Ẹyin pasitọ aye, ẹ kilọ fun Ọṣinbajo ko ma borukọ ara ẹ jẹ o

Spread the love

Awọn oloṣelu Naijiria yii ti ba nnkan jẹ, wọn ti purọ titi fawọn eeyan debii pe ko sẹni kan to n gba wọn gbọ mọ. Ọpọ wọn ko si lojuti nitori irọ ojukoroju bayii ni wọn maa n pa. Eyi ni ko ṣe si ohun kan bayii to tun jọ awọn ara Naijiria yii loju mọ. Ṣugbọn bi eeyan ba jẹ Pasitọ, tabi to ba pe ara rẹ bẹẹ, agaga to ba jẹ inu ijọ Ridiimu lo n lọ, awọn eeyan ṣi maa n foju ọmọluabi wo o, wọn yoo maa ro tiỌlọrun mọ ọn lara, pe eeyan to n fi orukọ Ọlọrun bayii ṣiṣẹ ko jẹ purọ. Eyi niIgbakeji Aarẹ Naijria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, yoo ṣe ṣọ ara rẹ gidigidi. Pasitọni, ọjọgbọn tun ni, amọ ibi ti orukọ rẹ n wọ lọ yii, kinni naa le bajẹ ju boun gan-an ti ro lọ. Ọrọ ẹnu rẹ lo si ko ba a. Lọsẹ to lọ lọhun-un, Ọṣinbajo lọ si ọdọAlaafin, nigba to si debẹ, ti ọti oṣelu pa a tan, ohun to sọ ni pe ki gbogboYoruba dibo fun Buhari lẹẹkeji yii, nitori ti wọn ba dibo fun un, iyẹn ni yoo fun wọn ni anfaani lati di olori ijọba Naijiria ni 2023, iyẹn ni pe bi wọn ba dibo naa lọdun naa, ọmọ Yoruba ni Buhari yoo gbe ijọba fun. Ọrọ naa daa, o dun-un gbọ leti. Afi ti pe Buhari funra rẹ ti sọ iru ọrọ yii lẹẹkan. Ohun ti Buhari sọ nigba ti akọwe ijọba rẹ, Boss Mustapha, lọọ ṣoju rẹ nibi ipade awọn aṣaaju Ibo ni peBuhari ni ki oun sọ fun wọn pe ki awọn Ibo dibo foun, pe ti wọn ba dibo foun, awọn ni oun yoo gbejọba fun lọdun 2023, nitori awọn nikan lo ku ti ko ti i ṣe olori ijọba Naijiria lati igba ti oṣelu yii ti bẹrẹ. Buhari n sọrọ yii lorukọ APC,Ọṣinbajo naa n sọ tirẹ lorukọ APC, wọn yoo gbejọba fun Yoruba, wọn yoogbejọba fun Ibo, bẹẹ ijọba yii kan naa ni, wọn ko si le gbe e fẹni meji lẹẹkan. Dajudaju, ẹni kan n purọ fun awọn ọmọ Naijiria ninu Buhari ati Ọṣinbajo, afi to ba jẹ awọn mejeeji kuku jọ n purọ ni, wọn ko ni ikan i ṣe ninu ọrọ ti wọn sọ yii. Ati pe beeyan ba fẹẹ wo o, nigba to jẹ Buhari lo nijọba rẹ, to si jẹ ko si ohun tiẹnikẹni le da ṣe ti ko ba lọwọ si i, eeyan yoo ti mọ pe ọrọ Ọṣinbajo ko le ṣiṣẹ ju ti Buhari lọ, ki i ṣe ninu iru ijọba ti wọn jọ n ṣe yii. Eyi lo ṣe yẹ ki gbogbo pasitọaye, bo jẹ ni Naijiria bo jẹ loke okun, kilọ gidi fun Ọṣinbajo, ko ma ba orukọ ararẹ jẹ, ko ma ba orukọ Ridiimu jẹ, ko ma sọ ohun ti oju rẹ ko ba to, ko si ma lọwọ si irọ pipa fun ọmo Naijiria rara. Bo ba si fẹẹ purọ fun Naijiria, ko ma purọfun Yoruba o, nitori ilẹ Yoruba lo n pada bọ bo ba gbe ijọba rẹ silẹ tan, ohun ti oju rẹ yoo si ri lẹyin to ba pada wale, oun paapaa ko ni i le fẹnu ara rẹ sọ. Ẹkilọ fun un o.

 

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.