Ẹyin ara Oke-Ogun naa, ẹ ma jẹ ki wọn gbe yin mọra

Spread the love

Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Igbakeji aarẹ wa, sọ fun wọn ni Ṣaki pe Buhari yoo kọ ile-ẹkọ giga poli fun wọn bi wọn ba dibo fun un. Ọṣinbajo wa l’Oke-Ogun lọsẹ to kọja yii, o de Ṣaki, o de Igbẹti, nigba to si ri awọn ọba wọn ṣajọ tan, o ni ti wọn ba le dibo fun Buhari, awọn yoo gbe poli wa si adugbo wọn. Akọkọ, iru awọn ileri bayii kọ lo yẹ ki ijọba kankan maa ṣe fawọn eeyan, nitori ojuṣe wọn ni lati kọ ileewe giga si awọn adugbo ti wọn ba mọ pe o yẹ ki wọn ṣe e si. Lati waa sọ eleyii di irinṣẹ idibo, ka maa tan awọn eeyan nitori pe ibo n bọ yii, nnkan ti ko daa ni o! Ati pe bi eeyan yoo ba wo awọn ohun ti ijọba yii ti ṣe lati ẹyin wa, ati awọn oriṣiriṣii ileri ti igbakeji aarẹ ti wọn gba iṣẹ lọwọ rẹ ni Abuja, ti wọn sọ loko kiri ko maa ṣe kampeeni yii n ṣe lati igba to ti n kiri, oluwa-rẹ yoo mọ pe yoo ṣoro ki ọkankan ninu awọn ileri wọnyi too ṣẹ. Ki i ṣe pe ẹni to ba fẹẹ dije ko le sọ pe oun yoo ṣe nnkan kan, ṣugbọn ki i ṣe iru awọn nnkan bayii, nitori lara awọn ohun to yẹ ki wọn ti fi ọdun mẹrin akọkọ wọn ṣe niyẹn. Bo ba jẹ wọn mọ pe iya ile-ẹkọ n jẹ wọn l’Oke-Ogun, ki i ṣe igba ti ibo n bọ yii ni wọn yoo maa lọọ fi iyẹn da wọn lọkan tolo, wọn yoo ti ṣe e fun wọn. Ohun ti ko si ye awọn ti wọn n ṣejọba yii maa n pọ ju eyi to ye wọn lọ. Bo ba jẹ wọn ti ṣe kinni naa fun awọn araadugbo yii, ti wọn ti kọ ileewe fun wọn, ti wọn si fun wọn ni awọn ohun amayedẹrun, koda bi wọn ko ba ri aaye de ọdọ wọn lati polongo ibo yii, awọn eeyan naa yoo dibo fun wọn, nitori wọn yoo ranti daadaa ti wọn ṣe. Bi ẹ ba ti ri awọn oloṣelu to jẹ lasiko ibo ni wọn yoo maa ṣeleri, ileri asan ni, iru ileri bẹẹ ko ni i jẹ mimuṣẹ laye. Ohun to kan n yaayan lẹnu ni ẹni to gbe iru iṣẹ bayii le Ọṣinbajo lọwọ, iṣẹ ti oun naa mọ pe pupọ ninu ohun ti oun n sọ kiri yii, irọ ni pupọ ninu ileri ti oun n ṣe kiri yii, ko ni i jẹ mimuṣẹ. Bi oun ba ro pe oṣelu lasan loun n ṣe, nigba to ba ya, Yoruba yoo beere awọn ọrọ yii lọwọ rẹ, nitori gbogbo ohun to n sọ yii ni wọn n kọ silẹ. O ti sọ bayii pe ki wọn dibo fun Buhari ko le jẹ Yoruba ni yoo gbajọba lọwọ ẹ ni 2023, imi-in lo tun sọ yii o, gbogbọ ẹ la n kọ silẹ, ọjọ n bọ ti a oo beere awọn ohun gbogbo to ba sọ. Oun naa ko kuku le sọ pe oun ko mọ ohun to n lọ, ko le sọ pe oun ko mọ pe wọn n lo oun ni, nigba ti wọn ba si lo o tan ti wọn ba sọ ọ silẹ, oju oun naa yoo mọ, oju oun naa yoo ja a. Ṣugbọn ko ma sọ Yoruba lẹnu o, ohun to ba ṣe, ko mọ pe oun loun fọwọ ara oun ṣe e o.

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.