Falcons yoo gba ayo mẹwaa fun igbaradi idije agbaye

Spread the love

Ẹgbẹ agbabọọlu awọn obinrin agba ilẹ Naijiria, Super Falcons, yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹsọrẹẹ mẹwaa lati gbaradi fun idije agbaye ọdun yii ti yoo waye nilẹ France.

Ikọ naa yoo kọkọ lọ si idije kan nilẹ China, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọtunla, nibi ti wọn yoo ti maa figagbaga pẹlu awọn orilẹ-ede mẹta mi-in, iyẹn China, Romania ati Korea Republic.

Bakan naa ni idije mi-in yoo waye nilẹ Cyprus laarin ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keji, si ọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun yii. Austria, Belgium, Czech Republic, Finland, Hungary, Italy, North Korea, Mexico, Slovakia, South Afrika ati Thailand ni wọn yoo ba pade nibẹ.

Lẹyin eyi ni wọn yoo koju Spain tabi Canada ki wọn too lọọ bẹrẹ igbaradi fun idije agbaye, o si ṣee ṣe ki wọn tun gba awọn ayo meji mi-in.

Tẹ o ba gbagbe, Naijiria nikan ni orilẹ-ede Afrika to ti lọ si gbogbo idije agbaye awọn obinrin lati ọdun 1991 to ti bẹrẹ. Ọjọ keje, oṣu kẹfa, si ọjọ keje, oṣu keje, nidije tọdun yii yoo waye.

 

 

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.