Ẹyin ara Kogi, ẹ kuutọju Dino Melaye

Spread the love

Wọn ma tun ni ara Dino Melaye ko ya o, ọsibitu lo wa bi a ti n sọrọ yii. O da bii pe ara ọkunrin naa ti mọ igba to ba ni wahala, ko kan ni i ya mọ rara ni. O jọ pe ara Dino Melaye da igba ti awọn ọlọpaa ba fẹẹ gbe e mọ, ara rẹ yoo kan daṣẹ silẹ ni, ni yoo ba dẹni ti wọn n gbe digbadigba kaakiri. Awọn ọlọpaa naa ni lọwọ o, amọ Dino naa di mẹru. Ẹni ba gbọ ẹjọ buruku ti awọn ọlọpaa n ro kiri bayii, yoo ro pe nitori ohun ti wọn ṣe fẹẹ mu Dino niyẹn. Wọn ni ẹjọ kan ti wa ni Kogi lati ọjọ diẹ sẹyin, lati igba ti wọn ti mu awọn kan ti wọn ni wọn fẹẹ ṣe jamba, wọn fẹẹ pa awọn eeyan ni Kogi, ti awọn yẹn si sọ pe Dino wa lara awọn to n ran awọn, lati igba yẹn ni wọn ti ni ki Dino waa ṣalaye ohun to ba mọ nipa awọn ibọn ati ohun ija mi-in ti wọn ba lọwọ wọn, atigba yẹn ni Dino ti n sa kiri. Bi awọn ọlọpaa ba fẹẹ mu un loni-in, yoo sa lọ, bi wọn ba si ri i mu ti wọn gba beeli ẹ, yoo tun lọ, wọn o ni i ri i. Atigba yẹn lo ti di pe bii ẹkun ati ologbo lawọn ọlọpaa ati Dino n ṣe. Bi ko ba si wahala, ti Dino ba n ṣe daadaa, agaga ti ko ba bu Buhari, awọn ọlọpaa yoo ṣe bii ẹni pe awọn ko ri i ni. Amọ to ba ti bu Buhari, tabi to ba fẹẹ da ija kan silẹ ni Kogi, tabi ti ọwọ oṣelu ẹ ba jọ pe o fẹẹ le ju, awọn ọlọpaa yoo lọọ jokoo de e nile, wọn yoo ni awọn gbọdọ mu un. Ohun to ṣẹlẹ ni teleyii naa niyẹn. Awọn eeyan yii fẹẹ mu Dino nitori wọn ro pe o wa lara awọn ti wọn ho le Buhari lori nigba to lọ sile-igbimọ aṣofin lọsẹ to kọja lọhun-un. Ṣe awọn kan ho le e lori, wọn pariwo ole ati opurọ le e lori nile-igbimọ aṣofin, awọn to tẹle e si nigbagbọ pe ko si bi wọn ṣe le ṣe iru rẹ nile-igbimọ ti Dino ko ni i mọ, nitori ọga awọn onijangbọn gidi loun naa nibẹ. Ohun ti wọn ṣe fẹẹ mu un niyẹn, iyẹn naa si loun naa ṣe sa fun wọn. Amọ nigba ti wọn jokoo sile ẹ fun ọsẹ kan ti wọn ko lọ, ti Dino ṣe kasẹẹti jade ti ko ta, oun naa jade ninu ibi to sa pamọ si ninu ile ẹ nibẹ, o ni ki wọn maa gbe oun lọ si ọdọ ọga awọn ọlọpaa pata, nigba ti wọn si de ọhun, lo ba di wẹjẹ, Dino ṣubu lulẹ, o lara oun ko ya o, bẹẹ lo si n mi pokanpokan bii ẹni ti ọjọ iku rẹ ti pe gan-an. Lọrọ kan, ọsibitu ni Dino wa, o n gba itọju lọwọ. Ṣugbọn ki lo de ti Dino naa n sa fawọn ọlọpaa, ṣe oun naa mọ nipa ibọn ati awọn ohun ija mi-in tawọn tọọgi Kogi n ko kiri ni. Tabi ka ni ki lawọn ọlọpaa naa ko kuku ba a ṣe ẹjọ ti wọn ba fẹẹ ba a ṣe kia ki gbogbo ohun to n run si tan nilẹ! Ọrọ naa ko yeeyan jare. Amọ titi igba ti wọn yoo wọ Dino dele-ẹjọ lati ọsibitu to wa, ẹyin ara Kogi, ẹ kuutọju ọmọ yin o.

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.