorin yii, ẹwọn taara lo fẹ fun ọpọlọpọ awọn ṣọja ti wọn n ṣejọba.

Braithwaite ni ohun to n ṣe awọn ti wọn n ṣejọba yii ni pe wọn ti ro pe gbogbo ohun ti awọn ba ṣe, aṣegbe ni, nigba to jẹ awọn nijọba, ko sẹni to le yẹ awọn lọwọ wo, ko sẹni to to bẹẹ lati da awọn lẹbi. Ọkunrin naa ni nibi ti awọn ti wọn ba ti n ṣejọba ba ti n ronu bayii, ọpọ aburu ni wọn yoo maa ṣe, nigba ti wọn kuku mọ pe ko si ofin tabi ijiya kan fawọn. Idi eyi gan-an lawọn adajọ si ṣe gbọdọ duro giri, ki wọn jẹ ki awọn ti wọn n ṣejọba mọ pe awọn le ṣe aṣiṣe, ati pe aṣiṣe yoowu ti awọn ba ṣe, tabi ọran yoowu ti awọn ba da, awọn gan-an ni wọn yoo fori ara wọn fa a. o ni bi wọn ba ti awọn ti wọn dana sun ile Fẹla, awọn ti wọn fi tipa ba eeyan sun, ti wọn ju wọn sẹwọn, ti ijọba to ran wọn si san owo gọbọi bii owo itanran, awọn mi-in to ba tun fẹẹ da ọran bẹẹ ninu awọn ti wọn n ṣejọba yoo ro o daadaa ki wọn too ṣe e.

Gbogbo awọn ọrọ yii ni lọọya awọn Fẹla to jọ, o si taari rẹ siwaju adajọ yii, o ni ko yẹ ọrọ awọn wo ko le mọ ohun ti yoo mu ṣe idajọ rẹ, ati asiko ti yoo tete fi ẹjọ naa si, ki ohun to n bajẹ fun awọn Fẹla yii ma waa bajẹ ju bẹẹ lọ. Adajọ paapaa ti mọ ibi ti ọrọ n lọ, o si ti mọ ohun ti ijọba fẹ ki oun ṣe ati ohun ti oun naa yoo ṣe ti orukọ wọn ko fi ni i bajẹ lẹyin odi. Nitori bẹẹ, ko jagbe, bẹẹ ni ko sọrọ odi, o kan sọ pe oun ti gbọ ni. O ni bo ba di ọjọ kẹrinla ati ikẹẹẹdogun si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun naa, (December 14, 15, 16), awọn yoo bẹrẹ ẹjọ ọhun, oun yoo si fi odidi ọjọ mẹta gbọ ọ. O ni laarin ọjọ mẹtẹẹta, oun ko ni i gbọ nnkan mi-in mọ ju ẹjọ tiwọn yii lọ, gbogbo ẹni to ba fẹẹ sọrọ ko waa sọrọ, gbogbo ẹni to ba fẹẹ rojọ ko waa rojọ, ati ẹlẹrii ijọba ati ti awọn Fẹla, ki gbogbo wọn pesẹ lawọn ọjọ wọnyi, nitori lẹsẹkẹsẹ ni wọn yoo gba idajọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ naa gun diẹ fun awọn Fẹla, sibẹ, ko si ohun ti wọn le ṣe, wọn ṣa ti mọ pe nigba naa ni wọn yoo de ba ẹjọ ti wọn ti n fa lati igba yii wa, ọrọ naa yoo si sun mọ odidi ọdun kan. Awọn Fẹla ni ẹlẹrii mẹwaa lawọn ni, awọn mẹwẹẹẹwa yoo si wa ni ile-ẹjọ lọjọ ti igbẹjọ ba bẹrẹ, ko sẹnikan ti yoo lọ sibi kan ninu wọn. Awọn ijọba ati ṣọja naa sọ pe awọn ni ẹlẹrii kan, agbẹjọro wọn to wa, Arabirin Kọmọlafẹ, ko lodi si gbogbo ọrọ ti wọn sọ kalẹ, o kan n sọ pe oun ti gbọ, oun ti gba naa ni. Lẹsẹkẹsẹ ni ọrọ naa si tan ka ilu, wọn n sọ pe wọn yoo da ẹjọ Fẹla ninu oṣu kejila, ọdun, awọn mi-in si ti sọ ẹjọ naa di owo, wọn ni wọn yoo fun Fẹla lowo ni ipari ọdun 1977. Awọn mi-in n ba a ṣiro iye ti yoo gba paapaa, wọn ni bi wọn ti ba ile rẹ jẹ to nni, owo nla ni wọn yoo gbe fun un.

Bẹẹ ọrọ naa ko ri bẹẹ, ẹjọ ni wọn ni wọn fẹẹ da, bi wọn yoo si ti da a, ko sẹni to ti i mọ, nitori bi Fẹla ti n da ọgbọn tirẹ, bẹẹ ni ijọba naa n da ọgbọn tiwọn, wọn ko si ṣetan lati fun Fẹla ni owo kankan. Ọna ti wọn yoo gba fi fiya jẹ ọkunrin olorin naa gbe ni wọn n wa, wọn si ti lero pe ko si ohun ti yoo ṣe naa ju ariwo lasan lọ. Ohun kan ṣoṣo to jẹ nnkan ayọ nibẹ ni pe bi wọn ti n ṣe gbogbo eleyii fun Fẹla, bẹẹ ni orukọ rẹ n tan si i, okiki rẹ si kan lati ilẹ yii kaakiri gbogbo aye, awọn eeyan si n ti i lẹyin, wọn ni ko ba ijọba Ọbasanjọ fa a ko tora wọn. Fẹla naa ti wọ ṣokoto ija rẹ, ariwo, “Mi o ni i gba!” loun naa n pa kaakiri.

(45)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.