Eyi t’Ọbasanjọ sọ yii naa, deede ni fun wọn ni Yewa

Spread the love

Bo ba jẹ ọrọ Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lawọn ara ipinlẹ Ogun yoo tẹle lasiko ibo to n bọ yii, gbogbo ilakaka ati ariwo Ibikunle Amosun, gbogbo idaamu Dapọ Abiọdun ati awọn eeyan rẹ ninu APC, gbogbo ṣagbaṣula ti Ladi Adebutu ati Buruji Kaṣamu n ba kiri ninu PDP, afaimọ ko ma jẹ Gboyega Nasir ti inu ADC ni yoo ko ere ọja jẹ mọ gbogbo wọn loju. Ọsẹ to kọja ni Ọbasanjọ gba ọwọ ọkunrin ara Yewa naa mu, lo ba sọ pe, “Eleyii ni ọmọ mi, ẹni ti inu mi dun si gidigidi, oun ni yoo wọle bii gomina ipinlẹ Ogun lọdun to n bọ!” Baba ki i deede sọrọ lasan, ko ma jẹ o ni ohun ti baba ọhun ti gbojule, tabi iran kan to ri ti awọn to ku ko ri, to fi mọ pe Gboyega Nasir ni yoo ṣe gomina Ogun tuntun. Awọn eeyan ti n sọ ọ tipẹ, wọn n sọ ọ lọtun-un, wọn n sọ ọ losi, wọn n pe Yewa lo kan, Yewa lo le ṣe e! Ṣugbọn ẹnu awọn ara Yewa funra wọn ko ko, eyi ti awọn naa si n ṣe ninu ọrọ ara wọn ni i joun. Ọtọ ni awọn Yewa to wa lati Ayetoro titi de Ibooro, de Imasai ati Joga ati awọn ilu to wa lagbegbe tiwọn. Ọtọ ni awọn ara Ilaro ti wọn ri ara wọn bii olori, ọtọ ni awọn Ibese de Igbogila titi wọ ilu Imẹko, Ilara ati awọn ilu to sun mọ orilẹ-ede Bẹnnẹ. Ọtọ waa ni awọn Ọta Awori titi de Atan, Owode, Ipookia Idi-Iroko, bi awọn naa ṣe lọ niyẹn. Ninu awọn yii, bi ẹni kan ba ti dide, bẹẹ lawọn to ku yoo sọ pe ki i ṣe ọmọ laduugbo tiwọn, wọn aa ni Yewa tiwọn ki i ṣe ojulowo, awọn eleyii lojulowo, kaka ki wọn si ba a ṣe, wọn yoo ba ara Ijẹbu tabi Rẹmo tabi awọn Ẹgba ṣe. Nibi yii ni iṣoro ti wa fun awọn ara Yewa yii, nitori awọn naa ko mọ ẹni ti wọn fẹẹ fa kalẹ laarin wọn. Ṣe ti ohun wọn ba ṣe ọkan ni, ẹni yoowu ti awọn oloṣelu ba fa kalẹ lati adugbo wọn, gbogbo wọn yoo dide lọwọ kan, wọn yoo duro ti i, wọn yoo si bẹ awọn agbegbe to ku bii Rẹmọ ati Ijẹbu tabi Ẹgba, lati ba wọn dibo fun un. Iyẹn ni wọn fi le ṣe ijọba ipinlẹ Ogun. Asiko tuntun kan lo delẹ fun awọn ara Yewa yii bo ba jẹ loootọ ni wọn fẹẹ ṣe gomina, yatọ si ariwo lasan ti wọn pa kiri. Bi wọn ba fẹẹ ṣe gomina Ogun loootọ, ki wọn dibo fẹni kan ki gbogbo aye tilẹ ri i pe Yewa lo dibo yii, wọn dibo fun ọmọ tiwọn naa. Ṣugbọn ti wọn ko ba ti ṣe bẹẹ, loootọ ni Ọbasanjọ sọ pe oun ri ayanfẹ ọmọ kan ti inu oun dun si gidigidi, o kan foju ri i lasan ni o, yoo ṣoro ki ọmọ rẹ to de Oke-Mosan, nile-ijọba. Ẹlẹru ni i kọkọ gbe e kawọn eeyan too ba a fọwọ kun un, bi awọn ara Yewa ko ba fa gomina kalẹ funra wọn, ko si ara Ogun ti yoo ba wọn lọwọ si i. Bo wu wọn ki wọn pariwo ju bẹẹ lọ, igbakeji ati igbakẹta ni wọn yoo maa jẹ, ipo kin-in-ni yoo si deewọ fun wọn. Bẹẹ ni wọn ko gbọdọ tori iyẹn bu ẹnikan tabi ba ẹnikan ja, bi wọn ba fẹẹ binu, ara wọn ni ki wọn ba binu, bi wọn ba si fẹẹ ja, ara wọn ni ki wọn ba ja, ki wọn ṣa maa ranti ni gbogbo igba pe awọn lawọn n fọwọ ara awọn ṣe ara wọn. Ẹni kankan kọ o.

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.