Ẹyin ara Ibadan, ẹ ma fun wọn lowo mọ o

Spread the love

Wọn ni awọn kan wa ni Ibadan bayii ti wọn lọọ duro sibi ti awọn eeyan ti n gba kaadi idibo, ti wọn si n gba owo lọwọ wọn. Nibi ti awọn eeyan ba ti pọ si ti wọn fẹẹ gba kaadi ni o, awọn kan aa waa sọ fun wọn pe ki wọn mu owo wa, awọn le ṣe e ti wọn yoo fi tete wọle. Bi wọn ba si ti gba owo yii loootọ, wọn yoo lọ sinu ile nibi ti wọn ti n ṣeto kaadi naa, ko si ni i pẹ ti wọn yoo fi waa pe wọn pe ki wọn maa bọ, wọn yoo si ri kaadi idibo gba. Awọn ti wọn ti wa nibẹ lati aarọ ko ni i ri kaadi gba o, nitori ko ti i kan wọn, kinni naa si ti n ṣẹlẹ kaakiri ọpọlọpọ agbegbe n’Ibadan. Ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn ti wọn n fun wọn ni kaadi idibo yii ti ja ọgbọn tuntun kan ni o, ọgbọn naa si ni ki wọn ko kaadi pamọ, ki wọn ma tete da awọn eeyan lohun, wọn si ti ni awọn agbero ti wọn wa nita, awọn agbero yii lo n ba wọn pero sọkọ, wọn n gba owo lọwọ awọn eeyan ti wọn ba fẹẹ tete gba kaadi tiwọn. Ẹ ma fun wọn ni owo kankan o, kaka bẹẹ, ẹ lọọ fẹjọ wọn sun ni tọlọpaa, bi awọn ọlọpaa naa ba si ti darapọ mọ wọn, ẹ fẹjọ wọn sun oloṣelu to ba wa nitosi yin, bo ba si jẹ awọn oloṣelu yii wa ninu awọn ti wọn n ṣe eleyii, ẹ fẹjọ sun ijoye yoowu to ba wa ni agbegbe naa, ẹ lọ si ọfiisi lọọya to ba wa nitosi, ẹ wa ẹnikẹni to ba lẹnu diẹ kẹ ẹ fi ọrọ naa to o leti, ki wọn si ṣeto lati mu iru awọn ọbayejẹ bẹẹ. Ko sẹni to ran wọn ki wọn  gba owo lọwọ yin, ko si sẹni to gbọdọ sanwo kan lati gba kaadi idibo rẹ. Bi ẹnikẹni ba n gba owo lọwọ yin, o n rẹ yin jẹ ni, ẹ ko si gbọdọ gba ẹnikẹni laaye lati ṣe bẹẹ. Yatọ si iyẹn, iwa ibajẹ patapata gbaa ni ẹni to ba ṣe bẹẹ n hu, lara ohun ti a si n sọ naa niyẹn, nitori nigbẹyin, ara ohun ti yoo ba eto idibo to n bọ yii jẹ ni. Ẹ ma fun wọn lowo kankan o, ẹ ma si ṣe gba wọn laaye ki wọn ṣe iru eleyii gbe. Ẹ fẹjọ wọn sun, ki ọlọpaa mu wọn, ki wọn si ba wọn ṣe ẹjọ ẹ. Ẹ ma jẹ ki ẹnikẹni ba eto idibo yii jẹ, ẹ ma si ṣe jẹ ki ẹnikẹni rẹ yin jẹ. Ẹ kilọ fun gbogbo ẹni to ba n ṣe bẹẹ paapaa, ẹ ran an leti pe ẹwọn lo fi n ṣere tiyẹn ti ko ba mọ.

 

(23)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.