Faṣọla, o o si gba wa lọwọ Julius Berger to n ṣọna Ibadan

Spread the love

Ọrọ Naijiria yii, nnkan ni. Nigba ti awọn aṣaaju wa ko ba ti fun wa ni apọnle, ti wọn ko si ka wa si kinni kan, a ko ni i jẹ kinni kan loju awọn araata paapaa, oju apọda ati alailọgbọnlori ni wọn yoo si maa fi wo wa. Loju ileeṣẹ Julius Berger ti wọn ṣe lara ọna marosẹ lati Eko si Ibadan, oponu lawọn ọmọ Naijiria, bi eeyan si fi wọn wọlẹ tabi to fi iwọsi lọ wọn, ko ṣe nnkan kan. Awọn eeyan yii lo n ṣe ọna naa lati Eko titi de jọnkiṣan Ṣagamu, ṣugbọn niṣe ni wọn ṣe bii pe oore ni wọn n ṣe ọmọ Naijiria, wọn n ṣe e bii ẹni pe a bẹ wọn ki wọn waa ṣe e ni, ki i ṣe iṣẹ wọn. Bẹẹ owo gọbọi ni wọn gba lori iṣẹ naa, wọn kan n ṣe e bii ẹni pe iṣẹ ọfẹ ni. Afi bii ẹni pe Naijiria nikan ni wọn ti n ṣe titi, ti a ko ri ibi ti wọn ti n ṣe ọna lagbaaye mọ. Awọn eeyan naa da titi yii ru lati bii ọjọ mẹta yii to jẹ inira ni fawọn eeyan lati gba ibẹ kọja, lati aarọ ṣulẹ ni idaamu ti ko lẹgbẹ fi dojukọ gbogbo awọn ti wọn ba gbabẹ lati ọsẹ to kọja. Niṣe ni ọna naa yoo di pinpin, sunkẹrẹ-fakẹrẹ yoo si gba ilẹ, awọn oloṣelu ati awọn ẹni adanu mi-in ti wọn n pe ara wọn ni aṣaaju wa ko si tun mu ọrọ naa rọrun. Awọn lo yẹ ki wọn ba Julius Berger sọrọ ki wọn si sọ pe ohun ti wọn n ṣe ko daa o, ṣugbọn awọn gan-an ni wọn yoo ti ọlọpaa siwaju, ti awọn yoo maa fọn fere, ti wọn yoo gbe mọto wọn gba wọn-wee, ti wọn yoo dojukọ awọn ti wọn n bọ, ti awọn onimọto mi-in yoo tẹle wọn, ti ọna naa yoo si pada di pinpin lẹyin ti awọn ba ti lọ tan. Ni orilẹ-ede agbaye gbogbo, nibi ti ijọba ti wa to fi ti araalu ṣe, ko si ileeṣẹ gidi ti yoo ṣe iru ọna nla bayii ti ko ni i ṣeto ọna kekere mi-in ti awọn eeyan yoo maa gba titi ti wọn yoo fi ṣe e tan, bakan naa ni wọn yoo si ko awọn eeyan wọn soju ọna pẹlu awọn agbofinro lati ri i pe ko si gosiloo, bẹẹ ni ọna ko di mọ ẹnikẹni. Ohun to n biiyan ninu ni pe ileeṣẹ Julius Berger yii n ba wọn ṣe ọna ni Ghana, wọn n ṣe ni Togo ati awọn ilu mi-in ti ko to Naijiria, bẹẹ ni wọn ko jẹ ṣe ohun ti wọn n ṣe fawa yii fun wọn. Ki lo kuku de ti ijọba wa sọ wa di ẹni yẹyẹ bayii, abi Julius Berger funra rẹ lo ya olorikori ileeṣẹ ni! Ọrọ ti de ibi ti Babatunde Faṣọla ti i ṣe minisita eto iṣẹ ode to gbe iṣẹ fawọn araabi yii ko gbọdọ dakẹ mọ, ko pe wọn ko kilọ fun wọn ni. Ṣebi ileeṣẹ mi-in lo n ṣe ọna marosẹ yii kan naa lati Ṣagamu titi wọ Ibadan, tiwọn ko buru to bayii, ileeṣẹ RCC ṣe iṣẹ tiwọn pẹlu ori pipe gan-an ni. Ohun to n ṣẹlẹ ni Mowe-Ibafo yii ko daa o, awọn Julius Berger lo si fa a, ki Faṣọla tete sọ fun wọn. Bi ko ba si tẹ wọn lọrun ki wọn gbe iṣẹ Naijiria silẹ fawọn mi-in, ki wọn yee fi ara ni wa ni ilẹ wa.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.