Fayẹmi fẹẹ ṣatunṣe si Ikọgosi atawọn ibudo mi-in l’Ekiti

Spread the love

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti kede pe atunṣe yoo de ba awọn ibudo kan pẹlu bi agbekalẹ ibẹ ati ọna ti wọn gba lo wọn ṣe nilo ki ijọba da si i. Lati ibẹrẹ ọsẹ to kọja ni Gomina Kayọde Fayẹmi ti bẹrẹ abẹwo sawọn ibudo kan nipinlẹ naa, o si han gbangba pe wọn nilo atunṣe.
Nigba to ṣebẹwo si ibudo Ikọgosi Warm Spring to jẹ ibi ti omi gbigbona ati tutu ti pade, eyi to ti di ibi tawọn eeyan ko fẹẹ maa lọ mọ, Fayẹmi koro oju si bi ijọba to kogba sile ko ṣe ṣe nnkan kan sibẹ laarin ọdun mẹrin.
Ibudo naa tawọn ile, ọkọ, afara atawọn nnkan mi-in to wa nibẹ ti bajẹ ni Fayẹmi sọ pe oun yoo ṣatunṣe si ko le di ibi ti okiki rẹ tun tan kaakiri ilẹ yii ati oke okun. O ni ibudo igbafẹ maa n ran ọrọ-aje ilu ati igbaye-gbadun awọn eeyan lọwọ, ko si sẹni to mọ idi ti ijọba to kogba sile ko ṣe mu un lọkun-un-kundun.
‘’Ẹ mọ bi ibi yii ṣe ri lọdun 2014 ti mo gbejọba silẹ, ṣugbọn o ti di nnkan ẹgbin bayii, gbogbo nnkan to n wu wa lori si ti di ofifo. Ijọba n pa owo daadaa nigba naa, iwuri ni ibi si jẹ fawọn eeyan, ṣugbọn nnkan ti yipada.’’
O ṣeleri lati ṣatunṣe si ibudo naa, bẹẹ lo sọ pe ileeṣẹ to n ṣe omi inu ike, Gossy Water Bottling Company, to ti di apati yoo tun jinde pada.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Gbenga Adewale to jẹ alakooso agba ibudo naa sọ pe ijọba to lọ ko da si ọrọ ibẹ rara, ati pe agbegbe naa ko ni ina ijọba lati bii ọdun mẹrin sẹyin. O ni yara igbalode bii ogun ni ko ṣe e gbe bayii fun ẹnikẹni nitori iṣoro kan tabi omi-in ti apa oun ko ka.
Awọn ibi ti Fayẹmi tun ṣabẹwo si ni Ekiti State Technical College, ti atunṣe ti n ba pẹlu ifọwọwosọpọ banki agbaye,opopona Ikọgosi si Ẹrijiyan, Igbara Odo Water Works, Odo Urejeto wa l’Ado Ekiti, ileewosan Ọba Adejuyigbe l’Ado-Ekiti ati bẹẹ bẹẹ lọ.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.