Fayoṣe fopin si erongba rẹ lati dupo aarẹ *Bẹẹ ni Atiku, Kwankwaso ati Turaki polongo de Ekiti

Spread the love

 

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe, ti fopin si erongba rẹ lati dupo aarẹ orilẹ-ede yii lọdun to n bọ. O sọ eyi lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, lasiko to n gbalejo Sẹnetọ Rabiu Kwankwaso ati Kashim Saminu Turaki ti wọn fẹẹ dupo aarẹ ninu ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP).

Kwankwaso to jẹ gomina Kano tẹlẹ ati Turaki toun jẹ minisita nigba kan ni wọn n lọ kaakiri awọn ipinlẹ lati beere fun atilẹyin awọn aṣoju ẹgbẹ PDP ti wọn yoo dibo yan oludije wọn laipẹ.

Gẹgẹ bi Fayoṣe ṣe ṣalaye, ‘’Mo fopin si erongba mi lati dupo aarẹ ilẹ yii nitori ẹtọ igbakeji mi, Ọjọgbọn Oluṣọla Ẹlẹka, to dupo gomina Ekiti ti APC gba lọwọ rẹ.

‘’Gẹgẹ bii adari rere, mi o le fi ẹni to jẹ oloootọ si mi silẹ ki n maa le nnkan mi-in. Awọn iwe ipolongo mi wa ninu yara kan, ṣugbọn afojusun ti yatọ bayii, ẹtọ Ẹlẹka ni koko lọwọlọwọ.’’

Fayoṣe fi kun un pe Kwankwaso wa lara awọn to tako oun nigba toun n pariwo lọdun 2015 pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko leto kankan fun ilẹ yii, ṣugbọn gomina tẹlẹ naa ti waa mọ ootọ bayii, o si ti di atunbi.

Ninu ọrọ ẹ, Kwankwaso ṣalaye pe aṣiṣe nla ni APC toun jẹ ara wọn tẹlẹ ṣe nipa yiyan Buhari, asiko si ti to lati le e lọ. O rọ awọn aṣoju naa lati dibo fun un nitori iriri to ni atawọn iṣẹ to ṣe ni Kano to fi iwa adari rere han.

Nigba to n sọrọ tiẹ, Turaki sọ pe iṣọkan ilẹ yii ti n mi lẹgbẹlẹgbẹ, gbogbo nnkan tawọn aṣaaju fi silẹ si ti n daru. O ni awọn adari ti ko mọ nnkan ti wọn n ṣe lo n dari ilẹ yii, bẹẹ ni ipaniyan atawọn iṣẹlẹ aburu mi-in ko yee waye, ṣugbọn oun mọ awọn igbesẹ ti Naijiria yoo gbe lati bọ ninu awọn wahala ọhun.

Ṣaaju ni Alhaji Atiku Abubakar to jẹ igbakeji aarẹ ilẹ yii tẹlẹ ti waa ṣepolongo tirẹ. Oloṣelu naa sọ pe Naijiria ti jin sinu ọfin iwa ibajẹ labẹ Aarẹ Buhari, ati pe eto aabo lasiko ogun abẹle gan-an fẹrẹ daa ju ti asiko yii.

O waa sọ pe gbogbo ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan oun ko lẹsẹ nilẹ, ati pe oun ti n pariwo tipẹ ki ẹni to ba ni ẹri jade sita, ṣugbọn oun ko ri ẹnikankan. O ni iriri ati ọgbọn lati dari Naijiria wa nikaawọ oun, eyi si ni nnkan toun fẹẹ jẹ kawọn eeyan mọ ki wọn le dibo foun.

(21)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.