Eyi ni itan bi Lamidi olayiwola Adeyemi se di Alaafin 4

Spread the love

Ọrọ to wa nilẹ yii ti kuro ni kekere, nitori ọjọ itiju nla kan ni ọjọ kẹjọ, oṣu keje, ọdun 1968, jẹ fun Gomina Ologun Adeyinka Adebayọ ati ijọba rẹ. Abi nigba ti odidi gomina paṣẹ pe ki awọn afọbajẹ ilu Ọyọ, iyẹn awọn Ọyọmesi, fi Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ti wọn ti mu lati jẹ Alaafin tẹlẹ silẹ, ki wọn si mu Ọmọọba Sanda Ladepo Ọranlọla Adeyẹmi, ki wọn fi orukọ naa ranṣẹ soun gẹgẹ bii Alaafin, ṣugbọn ti awọn Ọyọmesi tun ṣepade, ti wọn ni awọn ko le mu Ọranlọla kankan, Layiwọla ti awọn ti mu tẹlẹ lawọn yoo tun mu, ko si ohun ti awọn le ṣe si i. Ipade ti wọn si ṣe ki i ṣe awọn nikan ni wọn ṣe e, ijọba funra rẹ ran aṣoju wa, oju rẹ si ni awọn marun-un ninu awọn meje ṣe dibo, ti wọn ni Lamidi lawọn fẹ, awọn ko fẹ Sanda, bẹẹ ni awọn ko ni i mu ẹni meji lẹẹkan, ẹni ti awọn ti mu yii naa ni tawọn, ijọba lo ku ko ṣe ohun to ba fẹẹ ṣe. Iṣẹ yii naa ni oniṣẹ gbe lọ sọdọ Adebayọ gomina, lọrọ ba dariwo.
Ki i ṣe lọdọ awọn ijọba nikan ni ọrọ yii ti di ariwo o, o dariwo l’Ọyọọ paapaa. Nitori ko sẹni to mọ ibi ti ijọba yoo ba yọ si Ọyọmesi ni, nitori awọn naa mọ pe ọrọ ti di wahala bayii, ọtọ ni ẹni ti ijọba fẹ, ọtọ ni ẹni ti awọn ara Ọyọ fẹ, bo si tilẹ jẹ pe ẹni ti awọn ara Ọyọ fẹ lawọn Ọyọmesi fẹ, sibẹ, agbara ijọba ju ti gbogbo awọn ara Ọyọ yii lọ. Ṣugbọn awọn Ọyọmesi ti ṣe oju awọn ara Ọyọ daadaa, wọn ti taku mọ gomina lọwọ, wọn ti gbena wo o loju pe ko le halẹ mọ awọn, ọrọ naa si ti di ibinu nile ijọba. Ijọba funra rẹ ti bẹrẹ si i ronu ohun ti wọn yoo ṣe fun awọn Ọyọmesi yii, ati awọn ti wọn n gbo wọn lẹnu ni Ọyọ, nitori ko si ohun to n lọ niluu naa ti awọn ti wọn fẹ tijọba ati ti Ọranlọla ki i sare lọ si ilu Ibadan lati sọ fun wọn. Bi ijọba si ti n gbọ ọrọ naa ni inu n bi ijọba si i, won n beere pe ki lawọn ara Ọyọ yii gbojule ti wọn n tapa sofin ijọba, bẹẹ awọn naa mọ pe ofin ijọba yii ko daa.
Ni ọjo keji ti awọn Ọyọmesi ṣepade tiwọn ti wọn kọ ọrọ sijọba lẹnu yii, gomina Adeyinka Adebayọ pẹlu awọn ọmọ igbimọ rẹ ti wọn n paṣẹ ijọba Western State sare pe ara wọn jọ, wọn ni awọn ṣepade kan lori ọrọ Ọyọ yii, nitori ọrọ naa ti di kọlukọlu, to jẹ bo ti n kọlu ara Ọyọ lo n kolu wọn n’Ibadan, awọn ti wọn n ṣejọba si fẹẹ wa nnkan ṣe si i. Ko sẹni to mọ igba ti wọn ṣepade wọn tabi ohun ti wọn sọ, afi nigba ti ọrọ jade lọjọ keji ti wọn ni awọn ṣepade yii, iyẹn ni ọjọ kẹwaa, oṣu keje, ọdun 1978, tawọn oniwee iroyin si gbe e jade ninu beba wọn lọjọ kọkanla, oṣu naa. Ninu iroyin yii ni ijọba ti tun ṣekilọ fawọn Ọyọmesi, ti wọn si tun paṣẹ fun wọn. Wọn ṣalaye ninu lẹta kan ti wọn kọ pe ipade ti awọn Ọyọmesi ṣe yẹn, ti wọn ni Lamidi Ọlayiwọla lawọn mu, ipade naa ki i ṣe tawọn o, bẹẹ ni ki i ṣe ohun ti awọn ni ki wọn ṣe ni wọn ṣe, ipade ti wọn ṣe yii, tara wọn ni.
Ijọba ni ki awọn eeyan naa pada lọọ jokoo, awọn ko ni i kọwe si wọn lẹẹkeji mọ o, iwe ti awọn yoo kọ si wọn lori ọrọ naa gbẹyin niyẹn, ohun ti awọn si kọ sibẹ yii naa ni yoo ṣẹlẹ, boya wọn fẹ o, boya wọn kọ o. Ijọba ni ni deede aago mẹsan-an owurọ ọjọ kọkanla, oṣu keje, 1968, ki awọn afọbajẹ Ọyọ yii tun lọọ ṣepade mi-in, nibi ipade naa ni ki wọn si ti tun ero wọn pa, ọrọ ti wọn sọ ni Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu yii, kan naa, ki wọn sọ pe awọn ko sọ bẹẹ mọ, awọn ti gba lati ṣe ohun ti ijọba ni ki awọn ṣe, ki wọn si fi orukọ Sanda Ọladepo Ọranlọla ranṣẹ si awọn gẹgẹ bii ẹni ti yoo jẹ Alaafin ilu Ọyọ. Wọn ni bi wọn ba ti ṣe bẹẹ, ko ni i si ariwo mọ, bẹẹ ni ko ni i si ija kankan. Ati pe bi wọn ba ṣe bẹẹ, awọn ati ijọba yoo di ọrẹ ara wọn, ohun ti awọn Ọyọmesi ba si fẹ lati ọdọ gomina ni gomina yoo ṣe fun wọn. Ṣugbọn bi wọn ko ba ṣe bẹẹ, ti wọn ba tun ri gomina fin, nnkan yoo ṣẹlẹ si wọn.
N lawọn Ọyọmesi ba tun ṣa ara wọn jọ, wọn ni awọn yoo ṣepade laago mẹsan-an aarọ, nitori lẹta ti gomina kọ si awọn. Wọn ni awọn yoo ka lẹta naa, awọn yoo si jiroro le e lori, nitori ni gbogbo igba naa, wọn ko ti i mọ ohun to wa ninu lẹta, awọn naa n gbọ lori redio ati bi wọn ti ka a ninu awọn iwe iroyin ni. Ọlọrun si kuku ṣe e, ipade naa ki i ṣe ti awọn nikan mọ, awọn aṣoju ijọba yoo wa nibẹ, nitori wọn fẹẹ mọ ohun ti ijoye kọọkan ba ṣe nipade, wọn fẹẹ maa woju awọn ijoye Ọyọ yii bi wọn ti n sọrọ, wọn fẹẹ mọ ẹni to n gbo ijọba lẹnu ninu awọn Ọyọmesi, ki wọn le lọọ ṣalaye orukọ ati adugbo ẹni bẹẹ fun wọn nile ijọba. Eleyii gan-an lo n ba awọn ara Ọyọ lẹru, wọn ni pẹlu ihalẹ ati idunkooko-mọni ti ijọba n ṣe yii, afaimọ ki awọn Ọyọmesi ma juwọ silẹ, ki wọn bẹru, ki wọn ni awọn ko fẹẹ ṣẹ wọn, tabi pe awọn ko fẹẹ daran ijọba, ki wọn si ṣe ohun ti ijọba fẹ funjọba.
Iyẹn lo ṣe jẹ lẹgbẹẹ ile Baṣọrun Tijani Akano Eesuọla ti wọn ti ṣepade yii, niṣe ni awọn ara Ọyọ to sibẹ yika, bo tilẹ jẹ pe wọn ko pe wọn sipade naa. Awọn naa fẹẹ mọ ohun to n lọ ni, wọn ko si fẹ ki ohunkohun ṣe ẹyin awọn, bi ọrọ ba si di pe wọn yoo mu awọn Ọyọmesi, tabi ti wọn ba fẹẹ fiya jẹ ẹnikẹni ninu wọn, ki gbogbo wọn le dide si i. Yatọ si eyi, bi ọrọ naa ti gbilẹ to l’Ọyọọ ko le jẹ ki oloko kan lọ soko tabi ki olodo kan gba ọna odo lọ; ọrọ naa ti gba oko, o gba odo, lọwọ awọn araalu, kaluku lo n lakaka lati mọ ohun to n lọ. Bi awọn Ọyọmesi ti n wọ inu aafin Baṣọrun, bẹẹ lawọn araalu n pariwo orukọ wọn. Bi wọn ba ti ri wọn lọọọkan ni wọn yoo ti sọ funra wọn, “Baba Samu lo n bọ yẹn” tabi ki wọn ni “Akinniku lo n bọ yẹn o!”, awọn to ku yoo si gba ọrọ naa, bẹẹ ni wọn yoo maa kọrin, ti wọn yoo si maa pariwo lati fihan pe inu awọn dun si ijoye naa bo ti n wọle lọ.
Nigbẹyin, ẹsẹ awọn ijoye yii pe, wọn fẹẹ ka lẹta ti wọn kọ lati ọdọ ijọba ranṣẹ si wọn. Orukọ akọwe agba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Nathaniel Akinyẹmi, ni wọn fi kọ lẹta naa, nitori akọwe agba to wa nibẹ to n ri si ọrọ oye ati ti ijọba ibilẹ, Ọgbẹni Bateye, ti ku sinu ijamba mọto lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹrin, 1968, bẹẹ oun lo kọkọ wa nidii ọrọ naa tẹlẹ. Bẹẹ loootọ, orukọ akọwe agba lo wa ninu lẹta, awọn Ọyọmesi ati gbogbo ẹni to mọ nipa iṣẹ ijọba mọ pe gomina Adeyinka Adebayọ funra rẹ lo n sọrọ, nitori ohun ti a ba fọn fun fere ni fere n gbe jade, ohun to ba sọ ni akọwe agba yoo gbe jade. Bo si ṣe ri naa niyẹn, gbogbo awọn ti wọn n gbọ ohun to wa ninu lẹta ti ijọba kọ mọ pe ohun gomina awọn lawọn n gbọ, oun lo n ba awọn sọrọ, ki i ṣe akọwe agba kankan. Nigba ti alakooso ijọba ibilẹ Ọyọ, A. O. Oyediran, funra rẹ si ti wa lori ijokoo, awọn eeyan mọ pe ọrọ lati ọdọ gomina ni.
Nigba ti ipade naa bẹrẹ lawọn Ọyọmesi too mọ ohun ti ijọba wi loootọ, koko ohun to si wa nibẹ ni pe ijọba ni awọn ko gba awọn alaye ti wọn ṣe nijọsi pe awọn ti mu Lamidi Adeyẹmi, awọn ko si le yi orukọ rẹ pada si ti Ọranlọla Adeyẹmi. Ijọba sọ pe gbogbo awọn ofin ti wọn fi gbe ọrọ wọn lẹsẹ nipa eto bi wọn ti n jọba niluu Ọyọ ko ba awọn lara mu rara, awọn ko si gba alaye naa wọle nitori gbogbo ohun ti wọn n sọ yii, ilẹ ti ta si i, awọn ofin mi-in si ti wa to bori wọn. Nitori bẹẹ, awawi asan nijọba ka ọrọ awọn Ọyọmesi si, iyẹn ni ijọba si ṣe n gba wọn nimọran pe ki wọn ma fi ọwọ pa ida ijọba loju, nitori yoo ge wọn. Wọn ni atunse ni ipade ti wọn kọkọ waa ṣe naa wa fun, atunṣe kan ko si ju ki wọn mu ẹni ti awọn fẹ lọ. Bi wọn ba ti mu un, ti wọn si kọwe si gomina, ki wọn da gbogbo ọrọ to ku da awọn, awọn yoo yanju rẹ, ti ko si ni i si wahala kan nibi kan. N nipade ba bẹrẹ.
Ninu gbogbo ipade ti wọn n ṣe lati igba ti ọrọ Alaafin yii ti bẹrẹ, ipade ti ọjọ kọkanla, oṣu keje, ọdun 1968 yii, ni akoko ẹ kere julọ, nitori iṣẹju mẹta pere ni. Bi wọn ti ka lẹta naa ni awọn Ọyọmesi fi ohun kan naa sọrọ, iyẹn awọn marun-un ti wọn ti mu Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi tẹlẹ, wọn ni ko si ọrọ ninu lẹta yii, tabi ninu ipade ti awọn fẹẹ ṣe, nitori awọn ko sun nigba ti awọn ṣepade ti ọjọ Mọnde to kọja, awọn si mọ ohun ti awọn sọ nibẹ daadaa. Ohun ti awọn sọ ni pe Lamidi Ọlayiwọla lawọn mu, awọn ko le mu Sanda nitori pe o ni baba laye, bẹẹ ni Ifa paapaa ko mu un, Ifa sọ fawọn pe akoko rẹ yoo le koko fun awọn ara Ọyọ ni. Ṣe ki awọn waa ba aye ogunlọgọ awọn ara Ọyọ jẹ nitori ọrọ ijọba kan ni, wọn lawọn ko ni i ṣe bẹẹ, awọn ko si le yi ohun ti awọn ti wi pada, ijọba funra rẹ ni ko pada lọọ ronu, ko si ṣe ohun ti awọn araalu ba n fẹ fun wọn.
Niṣe ni awọn aṣoju ijọba nibẹ, A. O. Oyediran ati M. F. Taiwo, n wo ẹnu Baṣọrun Eesuọla Akano nigba to n sọrọ lorukọ awọn Ọyọmesi marun-un ti wọn dibo fun Adeyẹmi, ẹrin kan bayii ko si pa ẹnu wọn, nitori ọrọ naa wuwo ju wọn lọ. Ki Eesuọla too sọrọ lawọn Ọyọmesi to ku ti kọkọ wi tiwọn, bi wọn si ti n dide naa ni wọn n jokoo pada, nitori gbolohun kan naa lọrọ ti wọn n sọ, iyẹn naa si ni pe Lamidi Ọlayiwọla lawọn mu, ipinnu awọn ko yipada. Bẹẹ ni Baṣọrun sọ, bẹẹ ni Agbaakin sọ, bẹẹ ni Alapinni sọ, bẹẹ ni Samu sọ, bẹẹ naa si ni Akinniku wi. Awọn ijoye meji ti wọn mu Ọladepo Ọranlọla Adeyẹmi naa ni ipinnu tawọn paapaa ko yipada, iyẹn Aṣipa ati Lagunna. Ṣoki ti wọn sọrọ naa ree, ko si tun si ohun ti ẹnikan yoo wi le e, Baṣọrun si fontẹ le e pe ṣe awọn aṣoju ijọba naa ti gbọ, ibi ti awọn ti lọ naa ni awọn tun pada si, ibo awọn ti wọn fẹ ti Layiwọla ju tawọn ti Ladepo lọ.
Nigba ti Baṣọrun n ba awọn oniroyin sọrọ nita lẹyin ti wọn ti ṣepade oniṣẹẹju mẹta naa tan, o ni, “Eyi ti a n ṣe yii, ọrọ gomina wa, Ọgagun Adeyinka Adebayọ, naa ni a n tẹle. Oun lo ti sọ pe ko si ohun ti yoo fa a laye yii ti oun yoo fi gbe ọba ti awọn araalu ko ba fẹ le wọn lori. Awọn ara Ọyọ ko mu Ladepo, bi wọn ba mu un ni, ko si ohun ti awa ijoye le ṣe. Ṣugbọn nigba ti wọn ko mu un yii, ko si ohun ti awa Ọyọmesi le ṣe, ẹni ti ilu ba mu ni Ọyọmesi n mu. Bo ba jọ bii irọ, awa ti gba pe ki ijọba pe ipade nla si Atiba, ki gbogbo ilu peju sibẹ, ki wọn waa foju ara wọn ri ẹni to ba gbajumọ ju, ki wọn waa wo ẹni ti ilu ba fẹ ninu Layiwọla ati Ladepo, boya ọrọ naa yoo ye wọn ju bo ti ye wọn yii lọ!” Nigba ti awọn oniroyin tun bi i pe ṣe kinni yii ko ni i koba awọn Ọyọmesi, ti yoo fi di pe ijọba yoo binu, ti wọn yoo si yọ wọn loye, tabi ti wọn yoo ni ki awọn mi-in waa gba iṣẹ wọn ṣe.
Eesuọla Akano tun dahun: “Iyẹn ko le ṣẹlẹ. Ko le ṣẹlẹ nitori o ni idi ti wọn fi n yọ awọn Ọyọmesi. Ijọba le yọ wa bi a ko ba ṣe iṣẹ wa ni, ṣugbọn ninu ọrọ to wa nilẹ yii, a ti ṣe iṣẹ tiwa, bo tilẹ jẹ pe abajade iṣẹ ti a ṣe le ma dun mọ awọn kan. A ti ṣe ojuṣe wa, ko si ẹsun kan ti ijọba le fi kan wa nidii iyẹn.” Igba ti wọn beere lọwọ Baṣọrun pe ṣe loootọ ni wọn ti kọwe kan si ijọba tẹlẹ ti wọn ni Ọranlọla lawọn mu ni baba naa binu, o ni, “Irọ lawọn ti wọn n sọ bẹẹ kiri n pa, ko si Ọyọmesi kan to kọwe sijọba pe awọn ti mu Ladepo Ọranlọla.
Bi ẹnikẹni ba si kọ iru iwe bẹẹ si wọn, ki wọn mu un jade ki gbogbo aye foju ri i. Awa mọ pe irọ ni wọn n pa o, bẹẹ ni a mọ gbogbo awọn ti wọn wa nidii ọrọ yii, ṣugbọn Ọyọmesi ni wa, Ọyọ to mọ esi to ba ọrọ gbogbo mu!” Bo ti n sọrọ, bẹẹ lawọn oniluu gba a mọ ọn lẹnu, n lọrọ ba di ariwo ni aafin Baṣọrun, ṣugbọn ariwo ayọ ni.
Ọrọ ti waa di ibi ti ijọba yoo ti lo agbara rẹ bayii, abi eekinni kẹbẹ, eekeji kẹbẹ, ẹlẹẹkẹta lajẹ-n-jẹ-tan. Ẹẹmẹta ni wọn ti dibo bayii, ibi kan naa ti awọn Ọyọmesi jokoo si ni wọn jokoo si, ninu ibo mẹtẹẹta ti wọn si di yii, ẹẹmeji ni ijọba ti halẹ mọ wọn, ti wọn leri pe kugu yoo bẹ bi awọn Ọyọmesi ko ba ṣe ohun ti awọn fẹ, ṣugbọn ti awọn afọbajẹ Ọyọ naa taku pe awọn ko ni i mu Alaafin lẹẹmeji, ẹni kan ti awọn ti mu yẹn naa ni yoo jẹ Alaafin. Ọna ti ijọba waa fẹẹ gbe ọrọ naa gba ni ko ye ẹnikẹni mọ, wọn ni awọn mọ pe ijọba ko ro rere ro awọn. Ki ọrọ ma ba ẹyin yọ si wọn, awọn kan ṣa ara wọn jọ ninu awọn ọmọ ile Alowolodu ti wọn fẹẹ jẹ Alaafin yii, wọn si gba ile-ẹjọ lọ. Mọgaji Ile Baba-Kekere, Oloye Morohunranti Alabi ni wọn lo lẹjọ naa ni Ọyọ, ohun ti wọn si pe ẹjọ fun ni pe ko gbọdọ gbabọdi fawọn, pe ẹni ti gbogbo Ọyọ ba mu ni ki Mọgaji awọn duro ti.
Ko sẹni to mọ idi ti iru ẹjọ bẹẹ fi waye nigba naa, ṣugbọn o jọ pe wọn ti fura si Mọgaji Ile Baba-Kekere yii pe o n jo ijo kan lọ si ọdọ awọn Sanda Ladepo Ọranlọla Adeyẹmi, ṣe ọmọ Alowolodu kan naa ni gbogbo wọn. Awọn ti wọn pe ẹjọ naa lọjọ yii ni Siẹ Iya Oju-ooṣa, Salami Alabi Adeyẹmi, Siẹ Ejide l’Ọbagbori, Totooto Akano Adeyẹmi, Tijani Adebayọ Atanda, Jimoh Afọnja ati Ọkẹ Adeyẹmi. Awọn mejeeje ti wọn sare pe ẹjọ naa ree, Abiọdun Akerele si ni lọọya wọn, wọn ni awọn ko fẹ ki wahala kan ṣẹlẹ ninu idile awọn, iyẹn ni wọn ṣe gbe Mọgaji wọn lọ sile-ẹjọ. Ọjọ Mọnde ni wọn pe ẹjọ yii, iyẹn ọjọ kẹẹdogun, oṣu keje, ọdun 1968. Wọn ko ti i bẹrẹ ẹjọ naa ṣaa ti ijọba fi ranṣẹ pe awọn Ọyọmesi, gomina Adeyinka Adebayọ ni ki wọn wa si ọdọ oun ni ile ijọba. O ni oun fẹ ki awọn jọ fikunlukun, nitori ohun to n ṣẹlẹ naa ko ye oun naa rara.
Ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, 1968, lọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tusidee, awọn Ọyọmesi ba Adeyinka Adebayọ lalejo nile ijọba. Ṣe ni bayii, ijọba ti da gbogbo ọgbọn, ọgbọn ti pin, wọn ti halẹ mọ wọn lokeere, ihalẹ naa ko ṣiṣẹ, wọn ti leri titi, ileri wọn ko tu irun lara awọn Ọyọmesi yii, eyi to ku ni ọna ti ijọba yoo fi tan wọn, iyẹn ni gomina funra rẹ ṣe ni oun yoo ri wọn. Ni akoko naa, o loju ẹni to le ri gomina, ṣebi bo ṣe wa titi doni niyẹn. Gomina igba naa tilẹ lagbara pupọ, nitori gomina kan naa lo wa fun gbogbo ilẹ Yoruba pata, Adeyinka Adebayọ yii si ni. Bi wọn ba waa sọ pe ẹnikan n lọ sile gomina, tabi ẹnikan yoo ri gomina, tọhun ti di eeyan pataki lawujọ. Bẹẹ ni eeyan ko ni i de iwaju gomina ko ma ṣe ohun ti gomina ba fẹ ko ṣe, nitori iṣaju ina ko ni i jẹ ki ọmọde tọwọ bọ ina, ibẹru ejo ko ni i jẹ ki agbalagba paapaa tẹ ọmọ ejo mọlẹ, ẹni ba dewaju gomina yoo ṣe ohun to ba fẹ fun un.
Ohun ti Adeyinka Adebayọ paapaa ti fọkan si ree. Awọn Ọyọmesi naa ti mura wa o, nitori wọn ti halẹ mọ wọn ni Ọyọ ki wọn too kuro pe bi wọn ba de Ibadan ti wọn ko ba ṣe ohun ti wọn ni ki wọn ṣe, wọn yoo le wọn niluu ni, wọn ko ni i jẹ ki wọn pada wọ ilu Ọyọ mọ laelae. Ṣugbọn awọn eeyan naa ni nigba ti awọn ba de ọhun, ko si iku ti yoo pa awọn ti wọn ko ni i beere ọrọ lọwọ rẹ, kaluku awọn ti mura silẹ de iku to fẹẹ pa a. Igba ti wọn de ile ijọba lọhun-un loootọ, awọn kan ti mura silẹ de wọn, ki wọn si too ri gomina rara ni wọn ti ko wọn lọ sinu yara kan. Ninu ọfiisi yii ni wọn ti gbe iwe fun wọn pe ki wọn fọwọ si i, iyẹn orukọ Ọranlọla ti awọn mu gẹgẹ bii Alaafin, wọn ni ki wọn fọwọ si i, bi wọn ba ti fọwọ si i, nibi ti awọn wa yii naa ni gbogbo ọrọ yoo ti yanju, ṣugbọn bi wọn ko ba fọwọ si i, awọn ko le sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si wọn, Ọlọrun ṣe e, awọn naa kuku ri awọn ṣọja nita.
Nigba ti wọn si de ita ọfiisi gomina loootọ, awọn ṣọja kunbẹ girangiran pẹlu ibọn lọwọ wọn, ti oju wọn si le ba oyun jẹ lara obinrin, o pọn kẹnkẹn. Bẹẹ lawọn ọlopaa ni ki lo ṣubu tẹ awọn yii, awọn naa n sare lọ sare bọ, wọn mura ija silẹ paapaa, bi ẹni kan ba si ta felefele, kele yoo gbe e ni. Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, awọn Ọyọmesi ti Baṣọrun ṣe olori wọn taku, wọn ni Ọyọ kọ lawọn wa, ẹnikan ki i yan Alaafin lati ita, ilu Ọyọ ni wọn ti n yan Alaafin Ọyọ, ohun aburu ni lati wa si ilu Ibadan waa yan Alaafin, paapaa nigba to jẹ ọkan lara awọn abule Ọyọ ni Ibadan n ṣe.Wọn ni iru Alaafin ti awọn ba yan bẹẹ yoo ba ilu jẹ, igba rẹ ko le tura, nitori awọn ko ṣe ohun to yẹ ki awọn ṣe, eewọ gidi si ni lati yan Alaafin nita. Baṣọrun sọ fun wọn pe bo ba jẹ ti iku ni, awọn ko bẹru, nigba to jẹ jagunjagun lawọn lati ilẹ wa, bi iku ba de, awọn n lọ naa niyẹn, ki wọn ṣaa ba awọn gbe oku awọn pada fun awọn eeyan awọn l’Ọyọọ, ko ju bẹẹ lọ.
Nigba ti awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn n halẹ mọ awọn Ọyọmesi yii ri i pe kinni naa ko ṣee ṣe bẹẹ, wọn ni ki wọn jokoo, awọn n bọ. Nigba ti wọn pada waa ko wọn, ọdọ gomina ni wọn ko wọn lọ, ni yara nla ti wọn ti maa n ṣepade. Gomina ti jokoo, o si ti mu iwe kan to fẹẹ ka dani. Bi oun ti jokoo ni kọmiṣanna awọn ọlọpaa fun Western State, Ọgbẹni Emmanuel Olufunwa, wa lẹgbẹẹ rẹ, bẹẹ si ni kọmiṣanna to n ri si ọrọ oye ati ijọba ibilẹ, B. A. Ajayi. Akọwe agba ileeṣẹ to n ṣeto iroyin, Ọgbẹni A. A., naa duro si ẹgbẹ gomina rẹ, o si han pe Adeyinka Adebayọ ni ọrọ to fẹẹ sọ lẹnu. Ohun to wi ni pe oun ti gbọ gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni ilu Ọyọ lori ọrọ yiyan Alaafin, inu oun ko si dun si i. Ṣugbọn oun fẹẹ fi ye wọn pe ko si ohun to le ṣẹlẹ o, oun gẹgẹ bii gomina ko ni i gbe ẹni ti ilu ko ba fẹ le wọn lori gẹgẹ bii ọba. O ni nitori ẹ loun ṣe pepade awọn afọbajẹ ati awọn ọmọ oye, ki wọn yanju ọrọ wọn laarin ara wọn.

Adeyinka Adebayọ ni gbogbo ohun to n lọ pata loun ti gbọ, bẹẹ ni ojumọ kan ko ni i mọ ki awọn ti wọn fẹ daadaa fun ilẹ Yoruba ma kọwe si oun tabi ki awọn mi-in waa ri oun pe ki lo n ṣẹlẹ, ki lo de ti ọrọ ilu Ọyọ ri bayii. O ni oun naa mọ ohun to jẹ ki ọrọ naa ri bẹẹ o, ki i ṣe pe oun ko mọ ipo pataki ti ilu Ọyọ wa ninu itan Yoruba lapapọ ati ti Naijiria ni, nitori igbagbọ ni pe bi ohunkohun ba ṣẹlẹ ni Ọyọ ti ko dara, kinni naa yoo ran gbogbo ilẹ Yoruba to ku. O ni iyẹn lo ṣe jẹ gbogbo awọn ti wọn pe sibi ipade naa, awọn ọmọ oye lati ile Alowolodu ni, nitori awọn ni ọba kan, awọn ni wọn yoo jọba, bi wọn ba si ti mu ẹni ti yoo jọba kalẹ, ti awọn ni ki awọn fi ẹni bẹẹ jọba. O ni oun tun tun un sọ o, oun ko si fẹ ki awọn oniroyin tabi awọn mi-in gba ọrọ oun sodi, oun ko ṣetan lati fi tipa gbe ọba le wọn lori l’Ọyọọ o, ohun ti oun fẹẹ ṣe ni lati jẹ ki awọn ọmọ oye yanju ọrọ wọn funra wọn.
Loootọ si ni, awọn ti wọn wa nipade yii, awọn araale ni, ko si araata ninu wọn. Awọn Mọgaji ile Alowolodu ati awọn Baba-Iyaji pẹlu awọn ọmọ oye ni. Ninu awọn ọmọ oye ti wọn si wa nibẹ lọjọ yii ni Lamidi Adeyẹmi, ṣugbọn Ladepo Ọranlọla ko wa, bo tilẹ jẹ pe baba rẹ, Ọranlọla Adeyẹmi, wa nibẹ, nitori Mọgaji loun naa n ṣe. Gbogbo wọn lo wa nibẹ nigba ti Adeyinka Adebayọ n sọrọ yii, wọn si fi eti ara wọn gbọ ọ. Ọkunrin gomina naa ni ko si eyi to dun oun ju ninu ọrọ naa ju ti awọn ọmọ Ọyọ ti wọn wa nilẹ okeere ti wọn n kawe, ati awọn ti wọn n ṣiṣẹ paapaa, pe lojoojumọ ni wọn n kọwe soun, ti wọn si n sọ pe oun gẹgẹ bii gomina, ki oun yanju ọrọ naa kia, nitori awọn ko fẹ bi awọn ti n gbọ orukọ Ọyọ lokeere yii, bẹẹ ni ko ni i dara ki ohun aburu kan ṣẹlẹ nibẹ lasiko toun. O ni nitori rẹ loun ṣe fẹ ki awọn yanju ọrọ naa, ki awọn ọmọ oye ti wọn wa nibi ipade naa ba ara awọn sọrọ, ki ọrọ yanju o.

Nigba naa ni ẹnu awọn Ọyọmesi ṣi si ọrọ to wa nilẹ yii, ẹni to si kọkọ dide nibẹ ni Alapinni, Alaaji Salawu Adeleke, to dide sọrọ. O ni inu oun dun, o si daju pe inu awọn Ọyọmesi naa dun lati gbọ iru ọrọ bayii lẹnu gomina wọn, Adeyinka Adebayọ. O ni ohun ti oun ṣe wi bẹẹ ni pe awọn ti wọn n halẹ mọ awọn ti pọ ju lori ọrọ yii, wọn ko si jẹ ki awọn ṣe ohun ti awọn fẹẹ ṣe. O ni bii apẹẹrẹ, ki awọn too wa sibi ipade naa lawọn kan ti halẹ mọ awọn pe bi awọn ba lọ ti awọn sọ ero ọkan awọn, tabi ti awọn kọ lati ṣe ohun tijọba ba fẹ, awọn ko ni i pada dele, ile ijọba yii lawọn yoo ti ba lọ si ẹwọn, tabi ti wọn yoo ti fofin de awọn pe ki awọn ma wọ ilu Ọyọ mọ. O ni iru awọn ihalẹ bayii ko jẹ ki inu awọn dun, awọn ko si tilẹ mọ idi ti awọn eeyan fi n ṣe bẹẹ sawọn, nigba to jẹ iṣẹ ti ijọba ati ofin pẹlu awọn ara Ọyọ gbe le awọn lọwọ gẹgẹ bii afọbajẹ lawọn n ṣe.
Alapinni ni iṣẹ ti awọn baba awọn ti n ṣe lati ọjọ yii wa naa ni wọn ni ki awọn ṣe, ko si si inira kan tabi ohun to le nibẹ rara, bo ba jẹ awọn eeyan yoo fi awọn silẹ ki awọn ṣe iṣẹ awọn. Baba naa sọ pe ki i ṣe oni, ki i ṣe ana kuku ni awọn ti n yan Alaafin l’Ọyọọ, bi eleyii ṣe waa le kankan, ti awọn kan yoo maa halẹ mọ awọn pe bi awọn ko ba yan ẹni tijọba fẹ, iya yoo jẹ awọn ni ko ye awọn. O ni ni tawọn, awọn ko mọ ẹni ti ijọba fẹ, ẹni ti Ifa mu, ti ilu si fẹ, lawọn mọ, iru ẹni bẹẹ lawọn si maa n fi jẹ Alaafin. Salawu Adeleke ni bi awọn baba awọn ti n ṣe e niyi, iyẹn naa ni awọn si fẹẹ ṣe to di wahala. Ṣugbọn ni bayii ti Ọgagun Adeyinka Adebayọ ti fi ọkan awọn balẹ, awọn ko ro pe iṣẹ naa yoo nira mọ, awọn yoo ṣe e kia ki ọkan ijọba le balẹ, ki wọn si ri i pe awọn ki i ṣe alaṣeju, aṣa Ọyọ ati iṣe ilẹ Yoruba lawọn n tẹle ni, ohun to si le ṣe gbogbogboo lanfaani ni.
Ọrọ ti Alapinni sọ naa ni Baṣọrun gun le, nitori bi oun ti sọrọ tan ni Baṣọrun dide, o ni ọrọ toun naa ko ni i pọ, ibi ti Alapinni lọ loun naa n lọ, Alapinni ti sọrọ to wa lẹnu gbogbo Ọyọmesi, ki oun kan fi diẹ kun un ni. Baṣọrun Tijani Eesuọla Akano ni bi kinni kan ba wa ti awọn Ọyọmesi koriira, iyẹn naa ni ki wahala kan ṣẹlẹ ni ilu Ọyọ, nitori ko si bi ọrọ kan yoo ṣe ba oju ti ko ni i ba imu, bi aafaa kan ba si n leri kiri pe iyan yoo mu, ọmọ toun naa ko kuku ni i jẹ okuta, yoo kan an dandan ni. Iyẹn lawọn ko ṣe fẹ wahala l’Ọyọọ, nitori bo ba ṣẹlẹ to kan gbogbo ilu, yoo kan awọn naa gbẹyin ni. O ni o n dun awọn pe ọrọ oye yii waa ja sibi to n ja si yii, nitori ọrọ pe wọn n jẹ Alaafin l’Ọyọọ ki i mu wahala dani rara, ti eleyii nikan ni awọn ko mọ bo ṣe jẹ. Ṣugbọn gẹgẹ bi gomina ti wi yii, awọn yoo yanju ọrọ naa kia, awọn yoo si fẹnuko lori ẹni kan ṣoṣo ti yoo jẹ Alaafin.
Ṣugbọn Alapinni ati Baṣọrun ko mọ ọrọ ijọba ni, bẹẹ ni wọn ko mọ ọrọ awọn ti wọn maa n ṣe olori ijọba. Bi ọrọ kan ba wa to ba ta koko gan-an, awọn ijọba ati awọn ti wọn n ṣe olori ijọba ni ọgbọn ti wọn maa n da si i. Ọgbọn ti wọn si maa n da si i yii ni pe ọtọ ni ohun ti wọn yoo sọ fun awọn araalu, iyẹn ni pe ọtọ ni ohun ti wọn yoo sọ loju awọn oniroyin ti wọn yoo ba wọn gbe ọrọ naa jade. Niṣe ni wọn yoo maa sọrọ bii ẹni ti ko fẹ wahala, tabi pe ọrọ naa ko si lọwọ awọn, tabi pe awọn ko mọ nnkan kan nipa ọrọ naa, bẹẹ awọn gan-an ni wọn wa nidii ẹ, ohun ti wọn si fẹẹ ṣe yatọ patapata si ohun ti wọn n sọ lẹnu. Alapinni ati Baṣọrun to gbọ ọrọ Adeyinka Adebayọ ti ro pe ohun to wi yii naa lo wa lọkan rẹ, pe gbogbo ariwo ati wahala to n ṣẹlẹ, awọn oloṣelu Ọyọ lo wa nidii ẹ, ati awọn oṣiṣẹ ijọba kan to n fẹẹ fi ẹlomi-in jẹ ọba, wọn ko mọ pe ọrọ naa lọwọ Adebayọ funra rẹ ninu, afi nigba ti wọn koju ara wọn.
Bi wọn ṣe koju ara wọn ni pe Adeyinka Adebayọ pe awọn Ọyọmesi ati Baba-Iyaji si yara ọtọ, o loun yoo ba wọn ṣe ipade kan, bi awọn ba si ti ṣepade tan, oun yoo waa fun wọn labọ ipade naa, ki awọn oniroyin duro ki wọn ma ti i lọ. N lawọn oniroyin ati awọn ọmọ oye pẹlu awọn to ku nibẹ ba duro, gomina si ba awọn Ọyọmesi wọ yẹwu, oun ati ṣọja to n ṣọ ọ ti iyẹn duro gbagba pẹlu ibọn. Ṣugbọn ọrọ ti gomina sọ ninu ile yatọ si eyi to sọ nita, ohun to n sọ ni pe ki lo de ti wọn ko mu Ladepo Ọranlọla ti orukọ ẹ ti wa lọdọ ijọba, ki wọn yee fa ọrọ gun, ki wọn ma si ko awọn ara Ọyọ si hilahilo kan. O ni ki awọn naa wo gbogbo wahala to n lọ lọwọ, ogun wa niluu, awọn n ba Ojukwu fa a, ijọba apapọ ko raaye ẹjọ wẹwẹ tabi ọrọ adugbo, bi ija ba si de nibi kan, wọn le ko awọn ṣọja lọ sibẹ ki wọn ṣe wọn ṣikaṣika, oun ko si fẹ bẹẹ fun wọn l’Ọyọọ rara, nitori ijamba nla ni yoo mu dani.
Adebayọ ni ki wọn ronu wo ki awọn yanju ọrọ yii lẹẹkan. O ni bi wọn ba yanju ọrọ naa nibi ti wọn wa yẹn, apọnle ni yoo jẹ fun oun naa gẹgẹ bii gomina, ijọba apapọ ko si ni i maa ri oun gẹge bii ẹni ti ko to aṣẹ ilẹ rẹ i pa, tabi gẹgẹ bii ẹni ti ko le ṣe olori ipinlẹ rẹ. O ni bi wọn ba mu ẹni ti wọn ti mu yii, ti ọrọ naa si ṣe bẹẹ yanju, apọnle ti oun yoo gba lọwọ ijọba ko ni i kere, bẹẹ loun ko si ni i gbagbe awọn Ọyọmesi yii, nitori oun aa maa ranti wọn pe wọn ran oun lọwọ. Lẹyin ti gomina ti sọrọ lọ sọrọ bọ, o dakẹ lati reti esi lọdọ awọn Ọyọmesi, tabi Mọgaji ti yoo sọrọ. Ṣugbọn ọrọ naa ko lori nitori bi awọn Lagunna ati Asipa ti sọ pe ohun ti awọn n sọ lati ilẹ naa niyẹn pe ki wọn mu Sanda Ladepo Ọranlọla ki gbogbo ohun to n run nilẹ tan, bẹẹ ni Baṣọrun ati Alapinni pẹlu awọn to ku lọdọ tiwọn naa ni ko si ọna nibẹ yẹn, nitori awọn mọ ohun ti awọn n ṣe, awọn to fẹẹ gbabọde f’Ọyọọ ni ko mọ ohun ti wọn n ṣe.
Nibi ti ọrọ naa ti fẹẹ di ariwo ni gomina ti le wọn jade. Ko kuku pariwo mọ wọn, o ni ki wọn lọọ jokoo sita, oun n bọ, oun yoo le fun awọn ti wọn jokoo ni abọ ni. Bẹẹ ni gbogbo wọn jade, wọn si pa lọlọ nigba ti wọn tun jade, ṣe awọn ṣọja ati awọn oniroyin wa nibẹ, awọn to kan ri awọn kan ti wọn fajuro ninu awọn Ọyọmesi yii ni wọn mọ pe ipade naa ko fararọ, tabi pe kinni naa ko yọri si rere. Awọn ọga iṣẹ ijọba to ku naa wọle lati lọọ ba gomina, wọn fẹẹ mọ ohun ti yoo ṣe ati igba to n bọ waa ba awọn alejo rẹ sọrọ. Nigba naa ni wọn ba gomina naa to n kọwe hẹrẹhẹrẹ, awọn ti wọn jẹ akọwe ninu wọn si ba a wo iwe naa lẹyin to kọ ọ tan, wọn tun un ṣe, wọn si sare tẹ kinni naa laarin iṣẹju kan sikeji, nigba ti iwe si ti rẹdi, gomina jade, awọn ọga iṣẹ ijọba ti wọn si lọọ ba a ninu ile tẹlẹ sare tẹle e, wọn n tẹlẹ ko ko ko, nitori awọn ṣọja ko fẹran irin faaji, kolekole ni tiwọn.
Igba ti wọn jade sita ti Adebayọ jokoo, ti awọn to ku naa yi i ka, ti awọn ṣọja ati ọlọpaa si duro wamu, ọkunrin ologun naa mu iwe to ti kọ tẹnikan ko mọ ohun to wa ninu rẹ jade. Nigba to si ka iwe naa, ohun akọkọ to wa nibẹ ni pe “Lati akoko yii lọ, ijọba ti fagile gbogbo ọrọ oye tabi fifi Alaafin jẹ ni ilu Ọyọ, ẹnikẹni ko tun gbọdọ da kinni naa sọ mọ niluu Ọyọ tabi ni ibikibi: ofin ologun ni!” ‘Haa’ lawọn eeyan ṣe, bẹẹ lawọn mi-in kun hunrunhunrun, ṣugbọn ko sẹni ti wọn bi daa ti yoo pariwo sita, ṣe loju awọn ṣọja onibọn ti wọn tun so koboko mọdii leeyan kan yoo ti maa dun bii ekute! Bi wọn ba we bilala mọ ọn lara, tọhun yoo maa rẹrin-in akọ ni. Ṣugbọn awọn Ọyọmesi yii n ro o ninu ara wọn pe ki i ṣe ohun ti awọn sọ ni gomina yii pada waa gbe jade yii, oju to si fi ba awọn sọrọ ninu ile yatọ si oju to le koko to fi n kawe yii o. Ṣugbọn Adebayọ ko wo wọn, o n ba ọrọ rẹ lọ ni:
“Nitori rogbodiyan ogun abẹle to n lọ niluu bayii, to ti di pe gbogbo eeyan pata lo gbọdọ ba ijọba ṣiṣẹ lati ri i pe ọwọ tẹ Ojukwu, a si tẹ ọtẹ rẹ ri pata, ojuṣe mi gẹgẹ bii gomina Western State ni lati ri i pe ko si agbegbe tabi adugbo kan tabi ọrọ kan to ṣẹlẹ ti yoo yi ọkan awọn eeyan pada lati ma le ṣe ohun ti ijọba apapọ fẹ ki gbogbo wa ṣe, iyẹn lati ṣẹgun Ojukwu, ka si tẹ ọtẹ to gbe dide ri sinu okun. Ojuṣe mi ni nigba yii lati ri i pe ko si rogbodiyan kan to bẹ silẹ ni agbegbe kankan ni Western State, paapaa lori ọrọ jijẹ oye Alaafin to ṣi silẹ ni ilu Ọyọ. Ogun abẹle n lọ lọwọ nilẹ yii, gbogbo wa la mọ bẹẹ, ko si si ohun ti ẹnikẹni tabi ilu yoowu gbọdọ ṣe ti yoo tun mu ijọba apapọ ko awọn ṣọja to n jagun lati mu iṣọkan pada si ilẹ wa lọọ maa bawọn pẹtu sija nibi kan lori ọrọ ti ko to ọrọ. Emi gẹgẹ bii gomina ipinlẹ yii ko tilẹ ni i faaye gba iru nnkan bẹẹ yẹn. Ko ṣee ṣe rara.
“Niwọn igba ti mo ba si wa nipo olori ijọba Western State yii, n ko ni i bẹ ijọba apapọ pe ki wọn fun mi ni ṣọja lati fi dẹkun ija tabi awuyewuye nibi kan, nitori ẹ ni mo ṣe gbọdọ ri i pe wahala kan ko ṣẹlẹ labẹ ijọba mi. Nidii eyi, gbogbo ohun to ba jẹ mọ ọrọ yiyan Alaafin l’Ọyọọ pata, tabi ọrọ yoowu to ba kan awọn ti wọn n yan Alaafin, ki gbogbo ẹ ṣi lọ sokun igbagbe bayii o. Ko si ẹnikan to gbọdọ loun yoo maa sọrọ nipa Alaafin yiyan, ko si ipade, bẹẹ ni ko si ajọsọ kan mọ, titi ti ogun abẹle ti a wa ninu rẹ yii yoo fi pari. Ki kaluku pada si agbegbe ati ile rẹ, ki wọn si jokoo jẹẹ, ki wọn maa ọna ti wọn yoo fi fọwọsowọpọ pẹlu ijọba apapọ, ti ogun Ojukwu yii yoo fi pari. Nigba ti ogun ba pari ti ọkan gbogbo ilu si balẹ, a oo pada si ori ọrọ Alaafin Ọyọ o!”
Bẹẹ ni Ọgagun Adeyinka Adebayọ wi, o ni aṣẹ ologun naa yoo mulẹ lẹsẹkẹsẹ, ijọba oun ko fẹẹ gbọ kinni kan nipa ọrọ Alaafin.
Bata ja, ọrọ di ikalẹ; ko ṣa sẹni kan ti yoo duro kọkọ so bata to ja, yoo jokoo naa ni. Ati awọn ti wọn fẹ ti Lamidi Adeyẹmi, ati awọn ti wọn fẹ ti Ladepo Ọranlọla, onikaluku sinmi agbaja ni, nitori ijọba ti sọ pe oun ko fẹẹ gbọ kinni kan lori ọrọ naa mọ, bẹẹ ni wọn ti we kinni ọhun mọ ogun abẹle. Bi nnkan si ṣe ri lasiko ti a n wi yii, iyẹn lọdun 1968 yii, ẹni ti wọn ba sọ pe o n ṣe kinni kan to le di awọn ṣọja ti wọn n jagun abẹle lọwọ, wọn yoo mu un lọ sitimọle ninu iho-ilẹ, wọn ki i jẹ ki iru ẹni bẹẹ foju kan ita rara. Imu ọlọtẹ tabi agbẹyinbẹbọjẹ ni wọn yoo mu un, iyẹn ti wọn ko ba sọ pe o fẹẹ doju ijọba bolẹ. Iyẹn lo ṣe jẹ pe bi ọrọ ba ti da bayii, ẹni ti wọn ba kilọ fun bẹẹ yoo gbe jẹẹ ni. Ọpọlọpọ awọn oniroyin ni wọn ti wa nitimọle bẹẹ, ọpọ awọn ajijagbara bii Wọle Ṣoyinka si ti wa lẹwọn ọhun to ọjọ mẹta tẹni kan ko foju ri wọn, bẹẹ ọrọ lasan lo sọ.
Nitori bẹẹ, ko sẹni kan to fẹẹ ri ija ṣọja tabi tijọba, ko si sẹni to n fẹ ki wọn mu oun mọ ọlọtẹ to n gbeja awọn Ojukwu, bi ọrọ ba ti da bẹẹ, kaluku yoo ki ara rẹ bọlẹ ni. Eyi naa lawọn Ọyọmesi ati awọn ọmọ oye gbogbo ṣe ni ti Ọyọ yii, kaluku pada wa sile, wọn si gbe jẹẹ laaye ara wọn. Ibi ti ọrọ naa kan fi daa ni pe bi ọrọ ti ri yii, Baṣọrun Eesuọla Akano naa ni yoo maa ṣe olori ijọba ilu Ọyọ lọ, oun ni yoo duro bii Alaafin, yoo si maa paṣẹ ilu. Eyi tẹ awọn ara Ọyọ lọrun, wọn mọ pe ẹni to fẹ ti ilu naa ni yoo ṣi maa ṣejọba ilu lọ. N ni gbogbo ilu Ọyọ ba dorikodo, wọn n reti ọjọ ti ogun abẹle yoo pari. Ọrọ naa si di aṣa ti wọn n da laarin ara wọn l’Ọyọọ nibẹ, wọn aa ni, “Lọjọ wo lawọn ṣọja yoo mu Ojukwu wale o?” Owe ni wọn n fi ọrọ naa pa, wọn mọ pe lọjọ ti wọn ba mu Ojukwu wale logun pari, lọjọ naa ni wọn yoo si jẹ Alaafin fun wọn. Ṣugbọn ko sẹni to le sọ, ko si sẹni to mọgba ti ogun Ojukwu naa fẹẹ pari.

(111)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.