Ẹyin naa ẹ gba f’Ọlọrun bii Ambọde—-Buhari

Spread the love

Bakan naa ni Aarẹ Buhari rọ awọn ti wọn ni ijakulẹ ninu ipo kan tabi omi-in ki wọn gba kamu, ki wọn si gba abajade awọn esi idibo to waye kaakiri awọn ipinlẹ naa.

Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Garba Sheu, lo gbẹnu Buhari sọrọ yii lọsẹ to kọja.

O ṣalaye pe bi idije ba waye, kinni kan to daju nibẹ ni pe awọn kan maa yege, awọn kan maa ni ijakulẹ. O waa rọ gbogbo awọn ti wọn ni ijakulẹ naa pe ki wọn ma tori eyi fi ẹgbẹ naa silẹ, ki wọn gbiyanju lati wo awokọṣe gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambọde, to jẹ pe oun naa kuna ninu ibo abẹle lati dupo gomina lẹẹkeji nipinlẹ Eko, ti ko si tori eyi fi ẹgbẹ naa silẹ.

(37)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.