Fẹla ṣegbeyawo tan, o ko awọn iyawo Ẹ mẹtadinlọgbọn lọ si Ghana, n Lawọn ṣọja ba le wọn jade

Spread the love

Awọn ẹbi jinna diẹ si ibi ti Fẹla ti n ṣe igbeyawo rẹ, koda, awọn ọrẹ rẹ to sun mọ ọn gan-an ti wọn mọ ni amofin yẹra. Awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin rẹ ati awọn kọọkan ti wọn mọ ohun to ti ṣẹlẹ tẹlẹ ko fi taratara jokoo sibi igbeyawo naa, wọn n wo fẹtofẹto ni. Ṣebi ki Fẹla too ko awọn ọmọbinrin rẹ wa si Anthony, lọdọ aburo rẹ, ti wọn si tibẹ lọ si otẹẹli Parassona ti wọn ti n ṣeyawo yii, wọn ti kọkọ lọ si ile-ẹjọ, wọn si da ile-ẹjọ naa ru nigba ti awọn adajọ ati lọọya ati awọn ọlọpaa kootu ri Fẹla pẹlu awọn ọmọbinrin rẹ. O ni ki wọn ṣe igbeyawo kootu foun. Adajọ ti wọn kọkọ de ọdọ rẹ ni oun ko gbọ iru rẹ ri, ekeji naa si sọ bẹẹ, ṣugbọn eyi to jẹ ikẹta ni ti Fẹla ko ba kuro niwaju oun ati ni ile-ẹjọ naa kiakia, awọn yoo fi ọlọpaa mu un, wọn yoo si ka ẹsun ajọmọgbe si i lọrun, nitori gbọmọgbọmọ ni.
Ki lo de ti iyẹn fi ni gbọmọgbọmọ ni Fẹla ati pe wọn yoo ka ẹsun ajọmọgbe si i lọrun. Idi ni pe ọpọlọpọ awọn ọmọ to ko wa lati ṣeyawo fun wọn yii, ọmọde ni wọn, ọmọde ti ko ti i le da ero ara rẹ pa, tabi ti ko ti i mọ ohun to n ṣe, nitori wọn ko ti i pe ọmọ ọdun mejidinlogun. Awọn to pe ọmọ ọdun mejidinlogun tabi ogun ko to mẹwaa ninu awọn iyawo to fẹẹ fẹ yii, awọn ọmọ ọdun mẹrindinlogun, mẹtadinlogun, ati bẹẹ bẹẹ lọ lo pọ ju ninu wọn. Ṣugbọn nitori ijẹkujẹ ati imukumu ati aye ominira ti wọn ri nile Fẹla, ọpọlọpọ wọn lo da bii agbalagba, afi nigba ti eeyan ba wo oju wọn ni yoo mọ pe ọmọde pata ni wọn. Bẹẹ ofin Naijiria ni pe ko sẹni to gbọdọ fẹ ẹni ti ko ba ti i pe ọmọ ọdun mejidinlogun niyawo, bẹẹ ni ko sẹni to gbọdọ ba wọn da owo kan papọ, nitori wọn ko ti i lagbara labẹ ofin lati da ṣe ohunkohun.
Nibi ti awọn Fẹla ti jokoo ti wọn ti n wa adajọ ti yoo ba wọn ṣeto igbeyawo naa ni olobo ti ta wọn pe adajọ agba ti paṣẹ pe ki wọn fi ọlọpaa ko gbogbo wọn, pe wọn n wa awọn ọlọpaa ti yoo ṣa wọn ni o, bi wọn ba si ti mu wọn, itimọle ni wọn n ko wọn lọ, afi nigba ti wọn ba waa ṣalaye ohun ti wọn tori ẹ wa. Eyi lo mu Fẹla palẹ ara ẹ mọ, to si ko awọn iyawo rẹ lẹyin, o ni koju ma ribi, ẹsẹ loogun ẹ, oun naa mọ pe awọn ọlọpaa ko gbọdọ gbe oun, wọn yoo kan da ohun gbogbo ti oun ti palẹ ẹ mọ ru ni. Ohun ti oun ro ni pe bi awọn oniṣọọṣi ko ba gba oun, ko sohun to ni kawọn adajọ ma gba oun, bi awọn ba si ti ṣe tadajọ tan, awọn aa pada lọọ ṣe ti ibilẹ, nibi tawọn babalawo yoo ti faṣẹ si igbeyawo awọn, ohun gbogbo pari niyẹn. Bẹẹ awọn babalawo ti wa nitosi, bawọn ọlọpaa ba waa ko awọn ti mọle, wọn ba gbogbo ariya jẹ niyẹn.
Iyẹn lo ṣe sare kọkọ ko awọn iyawo ohun lọ sọdọ alafọrọlọ rẹ to jẹ aburo rẹ, Bẹẹkọ, ṣe Anthony loun n gbe, itosi ibẹ naa si ni otẹẹli ti Fẹla gba to n gbe pẹlu awọn obinrin rẹ naa wa, nigba ti wọn si ro gbogbo rẹ paapaapa ni wọn ni ki wọn lọọ ṣe eto gbogbo nibi ti awọn ti ro pe awọn yoo ṣe e naa tẹlẹ, ki wọn lọ si gbagede otẹẹli yii, ki wọn ṣe ohun gbogbo paapaapaa. Iyẹn lawọn ti wọn mọ irin-ajo ti wọn rin lọjọ naa ṣe n wo fẹtofẹto pe ṣe nnkan kan ko ni i ṣẹlẹ bẹẹ. Amọ o, ko si nnkan kan to ṣẹlẹ titi ti awọn iyawo naa fi mura tan, ti wọn si bẹrẹ si i rin gbẹndẹkẹ wa sori ẹni ti wọn ti pese fun wọn. Nigba ti gbogbo wọn si ti jokoo ti Fẹla naa ti de, pẹlu ọrẹ rẹ ọkunrin kan to jẹ ọrẹ ọkọ iyawo, iyẹn Alaaji Jimoh Buraima, ko tun si alaye kankan mọ, ki eto igbeyawo naa maa lọ gẹgẹ bi a ti kọwe rẹ ni, ko sohun to n da wọn duro mọ.
Ni deede aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹwaa lọjọ naa lọhun-un, Babalawo Ọdẹlẹyẹ bẹrẹ si i pe awọn ohun-Ifa, o si n fi ogede kọọkan ha a lẹgbẹẹ, eto igbeyawo naa si bẹrẹ pẹrẹwu. Ṣe gbogbo awọn iyawo ni wọn ti peju bayii, awọn mẹtadinlọgbọn, ọkọ iyawo funra rẹ, Olufẹla Anikulapo Kuti, si jokoo si aarin wọn. Ko si aṣadanu ninu awọn obinrin naa o, gbogbo wọn ni wọn mura deede, wọn si rẹwa lobinrin, bẹẹ ọmọde ni gbogbo wọn. Ko sẹni kan to ronu pe bawo ni Fẹla yoo ṣe maa kari awọn obinrin wọnyi lalaalẹ, bawo ni yoo ṣe pin ara rẹ laarin wọn. Ohun ti wọn n ro ni pe boya ni iru ọkunrin yii tun wa ni Afrika, wọn ko si gburoo pe iru rẹ wa ni gbogbo agbaye paapaa, ẹni ti yoo fẹ iyawo mẹtadinlọgbọn lẹẹkan ṣoṣo. Ṣugbọn idunnu ni ọjọ naa jẹ fun Fẹla, nitori ẹrin loun n rin, bi babalawo atawọn ọmọ awo to wa nibẹ ṣe n ki Ifa lọ.
Lati ṣalaye pe ko si ohun to buru ninu ohun ti wọn n ṣe nijọ naa, Babalawo Ọdẹlẹyẹ sọ ninu ẹsẹ Ifa to n ki pe, “Ẹdumare lo da gbogbo ẹda aye, pẹlu aṣẹ rẹ ni wọn si fi n pa’mọ, ti wọn n bi si i, ti wọn rẹ si i. Ohun yoowu ti wọn ba waa gbe ile aye ṣe, afi ki Ifa Agbọniregun mọ si i, nitori oun ni yoo gbe e tọ Eledumare lọ.” Babalawo waa bẹrẹ adura nikọọkan fawọn iyawo tuntun wọnyi, ohun to si n ṣe ni pe bo ba ti mu eelo kan, yoo fi kan Fẹla lori, yoo si waa fi kan gbogbo awọn iyawo naa pata lori nikọọkan, lẹyin naa ni yoo bẹrẹ si i wure. Nigba to mu obi, o na an soke ki gbogbo eeyan le ri i, lẹyin naa lo fi kan awọn tọkọ-taya lori, lo waa faṣẹ si i pe “Obi niyi o, obi ni i bi iku, obi ni i bi arun, obi naa ni yoo bi tiku-tarun kuro lori yin o.” Bẹẹ naa lo ṣe nigba to mu orogbo, o ni “Orogbo ni i gbo ni saye, orogbo yoo jẹ kẹ ẹ gbo, kẹ ẹ tọ o.”
Bayii lọkunrin babalawo naa ṣe nigba to mu oyin, to n tọ oyin naa si wọn lẹnu nikọọkan, o ni, “Adunkan, adunkan ni toyin, ko sẹni ti i moyin sẹnu ti i poṣe, aye yin yoo dun joyin lọ!” O mu ṣuga, o fi ṣadura pe igun mẹrin ni ṣuga ni, gbogbo ẹ naa adun ni, gbogbo igun aye wọn ni yoo ni adun. O mu ataare, o ni fọfọ ni ile ataare i kun, ile wọn yoo kun fun owo, ọmọ ati ohun rere gbogbo. Bayii ni babalawo naa n mu awọn kinni wọnyi nikọọkan, ko si si eyi to mu ti ko fi ṣadura, bo si ti n ṣe adura ni awọn tọkọ-tiyawo tuntun naa n ṣe n ṣe ‘aṣẹ, aṣẹ’. Ireke wa ninu ohun to lo lọjọ naa, wọn ge e wẹwẹ nigba to ya, o fi kan awọn iyawo naa lori, o si sọ kekere rẹ si wọn lẹnu, pe bi ireke ti ladun naa ni nnkan wọn gbogbo yoo ladun, wọn ko ni i mọ ikoro nigba kan. Bẹẹ lo tọ ọti ṣinaapu si wọn lẹnu, to n sọ pe ẹni ọti ki i ti o.
Lẹyin ti babalawo naa ti lo awọn ohun eelo iwure wọnyi tan, o bẹrẹ si i ki ẹsẹ Ifa loriṣiiriṣii lati maa fi ṣadura fun Fẹla ati awọn iyawo rẹ, gbogbo awọn ero to wa nibẹ si ba wọn da si i nipa ṣiṣe “aṣẹ”, “aṣẹ.” Lẹyin eyi ni Babalawo Ọdẹlẹyẹ jokoo, o ni ki Fẹla waa dafa, ko da Ifa lori awọn iyawo rẹ kọọkan. Nigba naa ni Fẹla yọ tuẹnti-tuẹnti Naira, iyẹn ogun Naira jade, bo ba si ti fi ọkan si ori iyawo rẹ kan, yoo jẹnu wuyẹwuyẹ, yoo ju kinni naa silẹ sinu ọpọn Ifa, bẹẹ lo si ṣe sori gbogbo iyawo rẹ nikọọkan. Bi owo ti n bọ silẹ sinu ọpọn Ifa ni babalawo n gba a, nigba to si gba owo naa tan, o gbe ọpẹlẹ rẹ ṣanlẹ nigba aimoye, bẹẹ lo n sọ ohun ti Ifa wi fun ẹni kọọkan wọn. O waa gbadura pe ki Ifa ṣe igbeyawo naa ni eyi ti yoo ni ere ninu, ki Ifa si jẹ ki gbogbo wọn pẹ laye, ki wọn si ba ara wọn lo pẹẹ pẹẹ pẹẹ.
Lẹyin naa lo waa gbe ọpẹlẹ janlẹ, to da Ifa fun gbogbo wọn lapapọ. Ohun to sọ ni pe Ifa ni oun ti fi aṣẹ si igbeyawo wọn, oun si ti faṣẹ si i ki wọn di tọkọ-taya, ki wọn maa gbe pẹlu irẹpọ lai ni i si wahala kankan fun wọn. O ni ohun ti Ifa n sọ foun, ti oun n ri loju ọpọn bayii, ni pe ko si ẹni kan ti yoo ku ni kekere ninu wọn, wọn yoo pẹ laye daadaa, koda wọn yoo gbo ju orogbo lọ, bẹẹ ni igba wọn yoo si sunwọn laarin ara wọn. Ṣugbọn babalawo naa ni oun ri kinni kan o, o ni iyẹn naa ni pe gbogbo awọn iyawo yii ko gbọdọ ṣe awọn nnkan kan ni gbogbo igba ti wọn ba fi wa nile Fẹla, iyẹn naa ni pe bi wọn ba lalaa, wọn ko gbọdọ sọ fun ara wọn. O ni ibi iyawo kekere ba lalaa, ko gbọdọ sọ fun iyawo agba, bi iyawo agba ba si lalaa, ko gbọdọ sọ fun iyaale rẹ kankan, ẹni yoowu to ba lalaa kan, ko yaa fi ala naa sinu rẹ ni, ohun ti ko fi ni i sija niyẹn.
Babalawo Ọdẹlẹyẹ doju kọ Fẹla funra rẹ, o ni, “Ẹni ọtọ pata gbaa ni Ọlọrun da ẹ o. Eeyan iyatọ ni ọ laarin gbogbo ẹda aye to ku. Abami Ẹda kan lo n ṣe. Ifa ni ki n sọ fun ọ pe o maa pẹ laye kanrin kese, ko si bi o ṣe le ku ni kekere rara, ko si si ọkankan ninu awọn ọmọ mẹta to o ti bi tẹlẹ ti yoo pade agbako kankan.’’ Babalawo naa waa ni ki gbogbo ohun daadaa ti oun ri laye Fẹla yii too waa le ṣẹ loootọ, yoo rubọ fun ilẹ, ilẹ ogẹrẹ afọkọyẹri. O ni irubọ ti yoo ṣe naa ni pe yoo ra odidi ẹran agutan kan, ẹran agutan funfun ti yoo ni dudu diẹ nibi oju rẹ, bẹẹ ni yoo wa ẹyẹ aparo meji, yoo si wa ogun orogbo ati ogun obi abata, nigba naa ni ohun ẹbọ pe, ti awọn yoo si fi gbogbo rẹ rubọ, ki adura rẹ le gba, ki gbogbo ohun to n fẹ le ṣẹlẹ, ki rere oriṣiiriṣii le maa ṣẹlẹ si i. Bẹẹ ni Fẹla ni oun yoo rubọ naa, oun yoo si ṣetutu, nitori oun fẹ ki igbeyawo oun dun, ko larinrin.
Laarin wakati kan pere ni wọn fi ṣe gbogbo eto naa, nitori paapaapaa bii ẹni to fẹẹ ra ireke ni Papa ni wọn fi kinni naa ṣe, awọn iyawo si pada si yara wọn, kaluku bẹrẹ si i pe ara rẹ ni Mrs Anikulapo Kuti, Fẹla naa si n yan fanda kiri inu otẹẹli laarin awọn ọrẹ rẹ ati awọn ololufẹ rẹ to wa, o ni nigba yii ni oun ṣẹṣẹ ṣe ohun to wa lọkan oun, oun tẹ ara oun lọrun, ẹri ọkan oun si da oun lare, nitori oun ko jẹ ki awọn ọmọbinrin ti Ọlọrun fi fun oun naa maa rare kaakiri. O sọ fawọn oniroyin pe ohun ti awọn aye fẹ ni ki wọn maa sọ pe awọn ọmọ Fẹla ko lọkọ, aṣẹwo ni wọn, gbogbo eeyan lo n ba wọn sun, o ni ṣugbọn iyẹn ti yipada bayii, gbogbo ẹni to ba leti ko gbọ, ki wọn mọ pe awọn ọmọ Fẹla ti ni ọkọ o, oun Fẹla si ni ọkọ wọn, ko sobinrin ti ko lọkọ ninu gbogbo awọn ti wọn n ba oun ṣere, Misis Anikulapo Kuti ni gbogbo wọn.
Gbogbo awọn ti wọn n gbọ ni wọn n miri, wọn n beere lọwọ ara wọn pe iru abami ẹda wo lọkunrin yii na, awọn ara ilẹ okeere paapaa si n wadii iru eeyan ti Fẹla yii jẹ. Awọn ti wọn n ṣe ijọba ologun n wa gbogbo ọna lati mu un, wọn ni ki lo n ṣe ọmọ onijangbọn yii to jẹ bi wọn ti n ge e lọwọ lo tun n bọruka, wọn o si tete mọ ohun ti wọn yoo tun ṣe fun un ti yoo dun un ju ki awọn ma jẹ ko ri ibi gidi kan ṣe ere rẹ, ki awọn si ri i pe ko ri ibi kan rin si, owo ti ile-ẹjọ si ni ki awọn fun un, ki awọn ri i pe ko sẹni kan to fun un lowo kan. Wọn ni nigba ti iya ba jẹ ẹ, to jẹ oun ati awọn iyawo to ṣẹṣẹ fẹ yii, ti ko ribi ṣere, ti ko si ri owo na, awọn obinrin naa yoo fi i silẹ, awọn ọmọde naa yoo si gba ile baba ati iya wọn lọ. Ṣugbọn Fẹla ki i ṣe eeyan bẹẹ, nitori ojumọ kan, ara kan ni. Bi ijọba ti n ronu tiwọn, bẹẹ loun naa n ronu ohun mi-in ti yoo ṣe.
Lalẹ ọjọ kẹjọ ti Fẹla ṣe igbeyawo rẹ, o gbera pẹlu gbogbo awọn iyawo rẹ mẹtadinlọgbọn, wọn ni wọn n lọ si orilẹ-ede Ghana. Fẹla ti nibẹ loun yoo wa toun yoo maa ṣere oun, oun yoo tilẹ yẹra fun wahala awọn ṣọja ni Naijiria, bo ba si ya, oun yoo pada nigba ti awọn ologun naa ba ko angara wọn lọ. Yatọ si tiyẹn, o ni oun fẹ ki awọn iyawo oun sinmi, ki wọn si gbadun aye ara wọn diẹ, ki wọn bọ lọwọ hilahilo ijọba ati awọn ṣọja Naijiria, ki wọn le bẹrẹ aye tuntun. Wọn kuro ni Naijiria ni Mọnde, ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 1978, wọn si wọ orilẹ-ede Ghana ni Tusidee, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keji naa. Papa ọkọ ofurufu Kotoka, ni Accra, Ghana, ni wọn balẹ si, oun pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ oṣere rẹ, ati awọn iyawo rẹ gbogbo. Wọn de si wọn lọrun ni Ghana tẹrutẹru.
Ṣugbọn awọn alaṣẹ ilẹ Ghana ti gbọ pe Fẹla n bọ niluu, oun ati awọn iyawo rẹ tuntun, wọn si ti ṣeto bi wọn ko ṣe ni i jẹ ko wọle. Nitori bẹẹ, bi ẹronpileeni ti n ja wọn silẹ ni papa-ọkọ-ofurufu yii, bẹẹ lawọn sikiọriti sare yi wọn po. Awọn ṣọja wa ninu wọn, awọn ọlọpaa wa ninu wọn, bẹẹ ni wọn sare rọ wọn sẹgbẹẹ kan, wọn ni wọn ko le wọle o. Bii ala ni kinni naa ri loju Fẹla, nitori igba akọkọ ti yoo wa si Ghana kọ niyi. Lati igba ti wahala ti ṣẹlẹ si i nile lo ti n wa Ghana, o si ti n ṣeto bi yoo ti gbebẹ fungba diẹ, koda, o ti wa sibẹ waa ṣere pẹlu awọn ọmọ rẹ naa tẹlẹ, wọn ko si sọ fun wọn ki wọn ma wọle nigba naa, bi eleyii ti waa ri ko ye ẹni kankan. Gbogbo ariwo ti wọn le pa ni wọn pa, gbogbo ija ti wọn si le ja naa ni wọn ja, awọn agbofinro ilẹ Ghana taku o, wọn ni Fẹla ko ni i wọle, ki wọn tete pada si Naijiria, ohun ti ijọba sọ niyẹn.
Nibi ti ọrọ naa le de, ti ko si ẹronpileeni ti yoo tete ko awọn eeyan naa pada si Naijiria, papa-ọkọ-ofurufu yii, nilẹẹlẹ lawọn eeyan naa sun mọju, awọn ṣọja ati ọlọpaa ko si fi wọn silẹ nigba kan, wọn ni awọn ko le fi wọn silẹ, afi ti ẹronpileeni ti yoo ko wọn pada si Naijiria ba de. Ọsan ọjọ Wẹsidee ni ẹronpileeni Nigeria Airways too de si orilẹ-ede naa, oun lo si ko Fẹla ati awọn eeyan rẹ pada si Naijiria ni ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun 1978. Fẹla fi ariwo nla bọnu, o ni nitori pe oun n forin oun sọrọ ni ijọba Ghana ṣe le oun, nitori wọn ni awọn ko fẹ ki awọn ọmọ awọn maa huwa bii awọn ọmọ Fẹla, bẹẹ irọ ni wọn n pa, orin Zombie ti awọn ọmọ Ghana n kọ kiri lo n bi wọn ninu, nigba to jẹ ijọba ologun ni wọn n lo ni Ghana naa, ọkan naa si ni ṣọja, wọn ko yatọ sira wọn.
Fẹla gba lọọya, wọn pe ijọba Ghana lẹjọ, o loun ko ni i gba, afi bi oun ba mọ ohun ti oun ṣe. Ni Fẹla ba pada si Naijiria o, o si jokoo ni Ikẹja, nibi to ti bẹrẹ igbe aye tuntun.

(23)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.