Ẹyin gomina ilẹ Yoruba, oju yin la n wo o

Spread the love

Idunnu lo jẹ nigba ti awọn gomina ilẹ Yoruba yari pe awọn ko ni ilẹ ti awọn yoo fi fun awọn Fulani Oni-RUGA. Ṣe adura ti gbogbo aye si n gba bayii ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ki wọn ko wa mọ RUGA, nitori ohun ti ko dara ni, oore ẹdẹ buruku, oore ti igbẹyin rẹ ko ni i dara ni. Awọn gomina ilẹ Yoruba ṣepade, wọn ni awọn ko ni ilẹ, awọn o si fẹ abule bẹẹ lọdọ awọn, ohun ti awọn fẹ ni oko maaluu ti awọn funra awọn yoo ṣe, ti wọn yoo si mọ bi awọn yoo ti ko eeyan awọn ati awọn mi-in ti awọn ba tun fẹ ti iwa wọn ba ofin ti awọn ba la silẹ mu sibẹ. Ko si ohun to dara to o. Eyi ti ijọba Buhari n fẹẹ ṣe yii, atẹyin-rọgbọn lasan ni. Bi wọn ba fẹẹ ṣe eto bayii ti wọn si ka araalu si, ti wọn ka awọn gomina paapaa ti wọn n ṣejọba wọn si, o yẹ ki wọn ti kọkọ jọ jokoo ki wọn jọ sọ ọ ni, ki wọn si jẹ ki awọn eeyan naa lọọ fi lọ awọn eeyan tiwọn nile, ki wọn too maa kede awọn eto raurau bẹẹ. Ṣugbọn ijọba Buhari mọ ohun ti wọn n ṣe. Wọn mọ pe ti ọrọ yii ba ti jade si aarin ilu, ko sẹni ti yoo gba ki wọn gbe eto buruku bẹẹ wa si agbegbe oun, ohun ti wọn ko ṣe sọ fawọn gomina wọnyi niyẹn. Ọlọrun si ti ba awọn gomina wa ṣe e, ofin to wa ni Naijiria ni pe awọn gomina lo ni ilẹ wọn, gbogbo ilẹ to ba wa ni ipinlẹ kan, gomina lo ni in, oun lo ni aṣẹ ibẹ, ohun to ba si wu u lo le fi ṣe. Bi gomina kan ko ba fun ẹnikẹni laaye lati lo ilẹ rẹ, koda ko jẹ ijọba apapọ ju bẹẹ lọ, wọn o le lo o. Iyẹn ni awọn gomina wa ṣe gbọdọ mu ọrọ naa ni lile, ki wọn ri i pe awọn o fẹnikan laaye lati lo ilẹ wọn fi ṣe RUGA, ki wọn si tẹle ohun ti wọn jọ sọ laarin ara wọn. Bo ba jẹ pe iṣẹ ẹran-sinsin ati maaluu tita ni ijọba fẹ ki wọn da silẹ ni ipinlẹ kọọkan, ko sohun to buru nibẹ, ki wọn ko owo fun gomina ko fi da a silẹ, ko si ṣe e ni ilana ti yoo fi ba awọn eeyan ipinlẹ rẹ mu. Ki i ṣe ki ijọba apapọ gba ilẹ onilẹ ko ni oun kọ abule RUGA sibẹ, ki awọn Fulani de, ki wọn ni ilẹ baba awọn ni. Iyẹn ko ṣee ṣe. Asiko yii ki i ṣe asiko oṣelu, bẹẹ ni ki i ṣe asiko ti gomina Yoruba kan yoo maa tako ekeji rẹ, asiko ti gbogbo wọn gbọdọ ṣiṣẹ pọ niyi. Tabi ere wo ni ẹgbẹ oṣelu APC tabi PDP yoo jẹ nibẹ nigba ti awọn Fulani ba gba ilẹ Yoruba! Oriire wo lo fẹẹ mu ba wọn? Gbogbo gomina ilẹ yii lo gbọdọ ṣiṣẹ pọ lati le awọn irunbi yii lugbẹ, eyi ti ko ba si lọ ninu wọn, ki awọn alalẹ ilẹ yii fi iku oro pa wọn, bo ba di kanran ki wọn maa pa awọn eeyan wa, ki wọn si maa ji wọn gbe, ki wọn maa fipa ba awọn obinrin olobinrin sun kiri. Lasiko yii lẹ gbọdọ fohun kan sọrọ, bẹ ẹ ba dewaju Buhari, ẹ duro ba a sọrọ pe awọn eeyan yin ko fẹ RUGA, bẹẹ ni ẹ ko ni ilẹ ti ẹ fẹẹ fi fun Fulani o. A ki i wi sibẹ ka ku sibẹ, ko si ohun ti wọn yoo fi yin ṣe, paapaa bi ohun yin ba ti ṣọkan. Oju yin la n wo nilẹ Yoruba, gbogbo aye wa wa lọwọ Ọlọrun, o wa lọwọ yin o!

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.