Eyi tawọn ara Amẹrika ṣe yii dara

Spread the love

Awọn ijọba Amẹrika ti ṣe ofin kan bayii fun awọn oloṣelu ati oṣiṣẹ ijọba Naijiria, wọn ni awọn o fẹ awọn ti wọn ba ti ṣeru lasiko ibo ti a di kọja yii, awọn ti wọn lọwọ si eru ṣiṣe, awọn ti wọn lo tọọgi, awọn ti wọn ji ibo ati bẹẹ bẹẹ lọ ni orilẹ-ede awọn. Wọn ni eyikeyii to ba fẹẹ lọ siluu oyinbo, iyẹn lọdọ awọn l’Amẹrika, awọn ko ni i fun un ni fisa o. Ẹni yoowu ti wọn ba si ti fun ni fisa ninu wọn tẹlẹ, awọn ti fagile fisa naa, ko si gbọdọ gberi mọ. Ninu awọn ti wọn ṣe bayii fun ni El-Rufai, ati ọkunrin to ṣeto idibo wọn ni ipinlẹ Ọṣun, pẹlu Rochas Okorocha, ati awọn mi-in bii tiwọn. O jọ pe wọn n reti ohun ti awọn adajọ ti ọrọ ẹjọ Atiku ati Buhari wa lọwọ wọn yoo ṣe ati ẹjọ ti wọn yoo da, ki wọn too mọ awọn mi-in ti wọn yoo fi orukọ wọn sinu ẹ. Boya awọn eeyan Atiku ni o, tabi awọn eeyan Buhari. O yẹ ki oju ti awọn ti wọn n ṣe ijọba Naijiria, ṣugbọn ibi ti ọrọ wa buru si ni pe a ko nitiju rara, awọn ti wọn n ṣejọba wa ko ni oju ti wọn n ti, bi wọn ba n pe wọn lole bayii, wọn yoo si maa gbe ọmọ ẹran jo ni. Bi wọn ba ni itiju ni, iru ohun ti Amẹrika ṣe yii to apero fun gbogbo wọn. O fihan pe awọn ibo ti wọn di kọja yii ki i ṣe ibo daadaa. Awọn araaata mọ pe eru ati ojooro buruku ni awọn ti wọn n ṣeto ibo ni Ọṣun ṣe. Wọn mọ, wọn si ri i, wọn mọ pe aburu gbaa lawọn oloṣelu yii ṣe fawọn eeyan Ọṣun, bo ba si jẹ Arẹgbẹ ko ṣe minisita ni, iba ṣoro fun un lati wọ orilẹ-ede Amẹrika pẹlu ofin yii. Ṣugbọn iru awọn eeyan bii Omiṣore yoo fara gba a, ati ọkunrin to jẹ oludari eto idibo naa nibẹ. Ẹni to ti mọ ẹni to wọle ibo, ṣugbọn to yi i pada pe dandan ni ki wọn tun ibo di nibi kan. Gbogbo agbaye mọ pe ojooro lo ṣe, awọn kan ni wọn si lo o lati ṣe bẹẹ, ṣugbọn oun naa ti fori ko o. Bẹẹ lawọn El-Rufai ṣe ni Kaduna, ọtọ lẹni to wọle, wọn yi kinni naa lojiji ni, ati ni Kano paapaa, awọn ti Okorocha si fi tipatipa mu pe ki wọn kede esi idibo oun sọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ fawọn aṣoju orilẹ-ede gbogbo nibẹ, ti awọn si pada sọ fawọn ijọba wọn. Awọn ti wọn ki i baa ṣe oloṣelu, tabi ti wọn ko ba lọ si ilu oyinbo ri, ti wọn ko si ni owo nibẹ tabi dukia, yoo ro o pe ki lo kan awọn Amẹrika ninu ọrọ Naijiria, ati pe ki lo wa nibẹ ti wọn ba ni ki wọn ma wa siluu awọn mọ. Awọn oloṣelu yii ko ni i wi bẹẹ, nitori pupọ ninu wọn, awọn owo yii ti wọn ji ko, ibẹ ni wọn n ko wọn si, awọn dukia ti wọn si ni nibẹ ko ṣee fi oju fo bẹẹ yẹn. Lati sọ pe ki wọn ma wọ Amẹrika yii, ijaya nla ni fun wọn. Lara iṣoro ti ko jẹ ki ọrọ tiwa yanju ni pe ninu ibajẹ bayii la ti n jẹ ti a ti n mu, a ko ni ofin to n mu wọn ti wọn ba ṣojooro lasiko idibo, a ko ni ofin to de awọn eeyan ti wọn ba ji ibo gbe tabi ti wọn ba lo tọọgi tabi ti wọn fowo ra ibo lasiko ti awọn araalu ba n dibo lati yan ẹni ti wọn ba fẹ. Awọn oloṣelu tiwa, bi wọn ba ṣe lo tọọgi to, tabi ti wọn ba ṣe fi owo ra ibo to, tabi ti wọn ba ṣe raaye ṣe ojooro to, bẹẹ ni wọn ṣe n lokiki to, bẹẹ si lawọn ẹgbẹ oṣelu wọn ṣe maa n ki wọn pe wọn mọ nipa eto idibo gan-an. Ṣugbọn ọmọ ti wọn ko ba kọ lati ile, ita naa ni wọn yoo ti kọ ọ wa, iyẹn lawọn Amẹrika ṣe fun wọn yii. Amọ ki wọn ma da a duro lori awọn yii nikan o, ko de ori awọn ẹbi wọn gbogbo ti wọn jọ n gbadun owo eru ati ti jibiti ti wọn n ri nidii oṣelu ọbayejẹ ti wọn n ṣe. Bẹẹ ni ki Amẹrika sọ fawọn orilẹ-ede to ku naa, ki wọn gba fisa wọn kuro lọwọ awọ oloṣelu ole to n ko owo wa wa si ọdọ wọn. Bi wọn ba ṣe bẹẹ, Naijiria yoo tiẹ roju diẹ. Awọn ole, alainitiju gbogbo!

(40)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.