Eyi ni bi Pasitọ Fadairo ṣe bo ṣe jajabọ lọwọ awọn agbenipa

Spread the love

Bisi Adesoye, Ileṣa

Ori ko Pasitọ Ẹniọla Fadairo yọ ni ojubọ awọn agbenipa kan ti wọn lo wa lagbegbe Ipetu-Ijẹṣa, nijọba ibilẹ Oriade, ni ọsẹ to kọja yii, ṣugbọn awọn obinrin mẹfa mi-in ṣi wa ninu igbekun awọn ọdaju ẹda naa, iyẹn bi wọn ko ba ti i yẹju wọn bayi.

Nigba ti Fadairo n ṣalaye lori bo ṣe ko sọwọ awọn agbenipa naa, o ni oun wọ ọkọ kan ti akọle ile ijọsin wa niwaju rẹ ni ilu Ikire lati lọ si ilu Akurẹ, toun si ro pe ọkọ awọn olujọsin ni. O ni oun ba awọn obinrin mẹfa ninu ọkọ naa.

Ọkunrin naa ni mẹkaniiki to n maa n ba oun tun mọto oun to bajẹ ṣe loun fẹẹ lọọ pe l’Akurẹ nitori mọto naa tun ti bajẹ si agbegbe Ikire.

O ni bi awọn ṣe de agbegbe Ipetu-Ijeṣa ni ọkọ naa ya biri lojiji sinu igbo, ti awakọ naa sọ pe oun fẹẹ sare ja awọn ẹru kan toun ko siwaju ọkọ si itosi kan ni, pe ki awọn ma binu.

Akiyesi mi-in ti pasitọ yii ni oun ṣe ni pe lasiko ti ọkọ yii ya, awọn obinrin mẹfẹẹfa naa ti sun lọ fọnfọn, ko si sẹni to taji ninu wọn pẹlu bi awakọ naa ṣe n sọrọ.

O ni ọkọ naa ko duro titi to fi rin bii ibusọ mẹwaa de abule kan, nibi ti ojubọ naa wa, ibẹ si ni wọn to o jẹ ki oun ati awọn obinrin mẹfa naa sọkalẹ.

O ṣalaye pe bi wọn ṣe n ko awọn wọle ni awọn ti n wo awọn oku eeyan mẹrin kan nilẹ nibi tawọn n gba kọja, o jọ pe wọn ṣẹṣẹ pa wọn ni bo tilẹ jẹ pe oriṣiiriṣii oorun buruku lo gba agbegbe naa kan, o ni bẹẹ loun bẹrẹ si i fọkan gbadura kikankikan pe ki Ọlọrun jọwọ, doola ẹmi oun, tawọn obinrin tojora ti mu naa si bu sẹkun kikoro ni tiwọn.

O ni bi alakooso ojubọ na ṣe jade wa lo dojukọ oun to bẹrẹ si i kilọ pe ki oun kọpureeti pẹlu awọn. O ni o ya oun lẹnu bo ṣe je pe oun gan-an lo dojukọ. Ko pẹ ti ọkunrin  yii wọle lo tun jade, to paṣẹ fun dẹrẹba lati gbe oun kuro ni ojubọ naa. O ni oun kọkọ ro pe wọn n lọọ pa oun nibomi-in ni, afi bi wọn ṣe lọọ ja oun danu silẹ si agbegbe Ekiti, ki oun too ri ọlọkada kan to gbe oun de ilu Ekiti, nibi ti oun ti pada si ilu Akurẹ lọdọ mẹkaniiki oun, ti oun si ṣalaye ohun to toju oun ti ri fun un.

Nigba ti ALAROYE ṣebẹwo sọdọ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, DSP Fọlaṣade Odorọ, lati beere nipa ọrọ yii, o sọ pe oun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa, o si ṣeleri pe oun yoo gbe igbesẹ lati ṣewadii.

O ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun yoo ṣawari ojubọ awọn agbenipa naa, awọn yoo si foju wọn wina ofin tọwọ ba ti tẹ wọn.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.