EYI NI ITAN BI LAMIDI ỌLAYIWỌLA ADEYẸMI ṢE DI ALAAFIN ỌYỌ (2)

Spread the love

“Ki lo de ti Gomina Adeyinka Adebayọ n ṣe bayii? Ki lo de ti ijọba Western Region ko fẹ ki Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi di Alaafin, nigba to jẹ ipo naa tọ si i? Abi ọrọ yii lagbara ju bayii lọ ni?” Ohun ti ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn ko mọ itan ilu Ọyọ, tabi ohun to ṣẹlẹ nibẹ laarin ọdun mẹwaa sẹyin n sọ niyẹn. Ṣugbọn awọn ti wọn mọ itan naa mọ pe ọrọ naa le ju bẹẹ lọ. Wọn mọ pe ki i ṣe Lamidi Adeyẹmi lawọn eeyan ijọba ibilẹ Ọyọ n ba ja, wọn mọ pe ki i ṣe awọn Ọyọmesi ni Adeyinka Adebayọ ko fẹẹ ri, wọn mọ pe ija naa ti kuro ni ija Ọyọ lasan, o ti di ija awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Action Group atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NCNC ti pupọ ninu wọn pada waa di ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, wọn mọ pe o ti di ija awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ati awọn ọmọlẹyin Akintọla. Ọrọ naa ti kuro ni ọrọ awọn ko-mẹsẹ tabi ọgbẹri, o ti di ọrọ awọn awo nikan. Ki i ṣe Lamidi Adeyẹmi ni wọn n ba ja, ọrọ baba rẹ, Alaafin Adeniran Adeyẹmi, ni wọn n tori ẹ ko wahala ba a.
Alaaji Adeniran Adeyẹmi, ọba ni, Alaafin nla si ni. Laarin ọdun 1945 si 1955, ọdun mẹwaa gbako, oun ni Alaafin nla to jẹ. Ni gbogbo igba naa, ko si araalu tabi ọmọde kan ti i wo oju Alaafin, agbara awọn ọba naa pọ. Lati ọdun 1945 to ti jọba titi di ọdun 1950, ko si wahala kan, bi ija kan ba tilẹ fẹẹ ṣẹlẹ, laarin oun ati awọn oyinbo ni. Ṣugbọn nnkan kan ṣẹlẹ lọdun 1948, nigba ti wọn fẹẹ da Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa silẹ ni ilẹ Yoruba ni. Ọbafẹmi Awolọwọ ati awọn ti wọn n ṣeto ẹgbẹ naa fi Ọọni Ifẹ, Adesọji Aderẹmi, ṣe olori ati Baba Isalẹ Agba pata, ipo ti wọn si fun un ju ti Alaafin Adeyẹmi lọ. Alaafin kọkọ fẹẹ tori eyi binu, ṣugbọn nigba ti awọn ọmọ Ọyọ meji ti wọn wa ninu ẹgbẹ naa, Bọde Thomas ati Abiọdun Akerele lọọ ba a, ti wọn si ṣe alaye pe ilọsiwaju Yoruba ni ẹgbẹ naa wa fun, Alaafin gba, o si gba lati wa ni ipo keji si Ọọni, eyi lo si ṣe jẹ lẹyin ti wọn da ẹgbẹ naa silẹ ni Ileefẹ, Ọyọ ni wọn ti ṣepade nla keji ni 1949, Alaafin si gba wọn lalejo gbaka gbiyan.
Alaapọn eeyan pata ni Bode Thomas, ọmọ eeyan nla kan niluu Eko ti wọn n pe ni Andrew Williams Thomas ni, ọkan ninu awọn ọmọ ilu Ọyọ ti awọn oyinbo ko lẹru ni, to si jẹ nigba to n pada bọ, Eko lo fi ṣe ibugbe, ṣugbọn ti ko tori rẹ gbagbe Ọyọ gẹgẹ bii ilu rẹ. Bọde Thomas mọwe, ori rẹ fẹrẹ pa, o si tete kawe, nitori ọdun 1919 ni wọn bi i, nigba ti yoo si fi di ọmọ ọdun mẹtalelogun ni 1942, o ti di lọọya, ọga lo si jẹ fun awọn bii Rotimi Williams ati Rẹmi Fani-Kayọde, bo tilẹ jẹ pe awọn mẹtẹẹta pada waa da ileeṣẹ amofin nla silẹ ni Idumagbo, l’Ekoo, ti wọn pe e ni ‘Thomas, Williams and Kayode Sollicitors’, ni Idumagbo, l’Ekoo. Opo nla to di Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa mu ni, bẹẹ oun lo kere julọ lọjọ ori ninu wọn. Ni ti Abiọdun Akerele ẹwẹ, ọrẹ Awolọwọ timọtimọ ni, awọn naa jọ da ileeṣẹ lọọya silẹ ni, ‘Awolọwọ and Akerele and Co.’ Ọmọ Ọyọ lawọn Akerele naa, wọn ko baba tiwọn naa lẹru ni. Ilu Oyinbo loun ati Awolọwọ ti dọrẹ, nitori ile ẹgbọn rẹ ni wọn ti da Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa silẹ ni London.
Ni gbogbo igba ni Bọde Thomas n lọ si ọdọ Alaafin, oun ati Arẹmọ, iyẹn akọbi Alaafin, si di ọrẹ timọtimọ. Nipa eyi, ni 1949, Alaafin fi Bọde Thomas jẹ Balogun ilu Ọyọ, ọmọ ọgbọn ọdun pere ni. Amọ nnkan yipada ni 1951, nigba ti wọn da ẹgbẹ oṣelu Action Group (AG), Ẹgbẹ Ọlọpẹ, silẹ. Idi ni pe ọpọlọpọ awọn ọba ilẹ Yoruba igba naa ti wọn n ṣe oṣelu, ẹgbẹ NCNC ni wọn n ṣe, Alaafin naa si jẹ ọkan ninu awọn alatilẹyin wọn. Eleyii kọkọ fẹẹ fa wahala laarin wọn, ṣugbọn awọn Bọde Thomas ati Abiọdun Akerele tun pada lọọ ṣalaye fun Alaafin pe awọn Ibo lo pọ ju ninu ẹgbẹ NCNC, ẹgbẹ tawọn Yoruba ree, ẹgbẹ ti yoo tun ilẹ Yoruba ṣe, ti yoo si fun awọn ọba wọn ni ọwọ ati apọnle to yẹ. Yatọ si bẹẹ, ẹgbẹ naa ni yoo gba ijọba Naijiria lọwọ awọn oyinbo nigba ti wọn ba fẹẹ lọ, iyẹn ni Alaafin ṣe gbọdọ wa lẹyin awọn. Alaafin gbọ, o gba, o si di ọkan ninu awọn alatilẹyin ẹgbẹ Ọlọpẹ.
Ọyọ ni Bọde Thomas ti waa du ipo lọ si ile-igbimọ aṣofin Western Region, o si wọle, gẹgẹ bi awọn ara ẹ to ku naa. Awolọwọ naa wọle, ati awọn bii Ladoke Akintọla ati awọn eeyan bẹẹ bẹẹ lọ. Ninu oṣu kin-in-ni, ọdun 1952, ijọba oloṣelu bẹrẹ ni Western Region, nibi ti wahala ti de niyẹn. Ki lo fa a? Ọhun to fa a ni pe BọdeThomas ti di alagbara, igbakeji olori ẹgbẹ Ọlọpẹ ni, iyẹn ni pe lẹyin Awolọwọ, oun lo kan. Ọmọ ile-igbimọ aṣofin Western Region ni, nitori ẹ ni wọn ṣe fi i ṣe minisita fun ijọba apapọ, oun ni minisita fun igbokegbodo ọkọ (Transportation), paripari rẹ si ni pe nigba ti wọn dibo ijọba ibilẹ, oun ni alaga ijọba ibilẹ Ọyọ ati agbegbe rẹ, bẹẹ ni wọn fi Abiọdun Akerele ṣe alaga ijọba ibilẹ Ọyọ Isalẹ. Agbara awọn mejeeji si bẹrẹ lati Ọyọ titi de Isẹyin, de Ṣaki ati awọn ilu Oke-Ogun, Ogbomọṣọ titi wọ itosi Ilọrin. Ipo ati agbara nla ni. Loootọ wọn fi Ọba Alaafin Adeniran Adeyẹmi ṣe Aarẹ (President) ijọba ibilẹ Ọyọ, sibẹ, ipo oludamọran lasan ni, gbogbo agbara ijọba ibilẹ yii, ọwọ Bọde Thomas lo wa.
Nibi ti ija ti de laarin awọn baba ati ọmọ yii niyẹn, ọrọ oṣelu ati pinpin agbara lo da ija wọn silẹ. Alaafin Adeyẹmi ko mọ iru ipo ti ọmọ kekere bii Bọde Thomas ati Akerele yoo wa ti wọn yoo fi maa da aṣẹ toun Alaafin ba pa kọja, tabi ti wọn yoo maa beere lọwọ oun idi toun fi ṣe ohun yoowu ti oun ba ṣe. Iru arifin wo niyẹn! Ṣugbọn ọrọ ti yatọ si bẹẹ, ofin tuntun lawọn Bọde Thomas n tẹle, ofin yii si fi Alaafin, tabi awọn ọba gbogbo si abẹ ijọba ibilẹ wọn, ẹni to si lẹlẹdẹ naa lo ni abule, Alaga ijọba ibilẹ to n paṣẹ nibẹ ni ọga ọba, iyẹn ni pe loootọ ni Alaafin jẹ baba fun Bọde Thomas, ṣugbọn oun lọga ọba naa ninu iwe ijọba, aṣẹ ti oun ba si pa ni ọba naa gbọdọ tẹle, ko gbọdọ da a akọja. Nibi yii ni ija ti bẹrẹ si i de, nitori bi Bọde Thomas ba paṣẹ kan, Alaafin Adeyẹmi ko ni i tẹle e, bi Alaafin Adeyẹmi ba si ṣe ohun kan, yoo ni ko si baba ẹni to le yẹ oun lọwọ rẹ wo, nitori oun loun niluu oun.
Ki i ṣe pe Alaafin Adeyẹmi ya alagidi tabi aletilapa, ṣugbọn o ṣoro fun un lati yipada kuro ninu ohun ti awọn baba tirẹ n ṣe to ba lọwọ wọn, paapaa nigba ti ọba naa ko kawe. Awọn ohun tawọn ọmọde oloṣelu yii n beere ati iwa wọn, arifin gbaa lo jọ loju rẹ. Nibi tawọn Ọyọmesi ti ba wọle niyi. Awọn Ọyọmesi ti inu wọn ko dun si Alaafin Adeyẹmi tẹlẹ, ti wọn ni awọn iranṣẹ rẹ maa n ri awọn fin, wọn n gba owo-ori ti ko yẹ ki wọn gba lọwọ awọn eeyan, ọba naa ki i sọ fawọn to ba fẹẹ fawọn eeyan joye, oun ni yoo gba gbogbo owo ibẹ ti yoo da a la. Awọn Ọyọmesi yii bẹrẹ si i ti Bọde Thomas pe ko ma gba fun Alaafin. Awọn kansẹlọ ti wọn yan naa, awọn ti wọn wa lati igberiko bii Okeeho, Iganna, Isẹyin ati gbogbo Oke-Ogun pata, pẹlu awọn mi-in ti wọn wa lati agbegbe Ogbomọṣọ, Igbẹti titi de Kiṣi, awọn naa ni wahala Alaafin Adeyẹmi ti pọ ju, wọn ni agbara tipatipa lawọn iranṣẹ rẹ n lo fawọn eeyan awọn.
Lati fi han Alaafin Adeyẹmi pe nnkan ti yipada si tatijọ loootọ, awọn Bọde Thomas bẹrẹ si i gbe ofin oriṣiiriṣii jade. Ofin akọkọ ni pe wọn gba eto idajọ kuro lọwọ awọn Iwẹfa, iyẹn awọn adajọ ibilẹ, wọn si ṣeto idajọ naa sabẹ ijọba, wọn fi awọn alakọwe si i. Lọna keji, wọn gba eto owo-ori kuro lọwọ Alaafin ati awọn ijoye tabi baalẹ igberiko, wọn gbe iyẹn naa si abẹ ijọba. Gbogbo eleyii ko ni nnkan meji ti wọn fi n ṣe bẹẹ ju ki wọn le di awọn ọna ti owo ati agbara n ba wọle fun Alaafin Adeyẹmi lọ. Nibi ẹjọ ibilẹ ti wọn n da ni wọn ti n ta awọn eeyan loji, ẹni ti wọn ba si faini, dandan ni ko sanwo itanran, eyi yoo mu owo wọle fọba ati awọn Iwẹfa, awọn baalẹ to ba si gba owo ori naa ni iye ti wọn n gba ninu owo ti wọn ba pa. Lati waa gba gbogbo eleyii lọwọ ọba to ni iyawo to le ni ọgọrun-un meji (200), ti awọn ero rẹpẹtẹ si wa nile rẹ, eleyii le ju ohun ti Ọba Adeyẹmi le farada lọ.
Bii ala ni ọrọ naa n ri loju Alaafin yii, o si n sọ fawọn eeyan pe koda nigba ti awọn oyinbo n ṣejọba, nnkan ko ma le koko bayii fun Alaafin, iru ijọba tiwa-n-tiwa wo waa ni eleyii o. Bi a ba tilẹ ni ki a da a silẹ ki a tun un ṣa, Bọde Thomas to n ṣejọba yii, ọmọ ọgbọn ọdun o le diẹ ni, Alaafin ti le ni ọmọ ọgọrin (80), ọdun, Bọde yii ko ju ọmọ ọmọ Adeyẹmi lọ, iru agbara buruku wo waa ni oṣelu gbe le e lọwọ yii. Awọn ofin tuntun yii dija laarin oun ati Alaafin, debii pe ninu gbọngan ipade nijọ kan, oun ati Bọde fa ọrọ mọ ara wọn lọwọ, ti Bọde sọrọ kan, ti ọba naa si ni ko gbẹnu dakẹ, abi ki lo n ṣe e ti ko mọ ohun to n sọ lẹnu. Lati igba naa ni nnkan ti daru, nitori Alaafin lọọ da ile-ẹjọ tirẹ silẹ ni aafin, bẹẹ lo da silẹ lọdọ awọn ijoye rẹ, o si da ohun gbogbo pada si bo ti wa tẹlẹ, o si paṣẹ fun awọn ijoye rẹ ki wọn maa gba owo-ori bi wọn ti n gba a lọ, ẹni ti ko ba tẹ lọrun ko waa ba oun.
Awọn araalu fẹran eto idajọ ti Alaafin, wọn si fẹran bo ti ṣe n gba owo-ori lọwọ wọn kawọn oloṣelu yii too de. Nitori bẹẹ, aafin ni wọn n ko ẹjọ wọn lọ, tabi lọdọ awọn ijoye abi baalẹ lagboole, wọn pa kootu ibilẹ tawọn ijọba ibilẹ ti, wọn ko si ya si wọn rara. Ọdọ Alaafin naa ni wọn n san owo-ori wọn si, Alaafin Adeyẹmi si n ṣeto naa bo ti n ṣe e laye awọn oyinbo tẹlẹ, o n ko eyi to ba jẹ tijọba fun wọn. Ọga meji ko le wa ninu ọkọ kan naa, awọn alakọwe ti wọn n ṣejọba yii mọ ofin oyinbo pupọ, wọn si mọ agbara ti awọn ni, nitori bẹẹ, wọn bẹrẹ si i wa gbogbo ọna lati fiya ti Alaafin Adeyẹmi ko ni i gbagbe jẹ ẹ, wọn ni ọba naa lawọn yoo fi jofin fun awọn ọba to ku nilẹ Yoruba ti wọn ba fẹẹ maa ta kan-n-gbọn kan-n-gbọn. Ṣugbọn gbogbo ara ti agbọnrin n da ni o, ko jẹ nnkan ara loju aja; nitori Alaafin Adeyẹmi ko ṣe bii ẹni pe oun ri wọn, paapaa nigba to jẹ gbogbo awọn araalu lo wa lẹyin ẹ, afi awọn Ọyọmesi ati awọn kansẹlọ oloṣelu nikan.
Ohun to kọkọ mu ija yii foju han sita ni ohun to ṣẹlẹ laarin Arẹmọ ati Bọde Thomas. Agbara Arẹmọ igba naa, bii agbara Alaafin funra rẹ ni. Agbara nla. Ṣugbọn oun naa lo da bii olori ọlọpaa baba rẹ, nitori ọpọ ibi ti baba rẹ ba lọ loun naa yoo tẹle e lọ. Gẹgẹ bi a si ti ṣe sọ tẹlẹ, ọrẹ timọtimọ loun ati Bọde Thomas. Ṣugbọn nigba ti ọrọ oṣelu ati akoso ijọba ibilẹ Ọyọ bẹrẹ si i dija yii, Arẹmọ ko fẹ bi Bọde ṣe n ṣe si baba oun rara, oun naa wa ninu ẹni to gba pe gbogbo igbesẹ ti awọn Bọde ati Akerele n gbe, lati foju Alaafin gbolẹ ni. Nitori nigba ti ọrọ owo-ori mi-in tun waye, ti ijọba tun fi owo kun owo-ori, ti wọn ni awọn yoo maa gba owo-ori fun ileewe ati awọn nnkan mi-in, ṣile mẹwaa lẹẹkan, ọrọ naa dija, Alaafin si sọ fawọn eeyan tirẹ ki wọn sọ fawọn araalu ki wọn ma sanwo-ori kankan ju eyi ti wọn n san tẹlẹ lọ. Yatọ si eyi, bi Arẹmọ ati awọn eeyan tirẹ ba ri awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn fẹẹ gba owo-ori, anajati ni wọn n na wọn, wọn yoo si le wọn danu kia.
Ọrọ yii lo kọkọ mu oun ati Bọde Thomas doju ija kọ ara wọn, nitori nigba ti awọn ẹmẹwa ati iranṣẹ Alafin ko yee na awọn ti wọn n gba owo-ori ati awọn ti wọn ba n pe ara wọn ni ọrẹ ijọba, Thomas gbe ọrọ naa koju Alaafin Adeyẹmi, o si sọrọ si i kaṣakaṣa, Arẹmọ si gba Bọde loju nitori arifin rẹ si baba rẹ. Nigba naa ni ọrọ di rudurudu. Bọde Thomas ko mu ọrọ naa ni kekere, nitori lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti mu Arẹmọ, wọn si ba a ṣe ẹjọ, ile-ẹjọ si da a lẹbi pe dandan ni ko sanwo itanran, wọn si tun da ẹwọn fun un pe ko ṣe. Wọn lo huwa to le da ilu ru ni, o si mura ija pẹlu aṣoju ijọba. Alaafin ati ọmọ rẹ gbe ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, nibẹ ni wọn si ti ni ki wọn ma sọ Arẹmọ sẹwọn. Ṣugbọn ijọba ko gba, lẹsẹkẹsẹ ni wọn pa oye Arẹmọ rẹ, wọn pa owo-oṣu to n gba tẹlẹ rẹ, wọn si le e kuro niluu, wọn ni ko gbọdọ de Ọyọ mọ laye rẹ, wọn le e sẹyin odi. Ẹyin odi yii naa lo si pada ku si.
Eleyii pọ ju ohun ti Alaafin yoo mu mọra lọ, o si tori bẹẹ kọyin si Ẹgbẹ Ọmọ Odudwa, ko lọ sipade wọn ti wọn ṣe lọdun 1952, o ni ṣebi Kofo Abayọmi to jẹ olori ẹgbẹ naa wa nibẹ nigba ti Bọde Thomas ati Akerele n ṣe gbogbo ohun ti wọn ṣe soun foun. Pabambari ni pe ọba naa ko fi bo pe oun ko ba ẹgbẹ AG, ẹgbẹ Ọlọpẹ, ṣe papọ mọ, o ni ọta ilu ni wọn, ọta oun si ni wọn. Kaka bẹẹ, o ni ẹgbẹ Alakukọ, iyẹn NCNC, loun atawọn eeyan oun yoo maa ṣe. Asiko naa ni ọkunrin tiṣa kan niluu Eko, hẹdimasita ni pẹlu, P. A. Afọlabi, dide wa si ilu Ọyọ lati Eko, ṣe ọmọ ibẹ loun naa, oun ati awọn kan si da Ẹgbẹ Ọyọ Parapọ silẹ ninu oṣu kẹjọ, ọdun 1953. Ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ NCNC ni Afọlabi, nitori bẹẹ ni ko si ṣe ya ẹnikẹni lẹnu nigba ti Ẹgbẹ Ọyọ Parapọ ni awọn ti mu ẹgbẹ NCNC gẹgẹ bii alajọṣe awọn, ati pe Alaafin Adeyẹmi ni Baba Isalẹ ẹgbẹ awọn. Alaafin naa kuku gba pe oun ti di alatilẹyin awọn NCNC.
Lẹsẹkẹsẹ ni ibinu ru bo gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ Action Group ninu, awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ naa ti wọn si wa ni Ọyọ naa n sọ pe ki awọn aṣaaju awọn tete ṣe nnkan fun Alaafin yii, ko too gbe agbara ilu Ọyọ le awọn NCNC lọwọ. Awọn Ẹgbẹ Parapọ yii paapaa ko mu nnkan rọrun rara fun awọn aṣaaju ẹgbẹ Action Group ti wọn n ṣejọba, gbogbo ọna ni wọn n wa lati fi ba wọn ja, kia ni wọn si ti sọ pe ki awọn eeyan ma san owo-ori ti ijọba ni ki wọn san. Ọrọ owo-ori yii di wahala gidi, nigba ti ẹgbẹ NCNC si ti fidi mulẹ daadaa bẹẹ, gbogbo ibi tawọn ti wọn n gb’owo-ori ba de ni wọn ti n na wọn ni inakuna, tabi ẹni to ba loun o lọ si kootu Alaafin, kootu tijọba lo fẹẹ lọ. Wọn yoo so tọhun, wọn yoo si na an, iru ẹni bẹẹ ko si jẹ ṣe bẹẹ mọ lae. Ilu ti da si meji bayii, nitori Ẹgbẹ Ọyọ Parapọ ko fi bo rara pe ẹyin Alaafin lawọn wa, ati pe NCNC lawọn ni tọkan-tara, Alaafin paapaa ko si kọ ohun ti yoo da silẹ, o ni awọn araalu wa lẹyin oun.
Nigba naa lawọn kansẹlọ patapata, ninu eyi ti Olori awọn Ọyọmesi, Baṣọrun Ladọdun wa, atawọn Ọyọmesi to ku, pẹlu alaga wọn, Bọde Thomas, pepade si kansu, ọrọ Alaafin Adeyẹmi ni wọn si sọ. Nibẹ ni wọn ti pinnu pe nibi ti ọrọ de yii, ọrọ naa ti fẹẹ kọja atunṣe o, nitori Alaafin ti di aṣaaju ẹgbẹ NCNC l’Ọyọọ, nigba to jẹ oun ni Baba Isalẹ wọn. Bẹẹ ni ọba ko gbọdọ ṣe oṣelu, nitori gbogbo awọn ọmọ ilu rẹ lo gbọdọ ri bii ọmọ oun, ni bayii ti Alaafin si ti fẹran awọn ọmọ rẹ kan, iyẹn awọn NCNC, to kọyin si awọn to ku, iyẹn awọn AG, afi ki awọn Ọyọmesi lọọ ba Alaafin, ki wọn sọ fun un pe awọn o fẹ ẹ lọba mọ o. Dajudaju, irọ ni wọn n pa pe ọba ki i ṣe oṣelu, nitori awọn ọba to ku pata ni wọn jọ n ṣe kinni naa, ṣugbọn pupọ ninu awọn ọba yii, AG ni wọn, alatilẹyin ẹgbẹ Ọlọpẹ ni gbogbo wọn. Awọn kọọkan ti ko ba ṣe ẹgbẹ naa ni wọn n ri ija ijọba; ko sohun ti Alaafin Adeyẹmi ṣe to jẹ tuntun rara.
Ṣugbọn ẹni to ba ju ni lọ, o le ju ni nu ni awọn oloṣelu Ọyọ ti wọn n ṣejọba fi ọrọ naa ṣe, nitori wọn ti fun awọn Ọyọmesi pẹlu awọn baalẹ ati ijoye igberiko ti wọn ko jẹgbadun ri ni ominira ti wọn ko ri iru rẹ ri, o si ya wọn lẹnu pe ẹni kan le duro wo oju Alaafin. Nitori bẹẹ, ẹyin ijọba lawọn yii wa, wọn n runa si kinni ọhun ki wọn le tete fiya jẹ Alaafin. Ni Ọjọbọ, Alamiisi, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1953, (29/10/53), ọrọ naa bẹyin yọ. Ọjọ naa lawọn Ọyọmesi kede faye gbọ pe awọn ko fẹ Alaafin Adeniran Adeyẹmi gẹgẹ bii ọba awọn mọ o, ko si tete maa mura lati fi ori oye silẹ ni kiamọsa. Eleyii le. Ojiji lo ba Alaafin, nitori ko mọ pe ọrọ naa yoo le debi yii rara. Ko si bi Alaafin kan ti lagbara to, awọn Ọyọmesi naa lo le yọ ọ, bi wọn ba si ti kede pe awọn ko fẹ ẹ, wọn ko fẹ ẹ mọ naa niyi, afi ko fi ori oye silẹ bi wọn ti wi. Nigba naa ni Adeyẹmi mọ pe ọran gidi ni kinni yii jare.
Ṣugbọn awọn Ẹgbẹ Ọyọ Parapọ ni ki Kabiyesi jokoo jẹẹ, wọn ni ko si kinni kan ti yoo ṣe e, ko fi ija naa silẹ fawọn, nitori ija naa ki i ṣe ija tirẹ o, ija awọn NCNC kari aye ni. Ṣe ni tootọ, awọn agbaagba ẹgbẹ NCNC l’Ekoo, awọn bii N. A Soule, awọn TOS Benson, awọn H.O. Davies, titi dori Nnamdi Azikiwe funra rẹ ati Adegoke Adelabu n’Ibadan ti ranṣẹ abẹlẹ si Alaafin pe awọn AG n halẹ mọ ọn lasan ni o, bi wọn ba gbe ọwọ kan ni igbekugbee, awọn yoo gbe ọwọ naa danu fun wọn ni. Lati fi han Alaafin pe ootọ lawọn n wi, lọjọ kẹta ti awọn Ọyọmesi ṣe ikede yii, iyẹn ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, yii kan naa (31/10/53), ni Satide, awọn Ẹgbẹ Ọyọ Parapọ yii pe ipade nla saarin ilu Ọyọ, wọn ni ki gbogbo aye waa gbọ tẹnu awọn. Ipade naa ki i ṣe kekere, o fẹrẹ ma si baalẹ igberiko ti ko si nibẹ, awọn ọba keekeekee paapaa wa, bẹẹ ni awọn ero rẹpẹtẹ lati Ṣaki, Irẹpọ Okeeho, ati awọn ilu gbogbo ni ayika Ọyọ.
Nigba ti yoo fi to bii aago mejila lọsan-an, awọn ero to ti wa ni gbọngan nla yii ti le ni ẹgbẹrun meji, koda, ero naa mu ibẹru ba awọn Ọyọmesi ati alaga ijọba ibilẹ ati awọn kansẹlọ rẹ gbogbo. Ipade naa la ibinu lọ diẹ, nitori ọrọ buruku ni gbogbo awọn ti wọn sọrọ nibẹ bẹrẹ si i sọ ranṣẹ si Bọde Thomas, wọn ni awọn koriira rẹ nitori ede-aiyede lo mu wa si ilu Ọyọ lati igba to ti bẹrẹ ijọba rẹ. Bẹẹ naa ni wọn kede pe Baṣọrun Ladọdun ki i ṣe Baṣọrun awọn, wọn ni o ti jẹ ijẹkujẹ lọdọ awọn oloṣelu lo ṣe kọyin si Alaafin. Wọn ni lọrọ kan, bi awọn Bọde Thomas, ati awọn Ọyọmesi ba jokoo si kọrọ kan ti wọn ni awọn ko fẹ Alaafin Adeyẹmi loye mọ, awọn wa si gbangba ni tawọn lati sọ fun gbogbo aye pe awọn kọ lawọn ran wọn niṣẹ bẹẹ, wọn ko sọ ọrọ naa gẹgẹ bii aṣoju awọn, wọn sọ ọrọ naa si apo ara wọn ni o, Adeyẹmi yii lawọn fẹ nipo Alaafin ni tawọn.
Ere ni Alaafin kọkọ pe ọrọ yii, ṣugbọn nigba ti ọrọ di ti awọn Ọyọmesi yii, baba naa ri i pe nnkan ti kuro nibi ti oun gbe e si. Ati pe lati fihan pe awọn alagbara lo wa nidii ọrọ naa, awọn kinni kan ṣẹlẹ laarin ọjọ mẹta sira wọn. Ṣe awọn Bọde Thomas ti gbe awọn ọmọ Ẹgbẹ Ọyọ Parapọ kan lọ sile-ẹjọ, wọn fẹẹ ju wọn sẹwọn pe wọn n di ijọba lọwọ lati gba owo-ori lọwọ awọn eeyan, ṣugbọn lọjọ Aje, Mọnde, to tẹle ọjọ tawọn Ọyọmesi lawọn ko fẹ Adeyẹmi mọ, iyẹn ọjọ keji, oṣu kọkanla, 1953, (2/11/53), Adajọ Adetokunbọ Ademọla dajọ ni ile-ẹjọ to ga julọ n’Ibadan pe ile-ẹjọ ijọba ibilẹ Ọyọ ni ko gbọdọ dajọ kankan lori awọn eeyan ti wọn mu yii ti ko ba nidii kan pato lọtọ, ki wọn yaa kọkọ fi wọn silẹ na titi ti iwadii lori ọrọ gbogbo yoo fi yanju ni. Ọrọ naa ye awọn aṣaaju ẹgbẹ Action Group, wọn mọ pe awọn NCNC ti rin si ọrọ naa, nitori o di dandan ki wọn tu awọn ọmọ Ẹgbẹ Ọyọ Parapọ ti wọn ti mu silẹ.
Ni Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu kọkanla, yẹn naa, (3/11/53), iyẹn ọjọ keji ti wọn dajọ yii, awọn ọba nla nla ilẹ Yoruba kan ṣepade n’Ibadan pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ AG, Ọbafẹmi Awolọwọ wa laarin wọn. Awọn ti wọn ṣepade nile ijọba n’Ibadan lọjọ naa ni Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adesọji Aderẹmi, Alake Abẹokuta, Ọba Adedapọ Ademọla, Awujalẹ ti Ijẹbu-Ode, Ọba Adesanya Gbelegbuwa, Ọdẹmọ Iṣara, Ọba Samuel Akinsanya ati Ọba Adele ti ilu Eko. Bi wọn ṣe ba awọn aṣaaju ẹgbẹ AG sọrọ naa ni wọn ba awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin sọrọ, wọn n wa ọna ti wọn fi le yanju ọrọ naa. Ọjọ naa gan-an lawọn ẹgbẹ Musulumi lapapọ, Muslim Congress of Nigeria, ti wọn wa ni Western Region kọwe pajawiri si igbakeji Gomina, wọn ni ko ma da awọn Ọyọmesi ati ijọba ibilẹ Ọyọ lohun o, ko ri i pe oun daabo bo Alaafin Adeyemi, ki kinni kan ma ṣe ọba naa, nitori eeyan daadaa ni, awọn oloṣelu lo fẹẹ ṣe akoba fun un.
Igbakeji Gomina Naijiria to n ṣe akoso gbogbo Western Region ti wọn ranṣẹ si yii, Sir Hugo Marshall, naa ranṣẹ pe Alaafin pe ko wa n’Ibadan, o si ba a ṣepade. Lọjọ Tusidee yii kan naa ni. Koko ohun to ba a sọ ko han si gbogbo eeyan, awọn ti wọn sun mọ ọn nikan ni wọn mọ pe ohun to sọ ni pe ki Alaafin Adeyẹmi tete mọ bi yoo ti gbọrọ si awọn Ọyọmesi ati ijọba ibilẹ rẹ lẹnu, pe awọn ko fẹ wahala nibẹ, bẹẹ ni ko si gbọdọ fi ara rẹ han bii ẹni to n ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu kankan. O ni bo ba ṣee ṣe fun un ko jinna si awọn Parapọ, ko jẹ kawọn araalu mọ pe oun kọ loun n ṣe atilẹyin fun wọn, oun ko si ran wọn ni awọn iṣẹ ti wọn n jẹ. Alaafin pada si Ọyọ, o si ronu ohun ti yoo ṣe, nitori bo tilẹ jẹ pe ọba naa laya bii kinnihun, ko mọ pe ọrọ naa yoo de gbogbo ibi to n de yii, abi ọrọ abẹle ilu Ọyọ ṣe waa di ohun ti yoo fa wahala rẹpẹtẹ bẹẹ. Nigba naa, ọrọ naa ko ṣee gba mu mọ, o ti di ina to n jo lalaala, Alaafin ronu ọrọ yii titi ni gbogbo Ọjọruu, iyẹn Wesidee, ọjọ kẹrin, oṣu kọkanla yii, nigba to si di Ọjọbọ, Alamiisi, ọjọ karun-un, oṣu naa, (5/11/53), Alaafin Adeyẹmi sọrẹnda. Boya nitori ọrọ to sọ pẹlu igbakeji gomina ni Ibadan ni o, tabi nitori amọran mi-in tawọn ti wọn sun mọ ọn fun un, ko sẹni to mọ, ohun ti gbogbo eeyan ṣa ri ni pe Alaafin sọrẹnda fawọn Bọde Thomas atawọn Ọyọmesi. Bawo lo ṣe ṣe e? Alaafin sọrọ sinu kasẹẹti ni, ti wọn si n tẹ ẹ jade seti awọn eeyan ilu. Bẹẹ lo sọ fawọn ijoye rẹ ti wọn sun mọ ọn pe ki awọn naa maa gbe ọrọ naa kiri agboole pe ohun toun Alaafin Adeniran Adeyẹmi sọ niyi. O ni ki awọn oniroyin waa gbọ ọrọ naa, ki wọn le gbe e jade fun gbogbo aye ri. O kọ ọ siwee jade fun alaga ijọba ibilẹ rẹ ati awọn kansẹlọ, o ni iwe adehun oun niyi, gbogbo ọrọ to wa nibẹ, oun loun sọ ọ, ki wọn jẹ ki awọn gbagbe ọtẹ ati ija, ki awọn maa ba iṣẹ idagbasoke ilu lọ.
Koko mọkanla pataki lo wa ninu iwe ti Alaafin Adeyẹmi kọ jade, ati ohun to ni ki awọn ijoye oun maa gbe kiri: akọkọ ni pe oun Alaafin kabaamọ gbogbo rogbodiyan to ti n ṣẹlẹ niluu Ọyọ lati ọjọ yii wa o, oun si fẹ ki awọn Ọyọmesi ati awọn alaga ijọba ibilẹ atawọn kansẹlọ to ku yẹ awọn igbesẹ alaafia yii wo, ki wọn gba a wọle, ki awọn le bẹrẹ igbe-aye tuntun. Alaafin sọ bayii pe, “Eyi ni adehun ti emi Alaafin Adeniran Adeyẹmi ba awọn ijọba ati Ọyọmesi pẹlu gbogbo ilu Ọyọ ṣe, pe:
(1) Emi Alaafin jẹjẹẹ bayii pe gbogbo ohun ti mo ba fẹẹ ṣe ni n oo maa fi to awọn ijoye mi leti; (2) Mo tun ṣeleri bayii pe gbogbo amọran ti awọn ijoye mi ba fun mi ni n oo maa tẹlẹ o; (3) Mo jẹjẹẹ pe mi o ni i da kinni kan ṣe mọ lati asiko yii lọ; (4) Mo jẹjẹẹ pe n ko ni i sọrọ rara lori pe ki wọn tun da Arẹmọ tabi oye arẹmọ pada siluu Ọyọ; (5) Mo jẹjẹẹ pe n ko ni i lodi si i pe ki wọn ṣe eto idibo nigba yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe e; (6) Mo jẹjẹẹ pe emi funra mi yoo ba ijọba ṣepolongo lori owo-ori tuntun ti wọn fẹẹ maa gba; (7) Mo jẹjẹẹ pe n ko ni i maa sọrọ buruku si awọn ijoye mi mọ lati akoko yii lọ, tabi ki n maa bu wọn, n ko si ni i jẹ ki ọkankan ninu awọn iranṣẹ mi ṣe bẹẹ; (8) Mo jẹjẹẹ lati maa ki awọn ijoye mi bo ṣe yẹ ki n ki wọn nigbakigba ti a ba pade; (9) Mo jẹjẹẹ bayii lati ma ṣe gbe sẹyin ẹni kan ninu ija awọn oloṣelu, tabi ki n ṣe atilẹyin fẹni kan ninu wọn; (10) Mo jẹjẹẹ lati maa fi ẹni yoowu ti awọn ijoye mi ati afọbajẹ ba mu wa joye; (11) Mo jẹjẹẹ lati le awọn iranṣẹ mi tawọn ijoye mi ba fẹ ki n le lọ danu lẹsẹkẹsẹ, ki n si gba awọn ti wọn ba fẹ ki n gba saafin, bẹẹ ni n oo si maa fun wọn laaye lati waa yẹ aafin wo nigbakigba ti wọn ba fẹ, ki eleyii le da wọn loju.”
Eyi ni ikede ti Alaafin ṣe, gbogbo awọn ara Ọyọ si n pe jọ kaakiri lati gbọ ọrọ to n tẹnu ọba wọn, Alaafin Adeniran Adeyẹmi, jade. Ni tododo, aya gbogbo eeyan lo ko soke nigba ti wọn n gbọ ohun Alaafin. Awọn ti wọn fẹran aṣa ti wọn si mọ bi agbara Alaafin atijọ ti to n bi ara wọn leere pe “Ki lo n ṣẹlẹ, ki lawọn oloṣelu yii mu wa yii, Alaafin ti waa di ẹni to n bẹ awọn Ọyọmesi ati awọn ọmọ keekeekee, eleyii ma ga o.” Nigba ti ọrọ naa si jade si gbangba patapata ni ọjọ Jimọ, ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, (6/11/53), ọrọ naa di ohun tawọn araalu tori ẹ pa gbogbo iṣẹ ti wọn n ṣe ti, ti wọn si n pejọ ni meji-meji tabi mẹta-mẹta, tabi ju bẹẹ lọ, kaakiri lati sọ ọrọ naa, wọn ni awọn fẹẹ wo ohun ti yoo pada ṣẹlẹ, nigba ti Alaafin si ti ṣe ohun ti wọn fẹ ko ṣe wayi. Ohun ti wọn ṣe n sọ bẹẹ ni pe wọn ko ti i mọ boya awọn alaga ijọba ibilẹ atawọn Ọyọmesi yoo gba ẹbẹ Adeyẹmi, wọn yoo ṣi jẹ ko maa ṣe Alaafin rẹ lọ.
Ati pe ni ọjọ naa gan-an ni awọn Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa ati awọn aṣoju ile-igbimọ lọbalọba Western Region n bọ ni ilu Ọyọ, wọn fẹẹ waa ba Alaga ijọba ibilẹ, Bọde Thomas, atawọn kansẹlọ rẹ ṣepade, ki wọn ri awọn Ọyọmesi ati Alaafin, ki wọn si pari ija naa fun wọn. Wọn ti fun ara wọn ni gbedeke, wọn ni wọn yoo wa ni ilu Ọyọ lati ọjọ Ẹti, iyẹn Jimọ, ọjọ kẹfa, titi di Satide, ọjọ keje, oṣu kọkanla, ọdun 1953 (7/11/53), wọn ni o si da awọn loju pe lọjọ naa ni ija naa yoo pari. Wọn ti ranṣẹ si Alaafin ati gbogbo awọn ti ọrọ yii kan pe awọn n bọ, awọn yoo lo ọjọ meji l’Ọyọọ, nitori ọrọ to ba kan Ọyọ ati Alaafin, gbogbo ilẹ Yoruba lo kan, awọn si gbọdọ yanju kinni ọhun ko ma di nla ni. Nidii eyi, gbogbo Ọyọ lo ti gbọ pe awọn Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa n bọ, wọn yoo waa kilọ fun Bọde Thomas ati awọn Ọyọmesi pe ki wọn fi Alaafin awọn silẹ, ki wọn jẹ ki ọba jaye ori rẹ, ki wọn yee fooro ẹmi ẹni ti ko ṣe nnkan kan fun wọn. Ṣugbọn awọn alaga ijọba ibilẹ ati awọn oloṣelu Action Group ni nnkan mi-in lọkan ni tiwọn naa. Ṣe awọn Ẹgbẹ Parapọ ati NCNC ti ko ero rẹpẹtẹ wọ ilu Ọyọ ni Satide, anfaani ree fawọn lati ko awọn ero tawọn naa wọlu ni Jimọ, ka waa mọ ẹni to ni ero to pọ ju ninu awọn. N lero rẹpẹtẹ ba ya wọ ilu Ọyọ, ṣugbọn awọn ti ọrọ kan bẹẹ, gbọngan nla Atiba ni wọn ni ki wọn maa wọ lọ, nitori ibẹ ni ipade naa yoo ti waye. Awọn kansẹlọ gbogbo pata ti wọn wa ni ijọba ibilẹ Ọyọ ati agbegbe rẹ, awọn Ọyọmesi pata, ati awọn aṣaaju ẹgbẹ AG ni agbegbe naa, ati awọn oloye kọọkan laarin ilu, wọn ni Atiba ni ki wọn maa niṣo, nibẹ ni wọn yoo ti yanju ọrọ Alaafin. Ki awọn ọmọ ẹgbẹ Oduduwa yii too de, gbọngan naa ti kun akunfaya, sugbọn ko sẹni to fa wahala tabi mura ija wa, kaluku jokoo wọọrọ, wọn n takurọsọ laarin ara wọn, wọn n reti ohun ti yoo ṣẹlẹ gan-an.
Ni taara ti awọn aṣaaju ẹgbẹ ọmọ Oduduwa ati awọn aṣoju igbimọ lọbalọba yii n bọ, ọdọ Alaafin ni wọn gba lọ. Awọn ti wọn wa nijọ naa ni: Baba Eko, Dokita Akinọla Maja to tun jẹ aarẹ Ẹgbẹ ọmọ Oduduwa; Ọba Samuel Akinsanya, Odẹmọ Iṣara; Ataọja ilu Oṣogbo, Ọba Samuel Adelẹyẹ Adenle; Balogun ilu Ibadan, Oloye Isaac Babalọla Akinyẹle; Balogun Ijẹbu-Ode, Oloye Fasasi Adesoye; Alaaji Sule Oyeṣọla Gbadamọsi, Akapo ẹgbẹ AG; Timothy Ọlajide Oyeṣina, Oluldasilẹ ileewe Ibadan Boys High School ati Salami Akintayọ (S. A.), Akinfẹnwa ti i ṣe igbakeji aarẹ Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa. Gbogbo wọn yii lo wọ ilu Ọyọ wa lọjọ Jimọ naa, wọn si kọkọ lọ sọdọ Alaafin nigba to jẹ bi a ba dele kan, olori ibẹ la a kọkọ ki. Wọn ba Alaafin sọrọ, wọn jẹ ko mọ ohun ti awọn waa ṣe, oun naa si ṣalaye fun wọn pe oun ti ṣetan lati gba gbogbo ohun ti wọn ba wi, nitori oun ti n ṣe awọn ohun ti wọn ni ki oun ṣe.
Lẹyin eyi ni wọn lọọ ba Bọde Thomas, wọn si ba oun naa ṣe ipade idakọnkọ, lẹyin naa ni wọn kọja si Atiba Hall, nibi tawọn ero rẹpẹtẹ ti n duro de wọn. Nigba ti wọn jokoo tan, Alaafin paapaa yọ ninu aafin rẹ, o si lọ sori aga rẹ ti wọn ti gbe sinu gbọngan ipade yii, gbogbo wọn si ke Kaabiyesi fun un. Alaafin lo ṣi ipade naa, o si tun ṣalaye awọn ohun to ti sọ fawọn aṣoju Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa atawọn lọbalọba yii ni kọrọ ni gbangba. O ni gbogbo ohun ti ipade naa ba fẹ koun ṣe loun yoo ṣe, to ba ti jẹ ki alaafia le pada si ilu Ọyọ ni. Akinọla Maja naa sọrọ, o ni idi ti awọn fi wa ni lati dẹkun ede-aiyede ati awuyewuye to n lọ l’Ọyọọ, nitori kinni naa n ja awọn laya, awọn ko si fẹ ohun ti yoo di wahala rara. O sọ fun wọn pe nibi ipade yii naa ni ki wọn ti ṣalaye ojuṣe Alaafin fun un, ki wọn ṣe tawọn Ọyọmesi ati ti alaga ijọba ibilẹ atawọn kansẹlọ rẹ naa, ko le ye kaluku, nitori ohun to n faja gan-an niyẹn.
Baṣọrun ti i ṣe olori awọn Ọyọmesi lo ki awọn alejo naa kaabọ lorukọ gbogbo ile, o ni awọn ki wọn pe wọn ṣeun, ati pe gbogbo ọrọ ti wọn sọ lawọn yoo yẹwo, awọn yoo si jiroro lori wọn ni ipade tawọn fẹẹ ṣe yii, nigba to kuku jẹ gbogbo awọn aṣoju lati abule ati ilu to le ni aadọta ni agbegbe Ọyọ ni wọn wa nibẹ, to jẹ gbogbo kansẹlọ lo peju, ọrọ ti awọn ba sọ nipade naa ko tun ni awawi ninu mọ, gbogbo ilu Ọyọ ati agbegbe rẹ pata lo sọ ọ, o si daju pe eyi to dara lawọn yoo ṣe. Ọrọ to sọ naa fi ọkan awọn onlaja wọnyi balẹ, o si mu inu Alaafin Adeyẹmi naa dun diẹ, ẹrin musẹ si pa ẹrẹkẹ rẹ, lẹyin naa lo si gbera, aafin ya. Bo ti n pada saafin lawọn alejo naa tẹle e, wọn si sin in de ẹnu ọna aafin lọhun-un ki wọn too pada, ipade naa si ti bẹrẹ pẹrẹwu. Awọn eeyan ti n sọ ero wọn, bẹẹ lawọn mi-in n sọ ohun ti wọn mọ nipa Alaafin, wọn ni gbogbo eyi to n ṣe yii, ọgbọn lo n da o.
Fun odidi wakati kan ni ipade naa fi n lọ, nigbẹyin, ohun ti gbogbo wọn fẹnuko si, lai si ẹni kan bayii to tako o, ni pe ki awọn ma gba ẹjẹ ati aba ti Alaafin da. Wọn ni awọn ko gba, afi ki Adeniran Adeyẹmi kuro nipo Alaafin. Awọn aṣoju yii kilọ fun awọn Ọyọmesi ati awọn kansẹlọ yii ṣaa o, wọn ni awọn n lọọ jiṣẹ fawọn to ran awọn, ṣugbọn awọn ko gbọdọ gbọ pe wọn fa wahala kan titi ti awọn yoo fi pada wa. Nigba ti ọrọ naa de etiigbọ Alaafin, kinni ọhun ba a ninu jẹ, nitori ọba naa ko tun mọ eyi to ku ti yoo ṣe. O ran ọmọ rẹ, Ọmọbabinrin Ake ati ọkan ninu awọn olori rẹ lati lọọ ba oun ki awọn ọmọ Ẹgbẹ Oduduwa to wa naa, awọn paapaa si lọọ ri i lọjọ keji ki wọn too maa lọ. Wọn ni ko ṣe suuru, ko ma ṣe ohunkohun ti yoo mu ija naa le si i o. Wọn ni ko kilọ fun awọn Parapọ ti wọn lawọn n ti i lẹyin, ko si jinna si wọn, nitori awọn Parapọ yii gan-an ni wọn ko wahala to pọ to bayii ba a, bẹẹ ni wọn ko si le gba a ti ọrọ naa ba le ju bayii lọ. Bẹẹ lawọn to waa pari ija naa wi, wọn si pada lọ.
Nitori lati le fi ohun gbogbo si eto ko too di aarin ọsẹ ti yoo tun pada wa, Bọde Thomas, alaga Ijọba ibilẹ Ọyọ yii, ko le kuro ni ilu naa lọjọ Satide ti awọn alejo rẹ lọ. Oun duro di ọjọ Sannde, iyẹn ọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla, yẹn naa (8/11/53). Ohun to sọ fawọn kansẹlọ ati awọn Ọyọmesi pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ Ọlọpẹ nibẹ ni pe oun yoo pada de titi ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, tabi o pẹ tan, Ọjọruu ti i ṣe Wẹsidee. Iyẹn ni pe bi oun ko ba de ni ọjọ kẹwaa, oṣu naa, (10/11/53), oun yoo de ni ọjọ kọkanla (11/11/53), bi oun ba si ti de lawọn yoo waa yanju ọrọ Alaafin.
Ṣugbọn ọjọ ti awọn Ọyọmesi ati awọn ara Ọyọ ri Bọde Thomas mọ ree o, nitori lojiji ni wọn gbọ l’ogunjọ, oṣu kọkanla, (20/11/53) yii, pe Bọde Thomas ti ku o. Haa ni gbogbo eeyan n ṣe, awọn Ọyọmesi, awọn kansẹlọ Ọyọ ati awọn eeyan ko si ro o lẹẹmeji, wọn ni Alaafin lo pa a. Awọn ọmọ Action Group ati awọn aṣaaju wọn binu kọja suuru, ọrọ naa pa wọn nigbe, o si jo wọn lara, ariwo ti wọn si n pa ni pe, “Alaafin ti pa Bọde o!” Wọn ni asasi lo fi pa a, wọn ni o fun un lobi jẹ ni, wọn ni ọkunrin naa gbo bii aja to fi ku ni, pe ko si tabi-ṣugbọn nibẹ, oogun buruku ni Alaafin fi pa Bọde.
Gbogbo awọn ọmọ Action Group, awọn ọmọ Ẹgbẹ Ọlọpẹ, ti ọrọ naa ka lara to bayii nijọ naa, awọn naa ni wọn pọ ninu ijọba Ọgagun Adeyinka Adebayọ ni Western State ni 1968, ọga wọn agba, Ọbafẹmi Awolọwọ si ni igbakeji olori ijọba ologun Naijiria, agbara nla lo wa lọwọ wọn. Nibi yii ni wahala ti ba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi to fẹẹ jẹ Alaafin, wọn ni ọmọ ẹni to pa Bọde Thomas niyẹn, ko le ṣee ṣe. Ṣugbọn, ṣe Alaafin Adeniran Adeyẹmi lo pa Bọde Thomas loootọ ni?
Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

(163)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.