Eyi ni bi Sunday ṣe pa Oloye Bademọsi-Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko

Spread the love

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti fi atẹjade sita lori ọna ti ọmọọdọ Oloye Ọpẹyẹmi Bademọsi gba pa a. Ọmọkunrin kan, Kofi Friday, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ni wọn lo pada de lati ilu Togo si orileede Naijiria, oun lo si ranṣẹ pe afurasi to pa oloye naa, Sunday Adefonou Anani, ẹni ọdun mejilelogun, lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu to kọja, pe ko waa ba oun nile laduugbo Yaba, niluu Ondo, pe oun ti baa ri iṣẹ ọmọọdọ. Atẹjade naa, eyi ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Chike Oti, buwọ lu ṣalaye pe aburo ni Sunday jẹ si Kofi. O ni iṣẹ kuuku, iyẹn alase loun ba a ri nile baba olowo kan laduugbo Ikoyi, niluu Eko. Kofi sọ fun Sunday pe ọrẹ oun kan, Agbeko Ayenahin, lo ba oun ba a wa iṣẹ naa.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu to kọja, ni wọn mu Sunday, ẹni ọdun mejilelogun, lọ si ile Oloye Bademọsi niluu Ondo. Iwadii awọn ọlọpaa fi han pe ọjọ Furaidee to ba pari oṣu ni oloye naa maa n wa niluu Ondo, to si maa n pada siluu Eko lọjọ Aiku, Sannde.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni oloogbe naa mu Sunday wa si ilu Eko, to si ni ko bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii kuuku. Ọjọ kẹta lẹyin ti ọmọ Togo yii bẹrẹ iṣẹ nile Oloye Bademọsi, iyẹn ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu to kọja, lo ba kiṣinni wọ inu yara oloye naa, ero rẹ si ni lati ji dukia baba naa ko.
Lasiko naa ni wọn ni iyawo Oloye Bademosi, iyẹn Abilekọ Ẹbunọla Bademọsi, ti lọ si Banki Polaris, to wa laduugbo Falọmọ, niluu Eko.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe wi, lẹyin ti Sunday wọ yara naa tan lo ti oloye yii lu ori bẹẹdi rẹ, o si sọ fun un pe ki i ṣe pe oun waa pa a o, iyẹn ni oloye naa si fi bi i leere nnkan ti o fẹ, ọmọkunrin naa si ni owo loun n wa.
Sunday jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe lẹyin ti Bademọsi sọ fun oun pe ko si owo nile, oun fi aṣọ so o lọwọ ati ẹsẹ, oun si gbe e silẹ latori bẹẹdi to wa. O ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe ṣe ni oloye naa ta oun nipaa, nigba naa si ni ọbẹ ti oun ti fi pamọ si abẹ aṣọ oun ja bọ lojiji. O ni oloye naa ja raburabu lati mu ọbẹ yii nilẹ, ṣugbọn oun fi ọrọ naa ṣe ẹni ba yara loogun i gbe, oun yawọ lati mu un ju u lọ. Ọmọkunrin naa sọ pe nibi ti oloye naa ti n lọ ọbẹ mọ oun lọwọ ni ọbẹ naa ti gun un.
Sunday ni nigba ti oun n gbiyanju lati jade kuro ninu yara naa ni oun ṣakiyesi pe oloye naa tun n gbiyanju lati fi ọbẹ yii gun oun, ṣugbọn oun ta a nipaa, o si ṣubu lulẹ. O ni lẹyin eyi loun mu ọbẹ naa toun tun fi gun un daadaa nigbaaya. Ọmọkunrin naa jẹwọ pe nigba ti oun pa a tan ni oun wọ inu baluwẹ oloye naa lọ, ti oun si sọ aṣọ ti oun fi maa n se ounjẹ ti oun so mọ ọrun (apron), ti ẹjẹ wa lara rẹ ati ọbẹ naa nu sibẹ. Sunday ni ojiji loun gbọ ti ẹnikan kanlẹkun kiṣinni ile naa, ara si fun oun pe o ṣee ṣe ko jẹ iyawo oloye naa, idi niyẹn toun fi gba ọna to wọ palọ sa jade.
Atẹjade naa sọ pe ọdẹ ile yii, Nura Mohammed, nigba to ṣakiyesi pe niṣe ni Sunday n gbọn, to si n kanju lati jade, bi i leere ibi to n lọ, to fi n kanju bẹẹ, esi ti o fọ fun un ni pe iyawo ọga lo ran oun niṣẹ.
Lẹyin ti Sunday pada si igboro, o ri awọn kan ti wọn n ko simẹnti wọ inu ọkọ tirọọki kan, ni o ba ran wọn lọwọ lati ko o, awọn ni wọn si fi ọkọ tirọọki naa gbe e de ilu Ondo lọfẹẹ, lẹyin naa ni dirẹba ọkọ yii tun fun un ni ẹẹdẹgbẹta Naira, lati fi dupẹ lọwọ rẹ nitori iranwọ to ṣe fun un.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ni iyawo oloye naa fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti. Iwadii awọn ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe Oloye Bademọsi pe iyawo rẹ lori foonu, to si sọ fun un pe Sunday ja wọ yara oun, awọn ọlọpaa si ri ẹri aridaju pe inu agbara ẹjẹ ni wọn ba oloye naa.
Ọjọ keji, oṣu yii, ni wọn mu Sunday, niluu Ondo, wọn si ba foonu Samsung oloye naa lọwọ rẹ. Awọn ọlọpaa sọ pe ẹkun kikoro ni ọmọkunrin naa sun lẹyin ti awọn fi fidio gbogbo iwa to hu naa han an.
Lẹyin ti awọn ọlọpaa mu un, wọn da a pada siluu Eko, nibi ti wọn ti gbe e pada sile oloye naa, ti wọn si ni ko fi ilana to gba pa oloye naa han awọn. Ṣa, wọn ti ko awọn ẹri ti wọn ri nibi iṣẹlẹ yii fun ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran nilana imọ sayẹnsi ti wọn n pe ni (Forensic), fun iwadii to peye lori rẹ. Wọn ni ayẹwo ti awọn ṣe si oku oloye naa fihan pe tan-an-na ọna-ọfun rẹ (lungs), ati aya jija lojiji (Mutiple sharp force trauma to the chest), wa lara nnkan to ṣeku pa a.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa sọ pe iwadii awọn fidi ẹ mulẹ pe awọn afurasi mẹrin kan ti awọn ti mu tẹlẹ, Kofi Friday, Agbeko Ayenahin, Salisu Hussein ati Nura Mamudu ko lọwọ ninu iwa ọdaran naa rara.
Imohin Edgal sọ pe laipẹ lawọn yoo fi awọn eeyan yii silẹ, ti wọn yoo si wa ẹni to le ṣe oniduuro wọn, nitori o tun ṣee ṣe ki awọn nilo wọn lasiko ti iwadii ba tun n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii. O ni laipẹ ni Sunday yoo foju ba ile-ẹjọ.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.