Eyi ni idi ti Buhari ṣe fagile abẹwo si ipinlẹ Kwara

Spread the love

Iwadii ti fi han pe abẹwo ipolongo ibo si ipinlẹ Kwara to yẹ ko waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni Aarẹ Muhammadu Buhari fagile nitori idajọ ile-ẹjọ giga Kwara to kede Ishọla  Balogun-Fulani, bii alaga ẹgbẹ APC.

Aarẹ Buhari, Alaga apapọ APC, Adams Oshiomhole, adari ẹgbẹ lapapọ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, atawọn oloyẹ ẹgbẹ APC lo yẹ ki wọn lọọ ṣe ipolongo nipinlẹ Kwara ati Kogi, ṣugbọn ti Aarẹ sun ti ipinlẹ Kwara siwaju lati duro de igbesẹ ti ajọ eleto idibo INEC, fẹẹ gbe lori aṣẹ ile-ẹjọ.

ALAROYE gbọ pe awọn amugbalẹgbẹẹ Aarẹ Buhari lo gba a nimọran lati ni suuru diẹ fun abẹwo si ipinlẹ Kwara, ki Ajọ INEC fi gbe orukọ awọn ojulowo oludije jade.

Ọsẹ to kọja yii lo yẹ ki ajọ eleto idibo gbe gbogbo orukọ awọn oludije APC to maa kopa ninu idibo to n bọ jade nipinlẹ Kwara.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn alaabaṣiṣẹpọ Aarẹ ko fẹ ki awọn eeyan maa ri Buhari bii ẹni to n tapa si aṣẹ ile-ẹjọ, nitori naa ni wọn ṣe gbe igbesẹ naa lati le gba alaafia laaye.

Wọn ni ko ni i bojumu fun Buhari lati gbe asia ẹgbẹ APC fun Abdulrahman Abdulrasaq, pẹlu bi oludije meji ọtọọtọ ti ṣe wa nilẹ bayii, ati pe idajọ ile-ẹjọ naa ṣi n da Aarẹ lọwọ kọ.

Ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Kwara ninu idajọ rẹ paṣẹ pe ikọ ti Balogun-Fulani n dari ni ojulowo, o fagile igbimọ alakooso Bashiru Bọlarinwa ti Oshiomhole gbe kalẹ.

Idajọ yii lo mu ki awọn oludije APC pin si meji. Abdulwahab Ọmọtoṣẹ lawọn igun Balogun-Fulani fa kalẹ lati dupo gomina. Bakan naa lawọn igun keji gbe Abdulrahman Abdulrasaq kalẹ bii oludije wọn.

Lọna mi-in ẹwẹ, adari ikọ ipolongo idibo fun Aarẹ Buhari to tun jẹ oludije fun ipo gomina nipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ti ni ko si ootọ ninu iroyin to n kaakiri pe Aarẹ Buhari fẹẹ ṣabẹwo si ipinlẹ Kwara.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ẹgbẹ APC, Alhaji Tajudeen Aro, fi sita lo ti ni awọn yoo kede ọjọ ti Buhari maa wa si Kwara fun ipolongo fun gbogbo araalu ti asiko ba to.

 

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.