“Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ ma jẹ irẹsi ilẹ okeere mọ o, ko daa fun alaafia yin.” Lai Muhammed.

Spread the love

Minisita fun eto iroyin ati aṣa, Alaaji Lai Muhammed, lo sọ bayii fawọn oniroyin nipinlẹ Eko. O ni ijọba Naijiria ko le sọ bi awọn irẹsi naa ṣe daa to fun alaafia awọn ọmọ Naijiria.

O ni pupọ ninu awọn raisi yii ni awọn onifayawọ gbe wọlu lati awọn orilẹ-ede Benin Republic, Niger ati Cameroon. Bẹẹ ilẹ India ati Thailand ni wọn ti n gbin ọpọlọpọ awọn raisi wọnyi, yoo si lo ọpọlọpọ oṣu lori omi ko too de orilẹ-ede Naijiria.

Lai Muhammed ṣalaye siwaju si i pe awọn orilẹ-ede ti wọn n gba ibẹ ko awọn irẹsi yii wọle gan-an ko ki i jẹ awọn irẹsi ọhun, awọn ọmọ Naijiria ni wọn n ko o wa fun.

O waa rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn maa ra irẹsi awọn agbẹ wa, o daa o si ṣara loore ju awọn irẹsi ilẹ okeere ti wọn ti po mọ oriṣiiriṣii kẹmika lọ. O ni titi ọdun 2020, Naijiria naa yoo le maa jẹ ajẹyo ati ajẹṣẹku ninu raisi orilẹ-ede wọn, tori awọn ileeṣẹ nla nla ti lọwọ si ọrọ naa bayii

 

.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.