EYI NI ITAN BI LAMIDI ỌLAYIWỌLA ADEYẸMI ṢE DI ALAAFIN ỌYỌ

Spread the love

Ọjọ Sannde kan bayii ni. Ọjọ karun-un, Oṣu kẹta, Ọdun 1968. Yoo ti maa to bii ọwọ aago kan lọsan-an, ọsan ọhun pọn ganringanrin, oorun nla fẹju mọ tewe tagba, ọlọmọ kilọ fọmọ rẹ pe ko yee sare kiri ninu oorun yii, awọn agbaagba si kilọ falaboyun ko ma rin regberegbe kiri nitori awọn anjannu ti i fọsan gangan ṣiṣẹ tiwọn. N ni kalukku ba sa sinu ile, awọn oṣiṣẹ ijọba si dakẹ mọnu ọfiisi, awọn ti ko si ni ọfiisi wa abẹ ooji fori pamọ si, wọn n reti igba ti yoo di ọwọ irọlẹ, ti oorun naa yoo sinmi agbaja. Asiko igba naa lawọn ti wọn ni redio lẹgbẹẹ gbọ iroyin, redio gbe e jade pe awọn afọbajẹ ilu Ọyọ ti mu Lamidi Ọlayiwọla gẹgẹ bii Alaafin tuntun.
Awọn eeyan ti n reti ikede yii tipẹ, lati igba ti Alaafin ana ti waja ni. Ọjọ Ẹti, Jimọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 1968 yẹn naa l’Ọba Gbadegẹṣin Ladigbolu Keji ti tẹri-gbaṣọ ni Ọsibitu UCH, n’Ibadan, lẹyin to ti wa lọsibitu naa fun bii oṣu kan, nitori ọjọ kẹfa, oṣu kin-in-ni, ni wọn ti gbe e debẹ. Alẹ ọjọ to ku naa gan-an ni wọn sin oku rẹ sẹgbẹẹ baba rẹ, Alaafin Ladigbolu Akọkọ, lẹyin ti wọn ti ṣe gbogbo ọrọ to yẹ ki wọn ṣe. Iku Ọba Ladigbolu Keji ka awọn eeyan lara nitori ko dagba, ọmọ ọdun mejidinlaaadọrin (68) ni, bẹẹ ni ko si pẹ lori oye naa ki iku too de, nitori ọdun 1956 lo depo naa, iyẹn ni pe ko lo ọdun mẹwaa nipo ọba. Lati igba to ti ku ni Baṣọrun Ọyọ igba naa, Tijani Eesuọla Akano, ti n ṣakoso ilu, ti gbogbo eeyan si n reti ọjọ ti wọn yoo kede Alaafin tuntun, ko too waa di pe wọn kede Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi.
Ko ya wọn lẹnu pe Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ni wọn mu. Baba rẹ ti jọba. Baba rẹ ni Alaaji Adeniran Adeyẹmi to ti wa nipo Alaafin lati ọdun 1945, to si wa lori ipo naa titi di 1955, o si ku diẹ ko dori oye naa lo bi Ọlayiwọla lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹwaa, ọdun 1938. Bẹẹ ni baba tirẹ naa paapaa, ọba ni. Adeyẹmi kin-in-ni, iyẹn Alaafin Adeyẹmi Alowo-lodu-bii-iyere ti jọba ni 1876 titi di ọdun 1905, ọkan ninu awọn to pẹ lori oye ni, ọgbọn ọdun lo lo nipo ọba. Nitori bẹẹ, awọn eeyan ti ro pe ko sẹni kan ti yoo binu pe Lamidi ọmọ Adeyẹmi fẹẹ jọba, nigba ti ki i ṣe pe tirẹ lakọkọ. Ṣugbọn ọrọ naa ko ri bẹẹ rara, nitori bi wọn ti kede orukọ Lamidi Ọlayiwọla pe oun ni yoo jọba yii, bẹẹ ni wahala de gidi.
Ohun to ṣẹlẹ ni pe bo ba jẹ bi wọn ti gbe eto kalẹ ni, ko too di oṣu kan lẹyin ti Alaafin waja yii ni wọn yoo ti kede orukọ Alaafin mi-in, akọwe ijọba ibilẹ Ọyọ igba naa, F. A. Taiwo, tiẹ ti kọwe si awọn Afọbajẹ yii pe ko too di ogunjọ, oṣu keji, ki wọn ti fi orukọ Alaafin tuntun ranṣẹ si oun, bẹẹ lo si la a mọlẹ pe idile Alowolodu nikan ni ipo naa tọ si, nibẹ ni Alaafin tuntun yoo ti jade. Ṣugbọn awọn afọbajẹ ko kede orukọ ẹnikan, nitori awuyewuye to n lọ labẹlẹ ko kere rara. Loootọ, nigba ti yoo fi di ọjọ kẹrinla, oṣu keji yii, awọn mẹfa ni wọn ti ya orukọ wọn sọtọ pe ninu wọn lẹni kan yoo ti jade, ṣugbọn wọn ko ti i mọ ẹni ti wọn yoo mu ninu Ashiru Mafọlayọmi Adeyẹmi to n ṣe kọntirakitọ l’Ọyọọ nibẹ, Sanda Ọladepo Adeyẹmi, sajẹnti ọlọpaa ibilẹ nileeṣẹ ijọba ibilẹ Ọyọ nibẹ, Agbọnyin Tẹlla Adeyẹmi ati Salawu Durodọla Adeyẹmi, oniṣowo lawọn mejeeji. Gbogbo awọn mẹrin yii, idile kan naa ni wọn ti jade ninu ẹbi Adeyẹmi.
Ṣugbọn awọn meji mi-in tun jade lati idile mi-in ninu ẹbi yii kan naa, Adebayọ Tẹla Adeyẹmi lati Epo Gingin, ati Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, ẹni ti orukọ rẹ de gbẹyin. Nibi ti wahala ti bẹrẹ gan-an niyẹn.
Loootọ Lamidi Ọlayiwọla kawe ju gbogbo awọn to ku yii lọ, nitori iwe mẹwaa rẹ duro san-un san-un, iṣẹ adiyelofo (Insurance) lo si n ṣe l’Ekoo, eyi si jẹ ko laju ju gbogbo awọn to ku ti wọn jọ n du kinni naa lọ. Ṣugbọn ọkunrin ọlọpaa ibilẹ toun naa n du ipo yii, Ọyọ lo wa, ijọba ibilẹ Ọyọ ti yoo faṣẹ si ẹni ti yoo di Alaafin lo si ti n ṣiṣẹ, sajẹnti ọlọpaa ibilẹ ni, o si gbajumọ laarin awọn oṣiṣẹ ati ọga gbogbo ni ijọba ibilẹ Ọyọ. Lọrọ kan, awọn eeyan rẹ ninu ijọba ibilẹ naa ti pinnu pe oun ni yoo di Alaafin, ko sọgbọn ti ẹnikan le da si i. Koda, ni ọjọ kẹsan-an, oṣu keji, awọn idile meji ninu awọn mẹrin ti akọkọ yii ti kọwe ti wọn ni gbogbo awọn fọwọ si i pe ẹni kan pere lawọn yoo fa kalẹ lati idile mẹrẹẹrin, ko si si ẹyẹ meji ti i jẹ aṣa, Sanda Ọladepo Adeyẹmi, ọlọpaa ijọba ni.
Ọrọ Ọladepo yii tilẹ ni bo ṣe jẹ, nitori baba rẹ, Ọranlọla Adeyẹmi, ti wọn n pe ni Baba Iwo lawọn Ọyọmesi kọkọ pe pe ko waa jẹ Alaafin lẹyin iku Gbadegẹṣin. Ṣugbọn Baba Iwo ko fẹẹ jẹ ẹ, o si pe ipade awọn ẹbi Alowolodu gbogbo, o ni oun ko jẹ Alaafin, ọmọ oun loun fẹẹ fa kalẹ, iyẹn Sanda Ọladepo Ọranlọla Adeyẹmi. Gbogbo awọn to ku ni wọn gba, wọn ni ko sohun to buru nibẹ, nigba to jẹ oun lo tọ si, bi ko ba si fẹẹ jẹ ẹ to jẹ ọmọ rẹ lo fẹ, ko si wahala kan nibẹ, ki Sanda waa jẹ Alaafin. Ṣugbọn ẹni kan tun wa nibẹ to n jẹ Baba Salami Dudu, iyẹn taku, o ni ko ṣẹlẹ ri, ko si Alaafin kan ti i jẹ ti baba rẹ i wa laye, nigba naa loun darukọ Ọmọọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, ọmọ Alaafin ijẹta, o ni ki wọn pe e ko waa jọba. Ohun to fa awuyewuye ree, ti ija ọrọ oye naa si fi di taarin awọn meji yii, tawọn kan n sọ pe ọmọ Ọranlọla Adeyẹmi lawọn n ba lọ, tawọn mi-in si n sọ pe Lamidi Adeyẹmi ni, ti ọrọ naa si gbona bii ajere.
Nigba ti yoo fi di ọjọ kẹtadinlogun, loṣu keji yii, awọn to ku ti wọn jọ fẹẹ du ipo naa ti sọwọ-silẹ, awọn meji pere to si ku naa ni Sanda Ọladepo ati Lamidi Ọlayiwọla. O waa ku ki awọn Afọbajẹ mu ẹni kan ninu awọn mejeeji yii, ki wọn si kede orukọ rẹ faye gbọ. Ṣugbọn ko ṣee ṣe. Ohun to fa a ni pe bi awọn ti n lu ni awọn n jo, ọrọ ti jade si awọn ọga ileeṣẹ ijọba ibilẹ wọnyi leti pe o jọ pe Lamidi Ọlayiwọla lawọn Afọbajẹ n ba lọ o, bi wọn ba si fi le jokoo idibo, ọkunrin to ti Eko wa naa ni wọn yoo mu, nitori wọn ko fi ti Saji-ọlọpaa ibilẹ to wa lọdọ awọn ṣe rara. N ni wọn ba n da ọgbọn, wọn fẹẹ mọ bi wọn yoo ti ṣe eto naa ti awọn Afọbajẹ yoo fi fọwọ si ẹni ti awọn fẹ. Awọn Afọbajẹ naa ki i ṣe ọmọde, wọn mọ ohun to n lọ, lojiji ni wọn si kede pe awọn yoo ṣepade pataki nile olori ilu, Baṣọrun Eesuọla Akano, lọjọ kẹrin, oṣu kẹta ọdun, wọn ni nibi ipade naa lawọn yoo ti mọ ẹni ti yoo jẹ Alaafin.
Baṣọrun ni kinni ọhun ti n pẹ ju, o si ti yẹ ki awọn fi orukọ ẹni ti awọn fẹẹ mu ranṣẹ, nitori ẹ ni ipade naa ṣe ṣe pataki fawọn. Awọn alaga ati akọwe ijọba ibilẹ Ọyọ ko mọ, ninu iwe iroyin Daily Times ni wọn ti ka nipa ipade ọhun lọjọ naa gan-an, n ni wọn ba sare girigiri, wọn si kọ lẹta pajawiri kan ranṣẹ si Baṣọrun, wọn ni ko gbọdọ ṣe ipade kankan o, bẹẹ ni wọn ko si gbọdọ mu Alaafin kankan, nitori ọrọ kan wa nilẹ ti wọn kọkọ gbọdọ yanju, Gomina Adeyinka Adebayọ ni oun fẹẹ ri wọn ni Ibadan na, wọn si gbọdọ lọ ki wọn de ki wọn too waa mu ẹni ti yoo jẹ Alaafin. Ibi ti iwe naa ṣe pataki de, oludamọran fun gomina ni gbogbo ẹkun Ọyọ, Ọgbẹni Ade Ogunsanya, funra rẹ lo fọwọ si i. Aṣẹ nla leleyii, ko si sẹni to gbọdọ tẹ ẹ loju.
Ohun to kọkọ ba lẹta naa jẹ ni pe deeti to wa nibẹ, deeti ọjọ Sannde ni, Sannde, ọjọ kẹta, oṣu kẹta, 1968, ni wọn kọ sori rẹ, bẹẹ ko si ileeṣẹ ijọba ti i ṣiṣẹ ni Sannde. Ati pe ki lẹta naa too de ọdọ Baṣọrun ati awọn Ọyọmesi to ku, awọn tọhun ti ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe, boya aarọ tabi oru ni wọn tilẹ ti ṣe e paapaa ti ẹnikan ko mọ. Awọn ti mu Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi gẹgẹ bii Alaafin, wọn ni alẹ ọjọ Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, lawọn ti mu Lamidi ki iwe too de ọdọ awọn rara. Bi ilẹ si ti n mọ laaarọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu kẹta yii, ni wọn ti fi iwe orukọ Ọlayiwọla yii ranṣẹ si ileeṣẹ ijọba ibilẹ, awọn ijoye funra wọn ni wọn mu un lọ. Yatọ si bẹẹ, wọn ṣeto bi ikede naa ṣe jade lori redio lọsan-an ọjọ naa, to si jade ninu iwe iroyin lọjọ keji, n lọrọ ba dariwo.
Ninu awọn Afọbajẹ mejeeje, awọn mẹfa lo fọwọ si iwe yii, awọn naa si ni Tijani Eesuọla Akano ti i ṣe Baṣọrun, Amadu Akanni to jẹ Agbaakin, Salawu Adeleke to jẹ Alapinni, Sunmọnu Oyewọ ti i ṣe Lagunna, Salami Ladeji to jẹ Samu ati Salawu Adeniyi ti i ṣe Akinniku. Ẹni keje wọn ko si nipade, iyẹn Bello Oyekọla to jẹ Aṣipa, ṣugbọn wọn ni gbogbo ohun ti awọn ṣe yii lo fọwọ si. Eyi ni gbogbo eeyan fi gba pe awọn Afọbajẹ Ọyọ ti sọrọ, ko tun si kinni kan ti yoo yi i. Igba ti awọn Ọyọmesi yii de sẹkiteeria ni Ibadan lati ri Gomina Adebayọ ti wọn lo n pe wọn, oun kọ ni wọn ri nibẹ, wọn ni wọn o le ri gomina mọ, kọmiṣanna ni wọn yoo lọọ ri. Oloye B. A Ajayi ni kọmiṣanna ọrọ Oye fun Western State lọjọ naa, akọwe agba fun ileeṣẹ naa si ni Ọladipọ Batẹyẹ, awọn mejeeji si ni wọn ṣepade pẹlu awọn Ọyọmesi, fun bii wakati meji ni wọn si fi n ṣalaye ọrọ funra wọn ni sẹkiteeria ijọba.
Ko jọ pe ipade naa mu nnkan ti awọn to pe e n fẹ jade, nitori awọn Afọbajẹ yii binu pe o ya awọn lẹnu pe awọn ko le ri gomina gẹgẹ bii lẹta ti wọn kọ si awọn lọjọ Sannde to jẹ irọlẹ Mọnde lawọn ri iṣẹ wọn, Oludamọran ijọba to si fọwọ si lẹta naa gan-an ko wa lati pade awọn. Ipade naa ko ni itumọ gidi kan si wọn. Ṣugbọn awọn ti wọn pepade mọ ohun ti wọn yoo ṣe, nitori awọn ni wọn wa ni ijọba ibilẹ, awọn ni wọn si wa nile ijọba, bẹẹ Lamidi Adeyẹmi kọ ni wọn fẹ ni Alaafin. Nitori bẹẹ, latọjọ tawọn Afọbajẹ ti fi orukọ Lamidi ranṣẹ, alaga ati akọwe ijọba ibilẹ to yẹ ko kede orukọ rẹ ki wọn si kọwe fun un ko ṣe bẹẹ, wọn ko tilẹ ṣe bii ẹni pe lẹta kankan wa lọwọ awọn. Oṣu kin-in-ni kọja, oṣu keji tẹle e, sibẹ wọn ko gbọ nnkan kan. Ṣugbọn ko sẹni ti ko mọ pe lati ijọba ibilẹ Ọyọ ni wọn ti fi onde de kinni naa mọlẹ, o si jọ pe wọn ti ko bọwọbọwọ bọ gomina paapaa lọwọ, ko mọ eyi ti yoo ṣe.
Ṣugbọn Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi funra rẹ ti sọrọ, o ni ọrọ to wa nilẹ yii ko ruju, oun loun yoo di Alaafin. Oniroyin Daily Times to ba sọrọ beere lọwọ rẹ pe bawo lo ṣe mọ pe oun yoo jọba, nigba to jẹ ẹni to n ba a fa a yii lẹsẹ nilẹ ju oun lọ. Layiwọla ni, “Bo ba jẹ ti Sanda ni, ko le jẹ Alaafin, oun naa si mọ. Idi ti ko fi le jẹ Alaafin ni pe ko sẹni kan ti wọn n fi jẹ Alaafin nigba ti baba rẹ ba ṣi wa laye. Sannda ni baba, baba rẹ wa laye. Bo ba jẹ bi eto ti lọ ni wọn yoo tẹle e o, emi naa ni wọn yoo fi jẹ Alaafin. O si da mi loju pe yoo ṣee ṣe.” Eleyii fi ọkan awọn eeyan balẹ, iyẹn ọrọ akin ti wọn gbọ lẹnu ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn naa, wọn ni ẹni to tọ lati jẹ Alaafin ni loootọ. Igba ti awọn ijọba ibilẹ waa kọ ti wọn ko dahun yii nkọ o.
Awọn Afọbajẹ jokoo. Awọn Ọyọmesi jokoo. Awọn araalu n woye ara ti awọn eeyan yii fẹẹ da. Lojiji lawọn alaga ijọba ibilẹ yii tun pe awọn Afọbajẹ, wọn ni ibo ti wọn sọ pe awọn di ni ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, 1968 lati yan Lamidi Ọlayiwọla bii Alaafin yẹn ki i ṣe ibo gidi kan, awuruju ni, nitori ko si aṣoju awọn nibẹ, bẹẹ ni ijọba ibilẹ awọn ko lọwọ si i. Wọn ni ki wọn dajọ ibo didi mi-in, ki wọn si mu ẹni ti wọn ba fẹ ninu awọn meji yii, nigba naa lawọn yoo too mọ pe gbogbo Afọbajẹ lo fọwọ si i. Awọn Ọyọmesi mọ pe kinni naa ti fẹẹ lọwọ kan abosi ninu, ṣe bi ko ba nidii, obinrin ki i jẹ Kumolu, bi obinrin kan jẹ Kumolu, iku ti mu akọni ile wọn lọ ni. Ati pe bi ki i baa ṣe pe ọrọ bajẹ tan pata, Iya suna ko ni i perun ninu mọṣalaaṣi. Eewọ ni! Ṣugbọn awọn Ọyọmesi yii ko sọrọ o, wọn o sọ pe awọn ko fẹ, wọn n duro de ibo tuntun ti wọn yoo di, wọn ni kawọn ara ijọba ibilẹ naa mu ọjọ to ba tẹ wọn lọrun funra wọn.
N ni wọn ba tun mu ọjọ tuntun o, wọn si fi ọjọ naa si ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu kẹfa, ọdun 1968. Ile Baṣọrun Eesuọla Akano naa ni wọn fi ipade naa si, ẹsẹ si pe wamuwamu nitori eyi ti wọn fẹẹ ṣe yii, ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye ni Western Region lati Ibadan ba wọn lọwọ si i. Oludamọran tuntun ni wọn fi ranṣẹ si wọn paapaa, wọn ni awọn ko fẹ ki ọrọ naa da bii pe ojoro wa nibẹ. Ọlọrun nikan lo mọ ohun ti agbọnrin jẹ tẹlẹ ikun, ko too ṣe ikun gbentọ si ọlọdẹ, bi ko ba bẹru ẹtu, ṣe ko tun bẹru ọta ni. O ni kinni kan ti awọn ijọba yii gbojule, ko kan sẹni to mọ ni. Nigba ti wọn de ipade, Oludamọran to ṣaaju wọn wa, Ọgbẹni A.O. Oyediran, sọ pe ki akọwe ijọba ibilẹ Ọyọ, B. Taiwo ka awọn lẹta to wa lọwọ rẹ, awọn lẹta to n da ede-aiyede silẹ laarin wọn, ki awọn too bẹrẹ eto naa rara, ki awọn Ọyọmesi funra wọn si gbọ nnkan to n lọ.
Ni Taiwo ba ko lẹta meji jade. Lẹta akọkọ ni eyi ti awọn aṣoju meji kan kọ, ti wọn ni awọn n kọ ọ lorukọ gbogbo idile Alowolodu, ti wọn ni awọn ti fẹnu ko pe ẹni kan ṣoṣo ni gbogbo awọn yoo fa kalẹ, ẹni ti awọn si fa kalẹ naa ni Sanda Ọladepo Adeyẹmi, oun ni gbogbo awọn fọwọ si ko jẹ Alaafin. Ohun to mu lẹta eleyii jọ pe o lọwọ kan abosi ninu ni pe awọn meji pere ni wọn fọwọ si i. Lẹta keji ti wọn tun ka nibẹ ni eyi ti awọn Baba-iyaji kọ, iyẹn awọn olori ọmọọba ọkunrin ati ọmọba obinrin fun gbogbo idile mẹwẹẹwa ninu ẹbi Alowolodu. Ninu lẹta ti awọn kọ yii, ọrọ eeyan mẹwaa ni wọn fi ranṣẹ lati idile kọọkan, awọn mẹwẹẹwaa yii si ni awọn Afọbajẹ ṣiṣẹ le lori, ki wọn too mu ẹni ti wọn mu, ki ọrọ too di ariwo. Lẹyin ti wọn ka lẹta naa tan ni Oyediran to wa lati Ibadan sọ pe ṣe awọn Ọyọmesi ti gbọ, ohun to jẹ ki awọn tun waa jokoo ree o, ki wọn tun ibo gidi di loju awọn.
Ọrọ naa ko la ariyanjiyan ninu, ko si la ariwo kankan. Eyi ti a n wi yii ti pẹ, awọn Ọyọmesi yii ti tun dibo, nigba ti wọn si ka ibo naa loju gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ, awon Afọbajẹ mejeeje ko dibo ẹyọ kan fun Sanda, ibo mejeeje, Adeyẹmi ni wọn ba lọ. Ko tilẹ too di pe ọrọ naa jade sita ni ọjọ karun-un, oṣu kẹfa yii, ariwo ti gbalu kan pe Lamidi Ọlayiwọla lawọn Ọyọmesi tun mu o. Ariwo ọrọ naa ko si duro ni Ọyọ nikan mọ, o ti kari gbogbo ilẹ Yoruba, awọn eeyan si ti fẹẹ mọ ẹni ti wọn n pe ni Lamidi yii, ati ọjọ ti wọn yoo gbe ade rẹ fun un. Ṣugbọn kinni kan ko dun mọ awọn ara ijọba ibilẹ ninu, ijọba West naa si ti tọwọ bọ ọ, nitori loootọ ni wọn dibo ti wọn mu ọmọọba yii, to si jẹ oju aṣoju ijọba wọn lo ṣe, sibẹ wọn ko dunnu si abajade idibo naa rara, o si han gbangba bayii pe wọn ko fẹ Ọmọọba Lamidi Ọlayiwọla lọba wọn, Saji-ọlọpaa Ọladepo ni wọn fẹ
Lati fi eleyii han, lojiji ni ijọba gbe iwe kan jade lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, wọn ni ọrọ ija to n ṣẹlẹ lori ọrọ oye Alaafin ti le bayii debii pe ijọba gbọdọ da si i, awọn si ti gbe igbimọ kan dide lati wadii gbogbo ohun to ṣẹlẹ, ki ijọba le mọ ohun ti yoo ṣe. Ohun ti awọn eeyan n beere ni pe ija wo lo ṣẹlẹ, nibo lo ti ṣẹlẹ, ta lo ba ara wọn ja, ṣebi awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ọyọ lo n ṣe ohun to wu wọn, o si ti han bayii pe ijọba fẹran ohun ti wọn n ṣe. Ṣugbọn gbogbo iyẹn ko de eti ijọba, ohun ti wọn ṣa sọ ni pe awọn ti gbe igbimọ kan dide, igbimọ naa yoo si bẹrẹ iṣẹ kiakia. Ijọba ṣalaye ẹnu wọn fẹrẹ bo, wọn ni bi wọn ti n jọba ilu Ọyọ ni pe awọn ọmọ oye yoo fi orukọ ranṣẹ si awọn Baba-iyaji, awọn Baba-iyaji yoo fi orukọ ranṣẹ si Baṣọrun, Baṣọrun yoo pe awọn Ọyọmesi jọ, wọn yoo si mu ẹni ti wọn ba fẹ ninu wọn. Ko si ohun kan ti awọn Ọyọmesi ṣe to ju eleyii naa lọ, ohun to waa fa ibinu ijọba ko ye ẹnikan.
Nigba to di Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu kẹfa, igbimọ ti ijọba Western State naa gbe dide bẹrẹ ijokoo rẹ. Adajọ majisireeti kan, Adeṣina Obilẹyẹ, ni wọn fi ṣe alaga igbimọ yii, oun nikan naa si ni igbimọ paapaa, nitori yatọ si awọn oṣiṣẹ, ko tun si ẹni ti wọn le jọ fikunlukun lori ọrọ yii, ohun to ba da lẹyin iwadii ni abẹ ge. Bo ti bẹrẹ ọrọ naa lọjọ naa lo kede pe ki gbogbo ẹni ti ọrọ ba kan, tabi gbogbo ẹni to ba ni ohun lati sọ ko waa sọ ọ niwaju igbimọ oun, tabi ko kọwe ranṣẹ soun ni ileeṣẹ ijọba ibilẹ Ọyọ, iwe naa yoo de ọdọ oun. O ni iṣẹ to wa niwaju oun ki i ṣe iṣẹ to le rara, laarin ọsẹ kan pere loun si fẹẹ fi ṣe iṣẹ naa, ki ọrọ oye Alaafin le yanju kiakia. Ṣugbọn oun lo ro pe ọrọ naa ko le, awọn ti ọrọ kan mọ pe kinni naa ki i ṣe kekere, wọn si ti tẹsẹ bọ ọ daadaa. Bo ti sọrọ tan bayii ni Abiọdun Akerele dide, o ni oun ni lọọya fun Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi.
Abiọdun Akerele ki i ṣe eeyan kekere, lọọya ati oloṣelu nla ni, ọrẹ si loun ati Awolọwọ, koda, wọn jọ da ileeṣẹ lọọya silẹ ki ọrọ oṣelu too da ija silẹ laarin wọn ni. Akerele ni ki i ṣe oun nikan loun da wa, o ni Ọgbẹni Afẹ Babalọla wa pẹlu oun, ati Tunde Alaka, awọn ni lọọya fun Baṣọrun ilu Ọyọ ati awọn Ọyọmesi mẹrin mi-in. Nibẹ naa ni Ṣobọ Ṣowẹmimọ naa ti dide, o ni oun ni lọọya fun awọn Baba-iyaji ati olori ẹbi Alowolodu. Lẹyin naa ni Dayọ Ogundare to jẹ ọga agba agbẹjọro ijọba Western State dide, o ni oun ni lọọya fun ijọba ati ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye, oun si wa lati ṣoju ijọba nibi ẹjọ yii ni. Nigba naa ni Alaga igbimọ yii mi kanlẹ, oun naa ti ri i pe ẹjọ naa ki i ṣe kekere bi oun ti ro o, ọrọ to le gba ọja oko, ko tun gba ọna odo lọwọ ẹni ni. Ṣugbọn ọrọ naa ko le to bẹẹ, ṣe orin ti ko ba ṣoro o da ni, egbe rẹ naa ki i nira lati gbe, ọsẹ kan geere naa ni Obilẹyẹ fi ṣe iṣẹ rẹ, ijokoo naa si wa sopin.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹfa, ọdun ni igbimọ to gbọ ẹjọ ọrọ oye Alaafin yii pari iṣẹ wọn, bo si tilẹ jẹ pe ni kọrọ ni wọn ti ṣe gbogbo ẹ ti ki i ṣe gbangba ni ojutaye, awọn eeyan kuku gbọ pe gbogbo ọrọ ti wọn sọ nibẹ naa, awọn ti wọn tẹle Layiwọla lẹyin bii Alaafin naa ni wọn n bori. Ṣugbọn iyẹn ki i ṣe ọrọ ijọba, o digba ti ijọba ba fi ẹnu ara rẹ sọrọ, bẹẹ ni ijọba ki i tete sọrọ, iwe nijọba n kọ. Ohun ti kaluku waa n ro ni pe iwe yoo jade laipẹ bi iwe ba si ti jade, ko si ohun ti yoo wa ninu iwe naa ju pe ki wọn gbe ade falade, ki wọn gbe oye fun ẹni to loye, ki wọn fi Ọmọọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ṣe Alaafin. Ni tootọ ni tootọ, lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹfa, Kọmiṣanna Ikede ni West, Bisi Ọnabanjọ, sọ fawọn oniroyin pe abajde ijọba lori iwadii ti igbimọ Adeṣina Obilẹyẹ ṣe lori Alaafin yoo jade lọjọ keji. O ni wọn ti pari iwe naa, wọn si ti fihan oun, ko si si ohun ti yoo tun da a duro mọ. N ni gbogbo aye ba gbojusoke lọjọ keji ti i ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 1968, wọn n reti ohun ti yoo ti ẹnu ijọba jade.
Ṣugbọn Ifa ọrọ naa ko fọre pẹẹ! Ohun to ti ẹnu ijọba jade ko dara. Ọrọ naa ki i ṣe ọrọ lasan paapaa, Gomina Adeyinka Adebayọ funra rẹ jade pẹlu ofin ologun ni. Ofin naa si le koko. O paṣẹ waa pe laarin ọjọ mẹrinla pere, iyẹn ọjọ mẹrinla si ọjọ ti ofin oun yii jade, Baṣọrun ilu Ọyọ, Tijani Eesuọla Akano, gbọdọ pepade awọn Ọyọmesi, ko si gbe orukọ Sanda Ọladepo Ọranlọla Adeyẹmi siwaju wọn, ki wọn si fi orukọ naa ranṣẹ si ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye ni Western State, gẹgẹ bii ẹni ti awọn mu fun Alaafin. Gomina Adebayọ ni Sanda Ọladepo Ọranlọla Adeyẹmi lawọn Babaiyaji fi orukọ rẹ ranṣẹ si Baṣọrun gẹgẹ bii ẹni ti wọn mu fun Alaafin, oun naa si ni ki Baṣọrun ati awọn Ọyọmesi fi oruikọ rẹ ranṣẹ sileeṣẹ ijọba laarin ọjọ mẹrinla, ko gbọdọ ju bẹẹ lọ.
Ki lo de ti Brigedia Adeyinka Adebayọ yoo gbe iru ofin bayii jade, ti yoo si fọwọ si i funra rẹ. Ijọba ṣalaye, bo tilẹ jẹ pe alaye naa ko wọ awọn Ọyọmesi ati ọpọlọpọ eeyan leti rara. Ijọba ni ni gbara ti Alaafin Gbadegẹṣin waja, olori ẹbi Alowolodu pe ipade gbogbo awọn ẹbi wọn, nibẹ ni wọn si ti pinnu pe orukọ ẹni kan pere lawọn yoo fi silẹ, ati pe orukọ ti awọn oo fi silẹ ni ti Sanda Ọladepo Ọranlọla Adeyẹmi. Ijọba ni igbimọ ti awọn gbe dide lo ṣalaye pe ninu iwadii awọn lawọn ti mọ pe orukọ Sanda ni olori ẹbi Alowolodu fi ranṣẹ si Baṣọrun, ṣugbọn Baṣọrun lo fi orukọ naa pamọ ti ko mu un jade, to waa ko orukọ awọn mi-in jade, ninu eyi ti orukọ ẹni kan ti wọn n pe ni Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi jade, to sọ pe oun naa fẹẹ du ipo Alaafin. Ijọba ni eleyii lodi si agbekalẹ iwe ofin ọrọ ọba jijẹ ni West, nitori ẹ lawọn si ṣe fẹ ko jẹ Baṣọrun funra rẹ ni yoo ṣe atunṣe.
Ijọba Adeyinka Adebayọ ni iwadii lawọn tẹle o, ohun ti iwadii naa si fihan ni pe Sanda Ọladepo Ọranlọla Adeyẹmi nikan ni awọn Baba-iyaji fi orukọ rẹ ranṣẹ lọna to tọ, ọna ẹburu ni orukọ to ku ba de ọdọ awọn Ọyọmesi, eleyii ko si ni ṣee ṣe. Ofin Adebayọ sọ pe ọrọ naa ko ni a n fi epo bọ iyọ ninu mọ, ki awọn Ọyọmesi ṣepade kia, awọn n reti orukọ Ọranlọla lọdọ awọn.
“Họwuuu!” Ariwo ti Baṣọrun Eesuọla Akano pa ree. O ni irọ nla nijọba ati awọn eeyan rẹ pa mọ oun to to bayii. Kia lawọn Ọyọmesi si ti ṣepade idakọnkọ, wọn kọkọ fẹẹ wo o pe ki awọn pe lọọya, ko ba awọn tumọ ọrọ yii, tabi ki awọn kuku pa ọkan ninu aṣa ilu Ọyọ rẹ ni. Aṣa ibilẹ naa ni pe Sanda ti wọn n pariwo orukọ rẹ yii ni baba, bẹẹ ni Alaafin to ba jẹ ki i ni baba laye!
Loootọ lawọn Ọyọmesi fẹ ẹ, awọn araalu naa fẹran rẹ, wọn fẹ ko di Alaafin. Ṣugbọn ijọba Western State atawọn ara ijọba ibilẹ Ọyọ ko fẹ Ọmọọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi gẹgẹ bii Alaafin. Bawo ni yoo waa ti ṣe e?
Ẹ maa ka a lọ ninu Alaroye ọsẹ to n bọ yii o.

(1415)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.