Fayẹmi ati Fayoṣe sọrọ sira wọn lori ọja tuntun atawọn dukia ijọba

Spread the love

Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan l’Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ati Gomina Ayọdele Fayoṣe to wa lori aleefa ti sọrọ sira wọn lori ọja tuntun ti Fayoṣe n ta fawọn oniṣowo atawọn dukia ijọba mi-in.

Ṣe ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni Fayoṣe bẹrẹ si i ta ṣọọbu igbalode naa fawọn oniṣowo, eyi to lo di tiwọn laelae ti wọn ba ti sanwo, bẹẹ ni ijọba n tẹsiwaju ninu eto naa.

Laipẹ yii ni Fayẹmi kede nipasẹ akọwe iroyin rẹ, Yinka Oyebọde, pe kawọn eeyan ṣọra fun ọja atawọn dukia ijọba mi-in ti Fayoṣe n fọgbọn ta fun wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘’A ti gbọ nipa ọna alumọkọrọyi ti Gomina Ayọdele Fayoṣe fi fẹẹ ta awọn nnkan ini Ekiti ni gbanjo. Lara awọn dukia naa ni ilẹ nla kan to wa laarin ileeṣẹ ijọba Ondo ati Elan Club ni Alagbaka, l’Akurẹ, Erinfun Livestock Development Centre to jẹ ẹgbẹta eeka lọna Poli Ado-Ekiti, Ọja Ọba tuntun atawọn mi-in. A fi asiko yii sọ fawọn eeyan wa, paapaa awọn to fẹẹ ra a pe ki wọn ma ba Fayoṣe dowopọ nitori ijọba to n bọ le ma fọwọ si i.’’

Ninu esi rẹ, Fayoṣe ni Fayẹmi kan n fakoko rẹ sọfo ni nitori oun ṣi ni gomina di ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ati pe ọjọ kẹrindinlogun ni yoo too gbajọba.

‘’ Ariwo lasan ni gomina tuntun n pa, ẹni to jẹ pe ẹtọ ẹlomi-in lo n lo. Ko duro de asiko tiẹ. Ṣe oun lo kọ ọja naa ni? Emi ti mo kọ ọ ni mo n pin in.

‘’Gbogbo eto la maa ṣe labẹ ofin lati jẹ ki awọn to ra ọja yẹn ni atilẹyin ofin. Mo ti ṣe oriṣiiriṣii nnkan amayedẹru mi-in fawọn eeyan, mo si maa fi gbogbo agbara mi daabo bo wọn. Mi o ni i gba ki wọn gbajọba ki wọn wa maa ta ṣọọbu fawọn eeyan tiwọn.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.