Fayẹmi ati Oni: Lẹyin idajọ ile-ẹjọ to ga julọ, awọn araalu n reti igbesẹ APC

Spread the love

O ti daju bayii pe igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) fẹẹ gbe lori ọrọ Gomina Kayọde Fayẹmi ati Oloye Ṣẹgun Oni lẹyin ti ile-ẹjọ to ga julọ nilẹ yii da Fayẹmi lare lawọn araalu n duro de.

Ṣe lọdun to kọja ni Oni wọ Fayẹmi lọ sile-ẹjọ ijọba apapọ ilu Ado-Ekiti pe ko lẹtọọ lati dupo gomina nitori ko fiṣẹ minisita feto ohun alumọọni to n ṣe nigba naa silẹ laarin ọgbọnjọ si ọjọ ibo abẹlẹ gẹgẹ bi ofin ṣe sọ.

Lọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun to kọja, ni Onidaajọ Uche Agomoh gbe idajọ kalẹ pe ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ nitori Fayẹmi ki i ṣe oṣiṣẹ ijọba ti ofin ọgbọnjọ yii ba wi, wọn yan an sipo minisita ni.

Oni tun gba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ilu Ado-Ekiti lọ, nigba to si di ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii ni Onidaajọ Emmanuel Agim dajọ lorukọ awọn ọmọ igbimọ to ku, iyẹn Onidaajọ Adamu Juaro ati Onidaajọ Abubakar Lamido. Awọn naa da ẹjọ ọhun nu pẹlu alaye ti ile-ẹjọ giga ti ṣe ṣaaju.

L’Ọjọru, Wẹsidee, to kọja nile-ẹjọ to ga julọ gbe idajọ kalẹ lẹyin ti Oni gbe ẹhonu lọọ ba wọn. Onidaajọ Amiru Sanusi lo gbe idajọ kalẹ lorukọ Onidaajọ John Okoro atawọn mẹta mi-in.

Sanusi ṣalaye pe abala igba-le-marindinlaaadọrun-un (285) iwe ofin ọdun 1999 ti Naijiria n lo sọ pe awọn ẹsun to ba jẹyọ ṣaaju ibo gbọdọ de kootu laarin ọjọ mẹrinla sọjọ to waye, ṣugbọn lẹyin ọjọ mejilelogoji ni Oni too gba ile-ẹjọ lọ.

O ni eyi ko fun kootu naa lagbara lati gbọ iru ẹjọ bẹẹ nitori ko tẹle ilana ofin lati ibẹrẹ, eyi ko si jẹ ko fẹsẹ mulẹ.

Bakan naa ni Onidaajọ Okoro sọ pe Oni to ti gba pe ipo keji loun ṣe ninu awọn to kopa nibi ibo abẹle APC lo tun pada waa tako ẹni to jawe olubori, eyi to jẹ iyalẹnu.

Fayẹmi funra rẹ ti sọ pe oun ati Oni ki i ṣe ọta, bo tilẹ jẹ pe o gba ile-ẹjọ lọ lati ṣatako oun. O waa ni pẹlu ofin ti APC ṣe pe wọn yoo da sẹria fẹni to ba gbe ẹgbẹ lọ si kootu, oun ko mọ ipinnu ẹgbẹ lori ọrọ naa.

Ipinnu ati igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC fẹẹ gbe lori ọrọ naa lawọn eeyan n duro de bayii, boya Oni yoo si gbe awọn igbesẹ kan tabi omi-in, ko sẹni to mọ.

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.