Ẹyin PDP Ọṣun, ẹ jẹ yaa ba ara yin sọrọ

Spread the love

Wọn ti ṣe eto idibo lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ PDP ninu ibo gomina to n bọ laipẹ yii ni ipinlẹ Ọṣun, ẹni ti wọn si mu ni Sẹnetọ Ademọla Adeleke. Bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa wa nile-ẹjọ ti ko ti i pari, sibẹ, awọn ikilọ kan wa to yẹ ki eeyan ṣe fun awọn ti wọn jẹ aṣaaju PDP ati awọn ọmọ ẹgbẹ wọn. Bo ba jẹ nigbẹyin, Adeleke yii naa ni PDP fa kalẹ, koda, bi wọn ba wọle ibo naa, awọn ẹgbẹ alatako to ba sun mọ wọn ju ni yoo gba kinni naa pada lọwọ wọn. Ko si si ohun meji ti yoo fa a ju sabukeeti ti ọkunrin yii n ru kiri lọ. Lara aburu ati oṣi to ba orilẹ-ede yii lẹ n ri yii. Awọn eeyan ti wọn lọ sileewe, ti wọn kawe yanju, ti wọn si ni oye ati imọ lati ṣe olori ati lati di ipo ijọba mu ko ni i ri aaye debẹ, bi wọn ba ti yọju lawọn ti wọn fi tọọgi depo kan, ati awọn ti wọn n ṣe ẹru fawọn oloṣelu kan yoo yọ ibọn yọ ada ati awọn nnkan mi-in si wọn, wọn yoo si fi tipatipa gba ipo ti wọn ko mọ kinni kan nipa rẹ. Bi ko ba jẹ bẹẹ ni, pẹlu iwe-ijẹrii (Testimonial) ti wọn n ru kiri ori ẹrọ ayelujara to jẹ ti Adeleke yii, bawo ni iru ẹni bẹẹ ṣe gbọdọ jẹ aṣofin. Loootọ ileewe Ẹdẹ Muslim College ni ọkunrin naa ti jokoo ṣe idanwo, ṣugbọn ninu iṣẹ mẹsan-an to ṣe, mẹjọ nibẹ lo ti gba odo, o feeli patapata. Ọkunrin naa ko si waa ka iwe mi-in yanju lati igba naa to le ko sabukeeeti rẹ kalẹ, afi ti ileewe Ẹdẹ yii to ti kuna nikan. Ṣe Adeleke ko tun iwe ẹri oniwee-mẹwaa rẹ ṣe ni, ṣe odo buruku to gba jade naa ree. Iṣẹ wo lo waa n ṣe lati igba yii, awọn wo ni wọn si gba a siṣẹ, imọ ati sabukeeti wo lo fi n ṣe iṣẹ naa. Awọn ibeere ti awọn oloṣelu gbọdọ maa bi ara wọn ree, awọn araalu naa ko si gbọdọ dakẹ, wọn ko gbọdọ tori pe ẹnikan jẹ ọmọ ilu tabi ọmọ adugbo wọn, ki wọn ma beere ohun to ni ninu imọ ati iye iwe to ka to fi ni oun yoo ṣe gomina. Ọtọ ni sabukeeti ti ọkunrin yii fi dibo ti aṣofin nijọsi, ọtọ ni eyi to fẹẹ fi ṣe ti gomina yii, ki lo de ti ko le ko eyi to lo nijọsi silẹ? Ko le ko o silẹ nitori ayederu sabukeeti ni. Bi eeyan ba si ti ibi sabukeeti ti ọkunrin yii gba wo o, ati iru ijo to n fi agbalagba ara jo lagbo ti ẹni to ba farabalẹ kọ ẹkọ imọ ko le jo yii, tọhun yoo ti mọ pe adanwo nla ni yoo ba wọn l’Ọṣun bi iru ẹni bayii ba di gomina wọn. Bi PDP ba si ṣe misiteeki ti wọn fa iru rẹ kalẹ, awọn lọọya ni yoo gba kinni naa pada lọwọ wọn fun ẹgbẹ oṣelu mi-in. Aabọ ọrọ leleyii fọlọgbọn, bo ba de inu wọn ko di odidi. Bi ko si dodidi ko si wahala, oju gbogbo wa yii naa ni yoo ṣe.

(85)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.