Eyi ni bi awọn alagbara aye ṣe le Ladọja kuro ninu ẹgbẹ ADC

Spread the love

Ki i ṣe iroyin mọ bayii pe gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Sẹnitọ Rashidi Ladọja ti fi ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), silẹ lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party (ZLP), ṣugbọn ohun to n le agba ijoye ilẹ Ibadan naa kiri yẹ ni sisọ

 

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ni Ladọja fi ẹnu ara ẹ kede pe ẹgbẹ oṣelu ZLP loun n ṣe bayii. Igbesẹ ọhun lo si fopin si gbogbo awuyewuye ati ahesọ to n lọ nipa inu ẹgbẹ oṣelu ti agba oṣelu yii wa gan-an.

 

Osi Olubadan ilẹ Ibadan yii sọ pe nitori pe awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu ADC ko fi ibẹru Ọlọrun pin ipo oṣelu lẹkun idibo Ibarapa, eyi to ko ijọba ibilẹ Kajọla, Isẹyin, Itẹsiwaju ati Iwajọwa sinu lo jẹ ki oun pin gaari pẹlu wọn.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, gbogbo wa la mọ ohun to ṣẹlẹ lẹyin ta a kede orukọ oludije dupo gomina ẹgbẹ yẹn. Awọn eeyan n pariwo pe iṣẹ ọwọ Ladọja ati Kọleoṣo ni, ṣugbọn awọn ẹni aifojuri lo pọ ninu awọn to n paṣẹ awọn nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ ADC, ko si ẹni to ri wọn soju. Iyẹn ni pe bo ṣe wu ki ohun ti wọn ṣe buru to, ko si ẹni to le yẹ wọn lọwọ ẹ wo.

 

“A ti wa lori ẹ tipẹ, ireti wa tẹlẹ ni pe a maa ri i yanju, ṣugbọn wọn ko jẹ ka ri i yanju. Eyi to da nnkan ru ni ti ipo igbakeji gomina, wọn fi tulaasi yan igbakeji fun oludije dupo gomina ẹgbẹ yẹn (Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹhin). Nigba ti emi fẹẹ dibo ki n too ṣe gomina, emi ni mo mu Akala funra mi gẹgẹ bii igbakeji mi, ki i ṣe pe awọn kan lo yan an le mi lori.

 

“Nigba ti mo ka iroyin yẹn lori ẹrọ ayelujara, mo pe Lanlẹhin, mo ni nigba wo lẹ pinnu lori ẹni ti wọn fa kalẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ gẹgẹ bii oludije dupo gomina, o loun naa ko mọ nipa ẹ. Mo pe Babalaje (Oloye Michael Kọleoṣo), oun naa ni wọn o fi to oun leti. Nnkan ti wọn tun waa fi ba ọrọ yẹn jẹ ni pe ki i ṣe ibi to yẹ ki wọn ti mu igbakeji gomina ni wọn ti mu un.

 

“Mo ni mi o ni iṣoro pẹlu ẹni tẹ ẹ fa kalẹ lati ṣe igbakeji gomina, ṣugbọn ọna tẹ ẹ gba mu un ni ko daa. ijọba ibilẹ Kajọla, Isẹyin, Itẹsiwaju ati Iwajọwa ni wọn jọ maa n fa ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin kalẹ laarin ara wọn, ọmọ Isẹyin si lẹni ti wọn fa kalẹ. Bakan naa, Isẹyin ati ijọba ibilẹ Itẹsiwaju ni wọn jọ wa ni ẹkun idibo kan naa lati fa eeyan kan kalẹ fun ipo ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, ọmọ Isẹyin ni wọn tun fa kalẹ fun ipo yẹn. Nigba ti wọn tun waa maa yan ondupo igbakeji gomina, ọmọ Isẹyin yii kan naa lo tun jẹ. Ṣe ko yẹ ki awọn Itẹsiwaju atawọn yooku ri nnkan kan ni?

 

Loootọ, ayanfẹ mi ni Lanlẹhin, oun ni mo ṣiṣẹ fun lati dupo gomina lorukọ ẹgbẹ ADC, ṣugbọn mo ri i pe pẹlu bi awọn to n gbe ikọkọ paṣẹ ẹgbẹ yẹn ṣe n ṣe e yii, a o le jawe olubori ninu idibo. Idi ti mo ṣe kuro nibẹ niyẹn. bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, ZLP lẹgbẹ mi, ti Amofin Ṣarafadeen Alli lemi atawọn alatilẹyin mi si n ṣefun ipo gomina ipinlẹ yii.”

 

Bakan naa lawọn alatilẹyin agba oṣelu nni, Oloye Michael Kọleoṣo, ti pinnu pe awọn paapaa ko ni i ba ẹgbẹ oṣelu ADC da nnkan pọ mọ nitori wọn ko fi tọga awọn ṣe.

 

Ninu ipade ti wọn ṣe niluu Ṣaki lopin ọsẹ to kọja ni wọn ti sọ ipinnu wọn ọhun di mimọ. Wọn ni awọn ko ni i ṣe ẹgbẹ ADC mọ, afi ti awọn adari ẹgbẹ naa ba fun Kọleoṣo lanfaani lati lọwọ ninu bi wọn ṣe maa fa oludije fun ipo igbakeji gomina lorukọ ẹgbẹ naa kalẹ.

 

Ta o ba gbagbe, eeyan bii mẹtala lo dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC ki Ladọja ati Kọleoṣo too ja fitafita lati ri i pe Sẹnetọ Lanlẹhin ni wọn fa kalẹ. Ṣugbọn ni bayii ti Ladọja ti tun kuro ninu ẹgbẹ naa, Amofin Alli to jẹ ọkan ninu awọn to ba Lanlẹhin fori gbari ninu idije naa ni agba ijoye yii tun gbé pọ̀n bayii.

 

Lọsẹ to kọja ni Lanlẹhin ati Alli pade nile Ladọja l’Ekoo, ti baba naa si sọ fun awọn mejeeji pe ki wọn ṣe ara wọn loṣuṣu ọwọ lati ri i pe wọn gbajọba mọ ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba ipinlẹ Ọyọ bayii lọwọ. Ṣugbọn pẹlu inu ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ti wọn wa yii, ọna ti wọn fẹ gbe kinni ọhun gba ko ti i ye ẹnikẹni.

 

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.