Fayẹmi gbena woju awọn obi to n fọmọ taja *O ṣeleri lati da awọn ileewe kan pada fun aladaani

Spread the love

Lati asiko yii lọ ni ijọba ipinlẹ Ekiti yoo maa mu awọn obi ti wọn n gbe ọja le ọmọ wọn lori lasiko to yẹ ki wọn wa nileewe. Lopin ọsẹ to kọja ni Gomina Kayọde Fayẹmi kede ọrọ naa, eyi to ni o ti di ofin lẹsẹkẹsẹ.

Igbesẹ yii waye latari bi akọsilẹ ṣe fi han pe ọpọlọpọ awọn ọmọ to yẹ ko wa nileewe ko lọ mọ latari owo, ṣugbọn latigba tijọba tuntun ti bẹrẹ ẹkọ ọfẹ, awọn ọmọ kan ti wọn n kiri ọja ko ti i pada sẹnu ẹkọ wọn.

Fayẹmi woye pe iye awọn ọmọde to n lọ sileewe ti dinku jọjọ, ṣugbọn pẹlu ẹkọ ọfẹ, ko yẹ ki obi kankan ni awawi. O ni ipinlẹ imọ ti wọn n pe Ekiti ko gbọdọ dohun igbagbe, gbogbo araalu lo si gbọdọ gbaruku ti ijọba.

Akọsilẹ fi han pe ida marundinlọgọta lo n lọ sileewe lasiko yii, eyi to jinna si ida mẹrindinlọgọrun-un tọdun 2014.

Ni bayii, ijọba ti bẹrẹ si i ṣe akọjọpọ awọn to fẹyinti lẹnu iṣẹ olukọ ki anfaani le wa fawọn to kunju oṣuwọn lati gba ipo wọn.

Bakan naa nijọba ti bẹrẹ eto lati da awọn ileewe to jẹ ti ṣọọṣi ati tawọn aladaani mi-in pada, ṣugbọn amojuto yoo wa lati koju awọn ipenija ẹka ẹkọ.

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.