Eyi ni itan igbesi aye Wolii Naomi, Olori tuntun laafin Ọọni ti Ile Ifẹ

Spread the love

Ki i ṣe iroyin mọ pe gbajugbaja iranṣẹ Ọlọrun to filu Akurẹ ṣebugbe, Wolii Oluwaṣeyi Ṣilẹkunọla Moronkẹ, tọpọ eeyan mọ si Wolii-Obinrin Naomi, ni olori tuntun laafin Ọọni ti Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji.
A ri i gbọ pe ọmọ bibi adugbo Odotu, nitosi aafin Ọsemawe, niluu Ondo, ni Alagba Oluwaṣeyi ati Oluṣọaguntan Funmilayọ Grace, ti wọn jẹ obi rẹ.
Olori Naomi ni ikẹta ninu awọn ọmọ mẹfa ti awọn obi rẹ bi, ilu Akurẹ ni wọn si bi i si ni nnkan bii ọdun mẹẹẹdọgbọn sẹyin.
Ileewe girama ‘Akurẹ Academy’ lo ti kawe jade, ko too di pe o tẹsiwaju lọ si Fasiti Adekunle Ajaṣin, to wa niluu Akungba Akoko, bo tilẹ jẹ pe ko pari ọdun kan tan ni fasiti ọhun ko too ko ẹru rẹ kuro nibẹ, nigba to ni Ọlọrun pe oun, koun lọọ bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ.
Lati kekere ni wọn lo ti bẹre iṣẹ Oluwa, to si n waasu nita gbangba ko too di pe o pinnu lati gba iṣẹ iranṣe naa lẹkun-un-rẹrẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2011.
Iṣẹ iranṣẹ to gba yii lo mu ki mama rẹ toun naa jẹ iranṣẹ Ọlọrun pa iṣẹ iranṣẹ tirẹ ti, to si lọọ darapọ mọ iṣẹ iranṣẹ ọmọ rẹ niluu Akurẹ.
Ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin lo ṣagbekalẹ ijọ tirẹ, eyi to pe orukọ rẹ ni ileeṣẹ iransẹ En-Heralds, siluu Akurẹ, nibi to fi ṣe ibugbe.
Ki i ṣe pe Wolii Naomi ti ni ilẹ kan nibi to kọ ijọ rẹ si gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nitori pe ileetura kan ti wọn n pe ni Sunview loun atawọn ọmọ ijọ rẹ ti n pade nigbakuugba ti wọn ba fẹẹ jọsin.
A ko ba ẹnikẹni ninu awọn eeyan olori ọhun nigba ta a ṣabẹwo sile rẹ to n gbe ninu Ẹsiteeti Ijapo, niluu Akurẹ, obinrin kan to n gbe layiika ile naa lo sọ ọ di mimọ fun wa pe gbogbo awọn eeyan rẹ ni wọn ti tẹle e lọ siluu Ileefẹ, ni kete to ti di olori laafin Ọọni.
Obinrin un sọ fun wa pe o ṣee ṣe ki awọn eeyan olori naa o ma ti i ronu ati pada siluu Akurẹ lasiko ta a wa yii, wọn maa duro si Ileefẹ titi ti wọn yoo fi pari gbogbo ayẹyẹ to rọ mọ ipo tuntun to ṣẹṣẹ de naa.
Ọkan ninu awọn to ti jọsin nile ijọsin Olori tuntun ọhun, Oluwasimi, sọ fun wa pe oun ko ti i le sọ ni pato ọna ti Wolii ati Ajihinrere obinrin ọhun yoo gba ti ipo tuntun to ba ara rẹ naa ko fi ni i ṣe idiwọ fun iṣẹ iranṣẹ to tori ẹ sa kuro ni fasiti, nibi to ti yẹ ko kẹkọọ gboye.
Olori ọhun lo sọ pe o ti figba kan riran si oun lasiko toun wa ninu oyun akọbi ọmọ oun pe oun gbọdọ gbadura daadaa, nitori pe ayanmọ toun yan latọrun ni pe oyun akọbi loun yoo ba ku.
Ibẹru ohun ti Olori ọhun sọ lo fa bi oun ṣe sa kuro ni ṣọọṣi ti oun n lọ tẹlẹ, toun si di ero ṣọọṣi rẹ.

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.