Eyi ni itan Igbesi aye akinwumi Isola, oga awon oluko ede Yoruba gbogbo

Spread the love

Nigba ti yoo fi to oṣu kan lẹyin ipapoda Ọjọgbọn Akinwumi Iṣọla, lẹta ti awọn ẹbi ẹ ti gba ki i ṣe kekere. Igbakeji aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, lo kọkọ kowe lati ba iyawo atawọn ọmọ oloogbe kẹdun, ọjọ kẹrin ni lẹta aarẹ orileede yii nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, tẹle e. Lẹyin naa awọn gomina ilẹ Yoruba kọ lẹta ibanikẹdun ranṣẹ sile oloogbe lọkọọkan. Awọn kan ti Amẹrika wa si Naijiria fun isinku ẹ paapaa.

 

Akanda eeyan n’Iṣọla lati kekere. Bi bẹẹ kọ, iba ti dero ọrun ṣaaju ọjọ iku ẹ pẹlu ọpọ ewu to ti la kọja. Ṣe ti eegun to n ba wọn gbe ni kekere ti wọn iba ti kan an loogun ni ka sọ ni, abi ti ọpọ eeyan to ti fẹnu kọ bii ẹni fẹsẹ kọ. Awada lasan loun si ro pe oun n ṣe loju ara ẹ. Sọrọsọrọ kan bayii lAkinwumi o jare, agaga to ba ri Adebayọ Faleti, ọrẹ ẹ pataki to doloogbe lọdun to kọja yẹn.

Boya obinrin kan ti wọn fi ṣe yẹyẹ lọjọ kan ni iba ti pa awọn mejeeji danu bo ba ṣe pe iyẹn lajẹẹ ni. Wọn ko mọ nnkan kan la ki i fi i ṣawada, bẹẹ ni wọn ko gba pe eeyan kan wa laye to kọja ẹni ti wọn le fi ṣe yẹyẹ.

Bi wọn ṣe ri iya naa to n ru igi bọ lọọọkan ni Akinwumi Iṣọla fọwọ tọ Faleti, to ni, “Wo o, Iya Alakara lo n bọ yẹn.” Iya naa ti fẹẹ de ibi ti wọn jokoo si ki wọn too dakẹ lori yẹyẹ ti wọn n fi i ṣe. Ṣe eebu ni ki wọn peeyan bẹẹ nigba naa, ẹni to ba sanra ni wọn fi maa n ṣe yẹyẹ bẹẹ. Obinrin onitiata to ti doloogbe nni, Iya Alakara, to jẹ iyawo Iṣọla Ogunṣọla lo n jẹ Iya Alakara ninu ere, eeyan si to sanra lobinrin naa.

 

Wọn o mọ pe ọrọ naa ta si iyẹn leti, o ti kọja ọdọ wọn diẹ ko too pada lọọ ba wọn, o ni “emi Iya Alakara ti ẹ n pe niyi o.” Ọrọ naa ba awọn òfinràn ọrẹ yii lojiji, n ni Faleti ba kọju si Akinwumi Iṣọla, o ni “Akara bawo, ki ni n oo fakara ṣe. Emi ki i jẹ ẹ. (o kọju si ọrẹ ẹ) Ngbọ, Akin, ṣe iwọ lo pe alakara.” Iyẹn naa ba dahun, o ni, ”Akara kẹ, nigba ti ki i ṣakara elepo.” Nigba naa lobinrin sisanra naa sun mọ Akinwumi Iṣọla, o ni, “Akara elepo naa ni.” Bẹẹ lọrọ di wo-mi-n-wo-ọ. Diẹ lo si ku ki obinrin naa fori sọ awọn asọrọ-sọ-boto ọrẹ meji yii laya.

Ìṣe wọn yii naa lo ba wọn dele ana, nibi ti wọn ti fi awọn obi iyawo ṣe yẹyẹ lọjọ igbeyawo ọmọkunrin wọn to bẹẹ ti awọn ẹbi iyawo iba fi gba ọmọ wọn pada lọwọ wọn bi ko ṣe pe wọn ti mọ awọn mejeeji bii gbajumọ eeyan lawujọ.

 

Gẹgẹ bi ọmọkunrin Faleti, Ọgbẹni Gbemi Faleti, to sọtan Iya Alakara ṣe fidi ẹ mulẹ l’Ọjọru, (Wẹsidee), to kọja ni gbọgan Civic Centre, l’Agodi, n’Ibadan, nibi ti awọn eeyan ti n sọ ohun ti wọn mọ nipa Oloogbe Akinwumi Iṣọla, o ni, “Ibi ti baba mi ati Ọjọgbọn Akinwumi Iṣọla ba wa maa n daru ni. Niṣe ni wọn maa n ṣawada ti awọn eeyan yoo si maa rẹrin-in arintakiti.

 

“Lọjọ ti mo ṣegbeyawo, awon mejeeji jokoo sẹgbẹẹ ara wọn. Ọjọgbọn Akinwumi Iṣọla waa pe mi, wọn ni, Gbemi, ṣe wọn o si gba idọbalẹ awa naa ba a ṣe dagba to yii, mo ni ẹ jẹ ki n gbiyanju lati ba awọn ana mi sọrọ na. Mo ba lọọ ba aburo iyawo mi pe jọwọ, ẹ mọ bẹẹ ṣe maa ṣeto yẹn ti awọn dadi ko fi ni i dọbalẹ ni tiwọn o. O ba ni haa, awọn obi oun wulẹ ti sọ pe awọn ko ni i jẹ ki wọn dọbalẹ tẹlẹ.

“Ṣugbọn lẹyin ti wọn fa iyawo le wa lọwọ tan, funra wọn (Akinwumi Iṣọla) naa ni wọn tun bọ siwaju ti wọn sọ pe, ‘Haa, awọn ana wa yii ma gọ o, wọn si fi odidi ọmọ tọrẹ lai gba idọbalẹ.’ Awon ni wọn si bẹbẹ pe ki wọn ma jẹ ki awọn dọbalẹ lọjọ yẹn o. Bi Ọjọgbọn Akinwumi Iṣọla ati baba mi ṣe maa n ṣawada niyẹn.”

 

Iwọnyii ni diẹ ninu ohun ti awọn eeyan sọ nipa Oloogbe Akinwumi Iṣọla

Gomina Abiọla Ajimọbi

Kọmiṣanna fun eto iroyin, aṣa ati irinajo afẹ ni ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Toye Arulogun lo ṣoju gomina nibi eto isinku Ọjọgbọn naa. Arulogun‎ sọ pe gomina ni ki n sọ fun yin pe iku Ọjọgbọn Akinwumi Iṣola ki i sọfọ, ohun ayọ ni, ka maa dunnu fun igbesi aye rere ti wọn gbe. Iwuri ni wọn jẹ fun wa nipinle Ọyọ, ogo ipinlẹ Ọyọ ni wọn.

 

Oduọla Joel Ọladọtun

Baba ni wọn jẹ fun mi nitori aburo baba mi ni wọn. Wọn si mu mi bii ọmọ nigba ti baba mi ko si laye mọ. Awọn ni wọn duro fun mi gẹgẹ bii baba lọjọ igbeyawo mi. ọpọlọpọ inawo to yẹ ka ṣe nibi igbeyawo mi gan-an, awọn ni wọn gbe bukaata yẹn. Awọn ni wọn ko jẹ ki n padanu anfaani ti mo ni lati lọ si Fasiti Ile-Ifẹ. Ẹni to ṣeleri fun mi lọjọ igbeyawo mi ja mi ni tanmọ-ọn, baba lo duro ti mi, awọn ni wọn gba mọto fun mi ti wọn ṣe eyi to pọ ju ninu inawo yẹn. Mi o le gbagbe wọn ninu aye mi. Gbogbo oore ti mo n ṣe fawọn alaini lonii, ọdọ baba ni mo ti kọ ọ.

 

Ẹgbẹyẹmi Oluwaṣẹgun

Aburo baba mi ni wọn, wọn si jẹ baba fun mi. Agba to tole ni wọn. Wọn laaanu. Ko si ẹni ti wọn ko kopa ribiribi ninu aye ẹ ninu gbogbo ẹbi. Gẹgẹ bi mo ṣe mọ wọn lati kekere, gbogbo ohun to ba jẹ ibanujẹ fun eeyan ni wọn maa n sọ dẹrin. Wọn ya mi lẹnu, gbogbo kọọsi ti mo ṣe nigba ti mo wa nibi iṣẹ, awọn ni wọn sanwo ẹ. Aburo mi to tele mi, awọn ni wọn ran an ni sukuu. Nigba ti baba wa ku, awọn ni wọn ra posi. Owo ti wọn na le idile wa lori lọdun 1986, Ọlọrun lo mọ iye miliọnu to maa jẹ. Lati igba ti baba mi ti ku, oṣooṣu ni wọn maa n fun iya wa lowo lati maa fi gbọ bukaata ile.

(183)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.