Eyi ni ilu Ipokia, nibi ti ọba wọn ti binu wole laaye *Wọn ki i ta ẹpa nibẹ *Ẹṣin ki i wọnu ilu naa.  Eewọ ladalu sise ta, bee ni wọn ki i lọta alẹ

Spread the love

Ipinlẹ Ogun ni Ipokia wa, ẹni to ba fẹẹ debẹ lati Eko tabi awọn ilu mi-in yoo ni lati gba Owode/Idiroko kọja. 

Yewa lawọn ara Ipokia, awọn kan ṣẹ wa lati Iṣẹyin ninu wọn bi wọn ṣe wi, awọn mi-in si sọ pe ede Anago tawọn n sọ nibẹ yii, wọn ni ede Ọyọ ni.

 

Wọnyi lawọn nnkan eewọ ti wọn ki i ṣe n’Ipokia titi doni, gẹgẹ bawọn agbaagba ilu naa ṣe salaye fun ADEFUNKẸ ADEBIYI, akọroyin ALAROYE nipinlẹ Ogun.

 

Oloye Ọmọba Samuel Adeyẹmi Ọlaawin—-

 

‘Ka kọkọ bẹrẹ lati ori ọba to jẹ n’Ipokia yii, to si pada binu wọlẹ pẹlu awọn iyawo ẹ atawọn nnkan ọsin ẹ bii aja ati ẹṣin. Onigbaale kin-in-ni, Oṣupa-o-pe meji, lorukọ ọba naa, oun lọba kẹta to jẹ niluu yii lẹyin ti wọn tẹ ẹ do. Ipokia ko le gbagbe ẹ laye yii.

 

‘’Itan sọ fun wa pe awọn mọlẹbi ọba Onigbaale lo dide ọtẹ si i lojiji, wọn lẹdi apo pọ, wọn ni ko fi ori oye naa silẹ fawọn.

Bẹẹ, ko sẹni ti i yọ ọba loye bi ko ba jẹ pe o ṣe aṣemaṣe. Iku lo yẹ ko bọṣọ lọrun ewurẹ lọrọ ọba jijẹ. Ṣugbọn wọn fooro Ọba Onigbaale, wọn ni afi ko fi ori oye silẹ.

Ohun to bi i ninu niyẹn to fi dide pẹlu awọn iyawo atawọn idile ẹ, ni wọn ba lọọ wọle sinu igbo, nibi ta a n pe ni ‘titi Onigbaale’ loni-in.

Oju titi naa, ko si ọba to jẹ ni Ipokia yii to gbọdọ gba ibẹ kọja. Ọba to ba da a laṣa yoo waja lẹsẹkẹsẹ ni.

 

‘’Ẹwọn (chain), kan wa nibẹ to jẹ ti Onigbaale, awọn akọni to ba wọbẹ lo le fa a lasiko ti wọn ba n wure, eeyan lasan ki i debẹ.

‘‘Ma gbiyanju lati debẹ o, ita igbo yẹn nikan ni ko o ya, eeyan lasan ki i wọnu Igbo Onigbaale o.

‘’Ninu igbo ti Onigbaale wọlẹ si yii, eeyan ko le mu nnkan meji jade nibẹ. Teeyan ba he igbin nibẹ, ko tun gbọdọ mu igi tabi nnkan mi-in.

To ba mu nnkan mi-in, ko ni i rọna jade mọ, ọna maa parẹ mọ ọn loju ni.

 

‘’Aṣẹ ni eyi latigba ti Onigbaale ti wọlẹ, bo si ṣe wa titi doni niyẹn.

‘’A ki i lagi alẹ nibi, bẹẹ la ki i lagi loru.  Eewọ tun ni lati lọta lori ọlọ lalẹ. Ẹni to ba dẹjaa, yoo foju ara ẹ ri ijiya ibẹ lẹsẹkẹsẹ ni.

Ni ti adalu (ẹwa ati agbado), ti a ki i se ta n’Ipokia, ogun kan lo ja wa lasiko kan, o lagbara pupọ. Nigba ti a maa waa ṣẹgun naa, ẹwa alagbado ni wọn se, ti wọn fi majele si i, ti wọn si gbe e lọ soju ogun naa, lawọn ọta wa ba jẹ ẹ, bi gbogbo wọn ṣe ku niyẹn.

 

‘’Latigba naa lo ti di eewọ lati gbe igba adalu tita niluu yii, ko sẹni to n se e ta. Ẹni to ba fẹẹ jẹ ẹ le se e ninu ile ẹ, ko jẹ ẹ, ṣugbọn ko ni i jẹ ẹ ni gbangba ita o, inu yara rẹ ni yoo ti jẹ ẹ.

 

‘’Bẹẹ naa ni ẹpa, a ki i ta ẹpa yiyan nibi.

Igbona lo wọlu nigba kan to pọ gan-an. Iwadii lo jẹ ki wọn mọ pe ẹpa yiyan maa n da kun igbona ni, ti yoo maa gbilẹ si i. Wọn waa ṣofin pe ẹnikẹni ko gbọdọ yan ẹpa ta n’Ipokia.

 

 ‘’Ẹni to ba fẹẹ jẹ ẹ le maa jẹ ẹ ninu yara ẹ, ṣugbọn a ki i yan an nibi.  A le ra a wa lati ibomi- in, ka wọnu ile jẹ ẹ.’’

 

Bayii ni Ọmọọba Adeyẹmi Ọlaawin pari alaye tiẹ nipa ilu Ipokia.

 

Mama Aboto Ojo (Ẹni ọdun mejilelaaadọrun-un), naa ṣalaye nipaỌba Onigbaale ti wọn ki i fi ṣere n’Ipokia. Alaye mama agba naa ree:

 

‘’Ọba Onigbaale Ẹkun, ọba a san wọlẹ bii arira, ọmọ igbo biri, okunkun biri, ọmọ ọrun ọla ti o ṣee bẹ lori. Aye o ni i bẹ ọrun wa o.

 

‘’Ọba Ipokia ni Onigbaale to wọlẹ si Iloo. Ki i ṣe pe Onigbaale naa fẹẹ ku, ko wu u ko wọlẹ, ibinu lo fa a nigba tawọn eeyan

gbogun ti i.

 Lo ba jade nile pẹlu awọn iyawo ẹ mejila, ati aja ẹ, ati ẹṣin, ti gbogbo wọn fi wọle si ọna tẹ ẹ gba kọja nigba tẹ ẹ n bọ yẹn.

 

‘’Ọkan ninu awọn iyawo mejila yẹn di odo ni tiẹ ni, ko wọlẹ bii awọn yooku. Odo naa wa lẹgbẹẹ Onigbaale nibẹ fun igba pipẹ. O ti gbẹ bayii, ṣugbọn igbo Onigbaale wa nibẹ, nibi ti ọba Ipokia ki i gba kọja, teeyan ko si le mu nnkan meji jade nibẹ.

 

‘’Ẹni to ba ṣẹgi ninu igbo Onigbaale, ibẹ kọ ni yoo ti mu okun ti yoo fi di igi naa. To ba tun gbiyanju lati mu okun lẹyin to ṣẹgi tan, ọna maa di mọ ọn loju ni, ko ni i jade ninu igbo naa mọ, afi to ba ju ọkan silẹ ninu ohun meji to mu’’

 

Jamiu Ọladega: Afọbajẹ Ipokia:

‘‘Iga ti a ti n fọbajẹ ni ilu Ipokia yii ni a n pe ni Ilusa, awa la n fọba jẹ. Bi wọn ko ba ri wa, ọba kankan ko le jẹ. Ọmọ oye ti a ko ba fọwọ si ko le jọba pẹlu.

 

‘’Lati ilu Iṣẹyin lawọn baba nla wa ti ṣẹ wa sibi. Ile afọbajẹ tẹ ẹ n wo lọọọkan yẹn la maa n mu ọba wọ. Bi ọba ko ba ti i wọbẹ, ko ti i di ọba. Aṣẹ ọba ni wọn n gba nibi.

 

‘’Oriṣa ti a n bọ nibi ni Koṣeegbe Iwọrẹrẹ alapo ẹkun. A kọle fun Oriṣa Koṣeegbe, a maa n wure nibẹ ni. Iyawo ni Koṣeegbe, ọkọ ẹ lo wa ninu ile Ilusa yẹn.

 

 ‘’Ẹni to ba wọnu ile Iwọrẹrẹ lai yẹ ko wọbẹ le fọ loju. Ẹ ko le gbe kamẹra yin yii wọbẹ rara, ko gbọdọ ṣẹlẹ. Ṣugbọn adura ti a ba ṣe nibẹ maa n ṣẹ ṣaa ni.

 

‘’A ki i sufee ni gbogbo ayika ile oriṣa Koṣeegbe. Bi alejo ba wọlu, ẹni to waa ki nibi gbọdọ ti sọ fun un pe wọn ki i sufee nibi o, eeyan ko si gbọdọ dẹjaa, ko ni oun yoo sufee ni toun.

 

‘’Ẹni to ba sufee ni gbogbo ayika Koṣeegbe, ṣẹ ẹ mọ kokoro ti wọn n pe ni ikan?, to maa n mu nnkan delẹ, to si maa ba a jẹ yẹn, kokoro yẹn lo maa bo gbogbo kọnbọọdu, baagi tabi apoti ti ẹni to sufee yẹn ba n ko aṣọ ẹ si jẹ, o maa ba aṣọ inu rẹ jẹ patapata ti tọhun a maa tọrọ aṣọ wọ ni.

Kaluku wa lo ti mọ ọn leewọ, ko sẹni to n sufee lagbegbe yii rara.

 

‘’Ọjọ mẹsan-an mẹsan-an la maa n bọ awọn oriṣa yii, to ba di loru ọjọ ta a ba bọ wọn, Oriṣa Koṣeegbe maa jade, aa maa sufee kaakiri adugbo laarin oru, awọn eeyan aa maa gbọ, ṣugbọn ẹnikẹni ko ni i jade lati foju ri i. Afẹni to ba n wa wahala. Oriṣa naa lo n sufee, ko sẹni to n ba a daṣa ife-susu nibi rara’’

 

Bayii ni wọn ṣalaye fun wa nipa ilu Ipokia.  Ipokia ọmọ Ipokimẹkun. Awọn lọmọ aṣudẹdẹ bii ojo, ọmọ agbajoji ma gbonilẹ. (A gbe ajoji ma gbe onilẹ) Ipokia, ọkan pataki nilẹ Yewa.

 

Ko sọba n’Ipokia lasiko yii, Ọba Raufu Ọladeyinde Adetunji Ade-ọlẹ, to jẹ kẹyin nibẹ ti waja lati bii ọdun meji sẹyin.

 

Aṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun lo ku tawọn ilu n reti gẹgẹ bi Oloye Eesemọ atawọn oloye yooku ṣe wi. Awọn ọmọ oye to fẹẹ jọba ti wa nilẹ biba, bẹẹ lawọn afọbajẹ ko rebikan.

 

 

 

(307)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.