Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ dide, ẹ gba ara yin lọwọ awọn oṣelu ole yii

Spread the love

Ko si ohun to le mu eeyan kan ṣe ohun ti awọn oloṣelu Naijiria n ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii ju ailojuti lọ. Bi eniyan ko ba ti lojuti, ko si iwa ti ko le hu: o le jale, o le purọ, bo si jẹ obinrin ni, o le maa yan ale kiri nile ọkọ. Tabi ẹyin naa ko ri iran wọn wo ni, niṣe ni wọn n rọ girigiri kuro ninu ẹgbẹ APC bayii, wọn n sa lọ sinu ẹgbẹ PDP ti wọn ti kọ silẹ nigba kan. Bẹẹ naa lawọn mi-in n pariwo pe eyi ti awọn ti ṣe ninu PDP to, awọn naa n sa lọ sinu ẹgbẹ APC. Tẹlẹtẹlẹ ni wọn yoo purọ pe awọn eeyan awọn kan lo ni ki awọn maa lọ, awọn eeyan ilu awọn tabi adugbo awọn lo ni ki awọn fi ẹgbẹ ti awọn n ṣe tẹlẹ silẹ , ki awọn sa lọ sinu ẹgbẹ mi-in, ṣugbọn ti asiko yii yatọ, ko kuku tilẹ si aaye a n ṣe alaye kan fẹnikan, kaluku n bọọlẹ ninu ọkọ ti wọn ti n wọ bọ tẹlẹ, wọn n sa wọ inu ọkọ mi-in lọ ni, oju ọna lawọn araalu wọn tabi ara adugbo wọn si ti n pade wọn. A ti n sọrọ yii tipẹ pe oloṣelu kan to ba nilaari, to jẹ olododo, to ṣee tẹle ki i kuro ninu ẹgbẹ oṣelu kan bọ sinu omi-in, nitori o ti gbọdọ ronu daadaa, ko ṣe arojinlẹ ko too di ọmọ ẹgbẹ oṣelu kankan rara. Ki i ṣe ibi yii nikan ni wọn ti n ṣe oṣelu, wọn n ṣe e kaakiri aye ni. Ṣugbọn ni awọn orilẹ-ede to goke agba, ko si oloṣelu kan ti yoo ti ẹgbẹ oṣelu kan bọ si omi-in, ki i ṣee ṣe fun wọn rara ni. Bi oloṣelu kan ba fi ẹgbẹ rẹ silẹ ni UK, tabi ni Amẹrika, ẹni bẹẹ yoo ya mọ kede pe oun ko ṣe oṣelu mọ ni, ki i ṣe ko kuro ninu ẹgbẹ to n ṣe, ko sare bọ sinu ẹgbẹ mi-in, awọn oloṣelu ti ko mọ ohun ti wọn n ṣe, ti wọn ko nifẹẹ adugbo wọn tabi araalu kan ni wọn maa n ṣe bẹẹ. Bi ẹ si wadii ẹ lọ ti ẹ wadii ẹ bọ, nitori apo ara wọn ni wọn ṣe n ṣe ohun ti wọn n ṣe. Ṣe ẹ ri i, awọn oloṣelu ti ẹ n ri yii, ninu gbogbo wọn, ko si ẹni ti yoo mu oore kan ba Naijiria ninu wọn. Idi ni pe omi ibajẹ ni wọn fi ṣe ẹda wọn, ninu ibajẹ ni wọn ti wo wọn dagba, ibajẹ ni wọn yoo si maa ṣe titi aye wọn. Bi awọn ọmọ Naijiria ba gbọn, awọn ni wọn le gba ara wọn silẹ lọwọ awọn oloṣelu ole, awọn onijẹkujẹ, awọn ọbayejẹ ti wọn n sa kuro ninu ẹgbẹ kan bọ sinu ẹgbẹ mi-in nitori atijẹ, ati nitori ki wọn le wa nipo agbara. Bi wọn si wa nipo agbara naa nkọ, kin ni wọn yoo maa ṣe nibẹ, ibajẹ naa ni o! Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ dide, ẹ gba ara yin lọwọ awọn oloṣelu ole.

 

(38)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.