Eyi ni bi tirela ṣe ran ọpọ eeyan sọrun n’Iworoko Ekiti *Irẹsi ti wọn ya fọto oloṣelu kan si lo ko *Iya atọmọ wa ninu awọn to ku *Ijọba Ekiti ṣeleri iranlọwọ fawọn to farapa Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Spread the love

Fun igba pipẹ lawọn eeyan ilu Iworoko Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, yoo maa ranti ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, latari ijamba manigbagbe to waye nibẹ, nibi tawọn ti ko din ni mejila ti jẹ Ọlọrun nipe, tawọn pupọ si farapa yannayanna.

Iwadii ALAROYE fi han pe ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ ọjọ naa lawọn eeyan deede gbọ ariwo, nigba ti wọn yoo si fi mọ nnkan to n ṣẹlẹ, tirela kan to n bọ lati ọna Ifaki ti kọlu awọn mọto kan, ṣe lo si waa sẹri mọ awọn ṣọọbu inu ọja ilu naa.

A gbọ pe ọkọ Toyota Camry kan ni tirela naa kọkọ gbe hanu to si n wọ lọ ko too fa ọkọ kekere kan ti wọn n pe ni korope, afi bo ṣe tun gun ori gegele to pin titi si meji, to si ya wọ awọn ṣọọbu kan tawọn eeyan wa.

Apo irẹsi kekere (kilogiraamu mẹẹẹdọgbọn) ati nla (aadọta kilogiraamu) ni tirela yii ko, wọn si lẹ aworan Sẹnetọ Ọmọtayọ Alaṣọadura to n ṣoju Aarin-Gbungun Ondo nile igbimọ aṣofin agba mọ awọn kan nibẹ.

Nigba tawọn eeyan yoo sare debẹ, oku ti sun, ṣugbọn wọn sa gbogbo ipa wọn lati yọ awọn to ti padanu ẹmi wọn atawọn to ṣi wa laaye, wọn si sare gbe gbogbo wọn lọ sileewosan Ekiti State University Teaching Hospital (EKSUTH), to wa l’Ado-Ekiti pẹlu iranlọwọ ajọ ẹṣọ oju popo, awọn agbofinro ati awọn eeyan mi-in.

A gbọ pe awọn ọmọleewe Ekiti State University, agunbanirọ kan atawọn mi-in ta a ti i mọ bi wọn ṣe jẹ lo faragba ninu iṣẹlẹ ọhun.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Mama Raliatu Karimu to jẹ olugbe ile tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ niwaju ẹ sọ pe ariwo loun deede gbọ tiẹkun si gba gbogbo agbegbe naa.

Mama agbalagba naa ni obinrin kan to n jẹ Funmilayọ, ọmọ ẹ atọmọ-ọmọ wa lara awọn tiṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe Funmilayọ atọmọ ẹ ku, nigba ti ẹsẹ ọmọ-ọmọ ẹ run.

Bakan naa ni Alagba Tijani Ganiyu to jẹ olori awọn to ni sọọmeeli l’Ekiti sọ fun wa pe dẹrẹba to wa tirela ọhun sun lọ ni, ki i ṣe pe bireeki ja.

Tijani ti aburo rẹ obinrin kan atọmọ ẹ wa lara awọn to jẹpe Ọlọrun sọ pe, ‘’Mọto yẹn deede ya kuro lori titi, ọna to lọ si Are Ekiti yii lo si ya si ko too kọlu awọn ṣọọbu yẹn. Ibi kan wa to jẹ pe ṣọọbu bii mẹta lo wa nibẹ, gbogbo ẹ lo run womuwomu.’’

Nigba ti yoo fi di aarọ ọjọ keji iṣẹlẹ naa, awọn ọdọ kan ti fabinu yọ, koda wọn koju awọn ọlọpaa kan to wa sibẹ, wọn le awọn oṣiṣẹ oju popo, wọn si fi igi di titi ilu naa pa. Ariwo ti wọn n pa ni pe awọn oloṣelu lo da ẹmi awọn eeyan awọn legbodo

kẹdun.

Nigba to n sọrọ laafin Ọba Michael Olufẹmi Aladejana, Alaworoko tilu Iworoko Ekiti, Ẹgbẹyẹmi ni ijamba naa ba ni ninu jẹ gidi, ṣugbọn ijọba yoo ṣeranlọwọ fawọn to faragba, mọlẹbi wọn, ọja ilu naa ati Iworoko lapapọ. O waa pẹtu sawọn araalu naa ninu pe jagidijagan ko le ran ẹnikẹni lọwọ niru asiko bẹẹ, ki wọn ṣe suuru ki nnkan le lojutuu.

Lẹyin naa lo lọ sileewosan EKSUTH, nibi tawọn mọlẹbi awọn to farapa ti fẹdun ọkan sọ pe wọn ko ti i tọju awọn eeyan awọn daadaa. Kia lo paṣẹ pe ki itọju bẹrẹ lakọtun nitori ijọba ni yoo san gbogbo owo naa.

 

Nigba to n fọrọ ikẹdun ranṣe nipasẹ Dayọ Josẹph to jẹ agbẹnusọ rẹ, Sẹnetọ Alaṣọadura ni ileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣe irẹsi nipinlẹ Kebbi ni wọn ti n ko awọn apo irẹsi ọhun bọ, eyi to jẹ ọna lati ṣe igbelarugẹ fawọn nnkan tiwa-n-tiwa. O ni awọn eeyan ẹkun idibo oun lo ni awọn irẹsi naa, asiko Keresi si ọdun tuntun lo si yẹ ki wọn ti ko o wa, ṣugbọn ti idiwọ diẹ wa.

 

O waa ba awọn tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si kẹdun, bẹẹ lo ni ki Ọlọrun tu mọlẹbi wọn ninu, ko si fun awọn to farapa lalaafia.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.