Ẹyin APC Ọṣun, ẹ ku amojuba Omiṣore

Spread the love

Nigba ti a n sọ lọjọsi, o da bii isọkusọ. Wọn ni Iyiọla Omiṣore ko le wọ inu APC, wọn ni oun ati awọn Arẹgbẹ ko le ṣe ẹgbẹ kan naa, wọn loun lo mọ bi wọn ṣe pa Bọla Ige, oun ati awọn Oloye Bisi Akande ko le jokoo pọ laelae. Ni bayii, Omiṣore funra ẹ ti sọ pe ṣe o digba ti oun ba ṣẹṣẹ n pariwo ki awọn eeyan too mọ pe oun ti wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni. O ni oun ti di ọmọ ẹgbẹ naa, ko si si ohun to tun le fa idiwọ kan mọ ju ki oun maa ba ẹgbẹ naa ṣe lọ. Ohun meji ni Omiṣore n wa ni tiẹ: akọkọ ni pe o fẹẹ pada si ile-igbimọ aṣofin, ki owo le maa wọle bo ti n wọle tẹlẹ, ki agbara si pada de si i lọwọ nigba to ba ti n rowo gidi gba nile aṣofin. Lẹẹkeji, awọn EFCC ti mu Omiṣore ni ole, oun fẹẹ bọ kuro ninu okun wọn, nitori oun naa mọ pe gbogbo ẹdakẹdaa to ba ti wọ inu APC, ko si bi ẹṣẹ ati iṣedeede rẹ ti le pọ to, yoo di ọkan ninu awọn angẹli mimọ lẹsẹkẹsẹ ni. Nidii eyi, bi ara Ọṣun kan ba ro pe Omiṣore n lọ sinu APC lati tun ipinlẹ Ọṣun ṣe, oponu ni tọhun. Omiṣore ko lọ sinu APC nitori ẹnibọdi, nitori ọrọ ara tirẹ nikan ni. Awọn eeyan kan wa ninu APC Ọṣun yii ṣa ti wọn ni alaye lati ṣe fawọn eeyan o. Awọn bii Arẹgbẹ funra rẹ, awọn alukoro wọn bii Sẹmiu Ọkanlawọn ati awọn mi-in bẹẹ, titi dori Bọla Ilọri, atawọn ti wọn sun mọ wọn. Awọn yii ni ariwo kan ti wọn n pa seti gbogbo eeyan nigba yoowu ti Omiṣore ba ti fẹẹ du ipo nigba to fi wa ninu PDP, ohun ti wọn maa n sare sọ naa ni pe “Ta lo pa Bọla Ige?” Wọn mọ pe idahun to wa lẹnu ọpọ eeyan ni pe Omiṣore mọ nipa ẹ, wọn ko si ni i tori rẹ dibo fun un. Ni bayii, Omiṣore ti wa ninu ẹgbẹ wọn, o wa ninu APC, wọn yoo si jọ maa rira lojoojumọ nitori ọmọ ẹgbẹ kan naa ni wọn n ṣe. O yẹ ki Arẹgbẹ beere bayii o, ki Oloye Bisi Akande naa si beere, ki wọn beere lọwọ ọkunrin yii pe ta lo pa Bọla Ige bi wọn ṣe ti maa n beere tẹlẹ, boya wọn yoo gbọ ododo ti wọn n wa kiri. Ṣugbọn wọn o ni i beere mọ, nitori ninu awo kan naa ni wọn yoo ti jọ maa jẹun bayii. Ẹ wo iye awọn ọmọ Ọṣun ti awọn eeyan yii pa nigba ti wọn n ba ara wọn ja, ẹ wo iye awọn ti wọn ba aye wọn jẹ nitori ija Arẹgbẹ ati ti Omiṣore, ati ija Baba Akande ati Omiṣore yii kan naa. Ọlọrun nikan lo le ṣedajọ awọn oloṣelu yii, ẹni to ba n tori tiwọn ja, tabi to ba n paayan nitori wọn, onitọhun ni ko mọ eyi to kan ninu ọrọ ara rẹ, o kan n jẹ ki wọn fi oun rugbo lasan ni. Ọlọrun o ni i jẹ ka padanu, ẹ yẹra fawọn oloṣelu wọnyi, ohun ti kaluku yoo jẹ lo n wa kiri.

 

 

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.