Fayoṣe tọwọ bọ afikun eto isuna lẹyin wahala pẹlu APC

Spread the love

Irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja ni Gomina Ayọdele Fayoṣe tọwọ bọ afikun eto isuna biliọnu mẹsan-an ati miliọnu mẹsan-an (9.9b) Naira to ti kọkọ da wahala silẹ laarin oun ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).

Nibi eto naa ti abẹnugan ile igbimọ aṣofin Ekiti, Kọla Oluwawọle, atawọn ọmọ ile naa kan peju si ni Fayoṣe ti buwọ lu biliọnu mẹsan-an ọhun, bẹẹ lo bẹnu atẹ lu bi APC ati Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ṣe tako igbesẹ naa.

O ni, ‘’O ya ni lẹnu pe Ọmọwe Kayọde Fayẹmi sọ pe afikun yii ko nitumọ. Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2014, to ku oṣu kan ko gbejọba silẹ lo tọwọ bọ iru iwe yii. Ko lọọ dakẹ o, emi ṣi ni gomina.’’

Fayoṣe ni gbogbo ọna ni Fayẹmi fẹẹ fi ba oun lorukọ jẹ, ṣugbọn awọn yoo wo nnkan to fẹẹ ṣe to ba gbajọba.

Ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja lawọn aṣofin mẹrinla fọwọ si afikun isuna naa nile igbimọ. Lẹyin eyi ni Ọnarebu Gboyega Aribiṣọgan to jẹ adari ọmọ ile to kere ju sọ pe Fayoṣe kan fẹẹ sọ ikowojẹ di ounjẹ ni.

Awọn to fọwọ si isuna naa ni: Kọla Oluwawọle to jẹ abẹnugan, Ṣina Animaṣaun, Samuel Ọmọtọṣọ, Samuel Jẹjẹ, Tọpẹ Fasanmi,

Dayọ Akinlẹyẹ, Wale Onigiobi, Dare Pelemọ, Cecilia Dada, Musa Arogundade, Sanya Aladeyẹlu, Ọlayọde Ọmọtọṣọ, Dele Fajẹmilẹhin atiỌlanrewaju Ọlayanju.

Aribiṣọgan ni awọn aṣofin to jẹ APC atawọn mi-in ko fọwọ si igbesẹ naa, Fayoṣe si fẹẹ fi bo aṣiri awọn jibiti kan to ti waye kaakiri awọn ileeṣẹ ijọba ni, ki i ṣe fun anfaani araalu.

‘’Ọjọ Fraide ọsẹ to kọja ni wọn pe abẹnugan sile ijọba ti wọn fun un ni afikun eto isuna yẹn. Gomina ko sọ bo ṣe n nawo fun wa, bẹẹ la o mọ bowo ṣe n wọle.’’

Bakan naa ni Taiwo Ọlatunbọsun, alukoro APC to sọrọ lorukọ gbogbo ẹgbẹ ti kọkọ sọ pe iwa ọkanjua gomina lo tun fara han, ko si bikita lori awọn oṣiṣẹ to jẹ lowo oṣu rẹpẹtẹ ati bi iya ṣe n jẹ araalu.

 

 

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.