Ẹya ara eeyan ti wọn ṣi tutu ni wọn ba lọwọ Aafaa Mustapha.

Spread the love

Bo tilẹ jẹ pe ipinlẹ Eko ni wọn ti foju wọn han, ipinlẹ Ogun ni awọn eeyan kan tawọn ọlọpaa Eko mu fun nini ẹya ara eeyan lọwọ ti ṣe iṣẹ ibi naa, ki wọn too foju wọn han l’Onikan.

Ọga ọlọpaa to n ṣoju ẹkun Eko ati Ogun, AIG Lawal Shehu, to foju awọn ọdaran naa lede ṣalaye pe mẹta ninu awọn tọwọ tẹ naa ni wọn jẹ aafaa. O ni lọjọ kẹwaa, oṣu kejila yii, ni olobo ta awọn ọlọpaa pe ọkunrin kan ti wọn n pe ni Aafaa Mustapha atawọn mẹta kan ko niṣẹ meji ju ki wọn maa lọọ hu oku lọ ni agbegbe Iṣabọ, l’Abẹokuta. Wọn yoo si ta ẹya ara awọn oku naa fawọn oniṣe ibi bii tiwọn.

Pẹlu iṣẹ iwadii to jinlẹ, ọwọ ba aafaa naa atawọn mẹta yooku ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi yii. Awọn ọlọpaa sọ pe ẹya ara eeyan bii ọkan atawọn mi-in ti wọn ṣi tutu lawọn ba lọwọ wọn.

Ki wọn too mu wọn ni wọn ti kọkọ nawọ gan ọmọkunrin kan ti ọjọ ori ẹ ko ju ogun ọdun lọ, ẹya ara eeyan ti wọn ṣẹṣẹ pa ni wọn ri gba lọwọ tiẹ naa nipinlẹ Ogun kan naa.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.