Fayẹmi bẹrẹ ipolongo ibo, o ni Fayoṣe lo f’Ekiti yawo

Spread the love

Minisita fọrọ ohun alumọọni nilẹ yii, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ti bẹrẹ ipolongo lati dupo gomina ipinlẹ Ekiti lẹyin to lọọ gba aṣẹ lọdọ awọn agba ẹgbẹ lolu-ile ẹgbẹ naa lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii. Ero rẹpẹtẹ lo wọ ilu Ado-Ekiti lọjọ naa tilu-tifọn pẹlu bi Fayẹmi ṣe di oludije kẹtadinlogoji to jade lati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).

Nigba to n sọ idi to fi fẹẹ pada wa sile ijọba, Ọmọwe Fayẹmi ṣalaye pe bi nnkan ko ṣe ṣẹnuure nipinlẹ Ekiti latigba toun ti kuro nipo lọdun 2014 lo mu oun pinnu lati waa pari iṣẹ toun bẹrẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘’Gbogbo awọn nnkan ta a ṣe fun igbaye-gbadun awọn eeyan wa ni gbogbo ilu nipinlẹ Ekiti nijọba to wa lori aleefa bayii ko fọwọ kan mọ. Ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn awọn arugbo lo n gba ẹgbẹrun marun-un ẹnikọọkan, ẹgbẹrun mẹwaa ọdọ la gba siṣẹ, a gba awọn tiṣa si i, a tun gba awọn oṣiṣẹ mi-in. Gbogbo iyẹn lo ti ditan bayii o.

‘’Wọn ti pa ẹkọ ọfẹ rẹ l’Ekiti debii pe ọmọ ileewe alakọọbẹrẹ n sanwo, awọn oṣiṣẹ ko rowo oṣu gba, ko si idagbasoke igberiko, bẹẹ ni wọn n parọ faraalu kiri.

‘’A maa gba ijọba pada lọwọ Fayoṣe, o si maa ṣẹwọn lẹyin ijọba.’’

O waa sọ pe oun kọ loun ko Ekiti si gbese di ọdun 2030 bi Gomina Fayoṣe ṣe n sọ kiri, oun gan-an lo ya biliọnu mẹtadinlọgọta, asiko si ti to kawọn ara Ekiti mọ ootọ to wa ninu ahesọ to n lọ nigboro.

Gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ APC ati ogunlọgọ ero lati wọọdu mẹtadinlọgọsan-an (177) ati ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Ekiti lo peju sile ẹgbẹ lọjọ naa, nigba ti Oloye Kẹmi Ọlalẹyẹ to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ ṣaaju awọn alaṣẹ.

Ọjọ karun-un, oṣu karun-un, to n bọ yii ni ẹgbẹ oṣelu APC yoo ṣe idibo abẹle lati mọ ẹni ti yoo koju awọn oludije lati ẹgbẹ mi-in.

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.