Fayẹmi pe Fayoṣe nija: Pade mi laarin ọja ka sọ ba a ṣe nawo Ekiti faraalu

Spread the love

Ipolongo ibo to n lọ lọwọ nipinlẹ Ekiti gbọna mi-in yọ nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ijẹta, nigba ti Ọmọwe Kayọde Fayẹmi pe Gomina Ayọdele Fayoṣe nija pe ko jẹ kawọn lọ saarin ọja lati sọ faraalu bi awọn ṣe nawo Ekiti.

Eyi waye lẹyin ti alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Amofin Gboyega Oguntuwaṣe, pe Fayẹmi nija lati sọ bo ṣe na biliọnu marundinlaaadọsan-an (165b) naira to jẹ owo Ekiti laarin ọdun 2010 si 2014.

Ninu alaye alaga naa lo ti sọ pe awọn ẹri lati ọdọ oluṣiro owo ijọba apapọ ati ileeṣẹ akọsilẹ owo nina fi han pe Fayẹmi gba owo naa, eyi si yatọ sawọn owo mi-in tijọba apapọ fun un ati eyi ti Ekiti pa labẹle.

 

”Lọdun 2011, Fayẹmi gba biliọnu lọna ogoji aabọ (40.5b) loṣooṣu, o gba ogoji biliọnu din diẹ (39.8b) lọdun 2012, o gba biliọnu mẹrinlelogoji le diẹ (44.3b) lọdun 2013, o si gba ogoji biliọnu le diẹ (40.1) lọdun 2014.

 

”Ṣugbọn Fayoṣe gba biliọnu mejidinlọgbọn le diẹ (N28.2b) lọdun 2015, biliọnu mọkandinlogun din diẹ (18.8b) lọdun 2016 ati biliọnu mẹrindinlọgbọn (25.6b) din diẹ lọdun 2017.

”Oriṣiiriṣii owo ni Fayẹmi tun ri gba lọwọ iojọba apapọ, bẹẹ lo ya biliọnu mẹẹẹdọgbọn ti Ekiti yoo san fun ogun ọdun. Ki lo ṣe pẹlu awọn owo yẹn? Ko si.

 

”Gbọngan ayẹyẹ to n kọ ko pari, o tun loun fẹẹ kọ ile ijọba tuntun, ṣugbọn o kan pese ilẹ ni, ko ṣiṣẹ kankan nibẹ. Ọja Ọba naa wa nibẹ ti ko kọ, bẹẹ ni biriiji.

 

”Gbogbo awọn owo ti Fayoṣe gba la ri nnkan to fi n ṣe, awọn araalu si ri ile ijọba tuntun, biriiji, titi ọlọda atawọn nnkan mi-in to ṣe. Awọn tiṣa ti Fayẹmi fẹẹ le nijọba Fayoṣe ti ṣe koriya fun, iyẹn lo jẹ ka maa gba ipo kin-in-ni ni Naijiria bayii.’’

 

Ṣugbọn Ọmọwe Fayẹmi ti sọ pe ko si agbegbe kan nipinlẹ Ekiti tijọba oun ko ṣiṣẹ si, ibi tawọn si ba iṣẹ de lọdun 2014 ni gbogbo rẹ wa di asiko yii.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ”Wọn n beere pe bawo la ṣe nawo Ekiti. Ki wọn lọọ wo gbogbo ilu ati ileto ta a ṣiṣẹ si. Ko si agbegbe ti ko jẹgbadun ileewosan, gbọngan ilu, ileewe, titi ọlọda onikilomita marun-un, owo fawọn arugbo, iṣe fawọn ọdọ ati oriṣiiriṣii eto ironilagbara.

 

”Ko si nnkan ta a fowo Ekiti ṣe ti a ko le tọka si, ṣugbọn gbogbo owo tijọba asiko yii n gba ko han nipinlẹ Ekiti. Nigba mẹta ni ijọba mi ṣe afikun owo oṣu nitori nigba ti Fayoṣe kuro nibẹ lọdun ***2016, eto owo oṣu ti Gomina Adeniyi Adebayọ fi silẹ naa lo lo.

 

”Ijọba mi ṣe afikun lati ẹgbẹrun marun-un aabọ si ẹgbẹrun mẹjọ o le, a tun gbe e si ẹgbẹrun mẹtala o le, ka too waa sọ ọ di ẹgbẹrun mọkandinlogun o le.

 

”Mo fi asiko yii pe Gomina Ayọdele Fayoṣe nija lati pade mi laarin ọja, ka le ṣalaye ba a ṣe nawo Ekiti faraalu. Ti a ba sọ fun gbogbo eeyan nnkan ta a fowo wọn ṣe, awọn gan-an lo maa ṣedajọ wa, wọn yoo si mọ ẹni to n fẹ ilọsiwaju wọn.’’

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.