Eyi ni bi eto isinku Baba Sala yoo se lo

Spread the love

Awọn mọlẹbi Apostle Moses Ọlaiya Adejumọ ti gbogbo eeyan mọ si Baba Sala ti kede eto isinku baba alawada naa, ẹni to jade laye lọjọ keje, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn aburo baba naa ti Alaroye ba sọrọ nile wọn nilu Ileṣa, Apostle Ọlabọde Adejumọ, ṣe ṣalaye, wọn ti gbe igbimọ kan ti Oloye Oyewọle Olowomojuọrẹ, Ọmọọba Sunday Adegẹye ti gbogbo eeyan mọ si King Sunny Ade, ati ọkan lara awọn ọmọ baba, Yẹmi Adejumọ, kalẹ lati ṣe eto naa bo ti tọ.

Lọjọ kẹta, oṣu kejila, ọdun yii, ni titẹ-oku nitẹẹ ẹyẹ yoo bẹrẹ ni National Theatre, niluu Eko, wọn yoo si tun ṣe bẹẹ ni Cultural Center, niluu Ibadan, lọjọ kẹrin, oṣu kejila, iyẹn Tusidee.

Wọn yoo kọkọ tẹ baba nitẹ ẹyẹ laaarọ ọjọ Wẹsidee lori papa iṣere Osogbo City Stadium, niluu Oṣogbo. Isin orin onigbagbọ yoo si waye nirọlẹ ọjọ naa ninu ijọ C&S Movement, Idasa, nilu Ileṣa.

Isin alẹ onigbagbọ yoo waye ni Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu kejila, nigba ti wọn yoo ṣe isin ikẹyin fun Baba Sala lọjọ kẹfa, oṣu kejila, kan naa ninu ile ijọsin rẹ ni Idasa, ko too di pe awẹjẹwẹmu yoo waye nibi ti wọn yoo kede laipẹ.

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.