ẹyin oṣu kan, awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ pada sẹnu iṣẹ l’Ekiti

Spread the love

Ana, ọjọ Aje, lawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Ekiti pada sẹnu iṣẹ lẹyin bii oṣu kan ti wọn ti daṣẹ silẹ latari awọn owo kan tijọba to kogba sile jẹ wọn.
Nibi ipade pajawiri to waye niluu Ado-Ekiti lọjọ Aiku, Sannde ijẹta, lawọn adari ẹgbẹ Nigeria Union of Local Government Employees (NULGE) to jẹ apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ti kede ọrọ naa.
Ninu atẹjade kan ti alaga wọn, Ọgbẹni Bunmi Ajimọkọ ati akọwe, Ọgbẹni Aleru Suleiman, fọwọ si, wọn ni idi tawọn fi gbe igbesẹ naa ko ju bi Gomina Kayọde Fayẹmi ṣe ti bẹrẹ si i san awọn owo tijọba atijọ jẹ awọn kiakia.
‘’A ti pinnu pe nitori bi ijọba tuntun yii ṣe ti n san awọn owo ajẹmọnu wa diẹdiẹ pẹlu bi wọn ṣe ti gbe e fun awọn ijọba ibilẹ, tawọn oṣiṣẹ kan si ti n ri i gba, a fagile iyanṣẹlodi ta a bẹrẹ bii oṣu kan sẹyin.
‘’Gbogbo oṣiṣẹ la n reti lẹnu iṣẹ lati asiko yii lọ. A fi asiko yii dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan wa fun aforiti ati ifọwọsowọpọ ti wọn fun wa lasiko ti a n ja fun ẹtọ wa.
‘’Lakootan, ẹgbẹ yii dupẹ lọwọ Ọmọwe Kayọde Fayẹmi fun igbesẹ akin to gbe lori ọrọ yii.’’

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.