Ẹwọn oṣu mẹta ni Kayọde ati Najeem n lọ *Lati Ondo ni wọn ti lọọ ji ewurẹ l’Ejigbo

Spread the love

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki baba ẹni ọdun mejidinlọgọta kan, Kayọde Bashiru, ati Ọlawale Najeem, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn lọọ fi aṣọ penpe roko ọba fun odidi oṣu mẹta lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan wọn.

Lati ilu Ondo la gbọ pe awọn mejeeji ti wa si Ejigbo, nipinlẹ Ọṣun, wọn si ji iya-ẹran nla nla mẹwaa gbe, nigba ti wọn de agbegbe Abere, niluu Oṣogbo, lasiko ti wọn n pada lọ lọwọ awọn agbofinro tẹ wọn.

Wọn beere ibi ti wọn ti ri ewurẹ yii, wọn ko si le dahun daadaa ni wọn ṣe taari wọn si agọ ọlọpaa. Lẹyin iwadii ni wọn jẹwọ pe ṣe lawọn ji awọn ewurẹ naa gbe, idi si niyi ti wọn fi foju bale-ẹjọ.

Lọjọ ti wọn kọkọ fara han ni kootu, Agbefọba to n ṣe ẹjọ naa, Abiọdun Fagboyinbo sọ fun kootu pe ni nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ni ọwọ tẹ wọn lẹyin ti wọn ji awọn ewurẹ naa gbe.

Nigba ti akọwe kootu beere boya wọn jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan wọn, kia ni wọn sọ pe awọn jẹbi, idi niyi ti agbẹjọro wọn, Nnajite Okobie, fi rọ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo wọn nitori pe wọn ti kabaamọ iwa ti wọn hu, ati pe ọpọ ẹbi ati ara lo n woju wọn fun ati-jẹ.

Lasiko ti Onidaajọ Rofiat Ọlayẹmi fẹẹ gbe idajọ rẹ kalẹ lo beere lọwọ agbefọba pe awọn ewurẹ mẹwẹẹwaa naa da gẹgẹ bii ẹri, ṣugbọn Fagboyinbo sọ pe awọn ti ta wọn.

Adajọ beere idi ti wọn fi ta awọn ewurẹ ọhun, Fagboyinbo ṣalaye pe wọn ti n ṣaisan lo jẹ kawọn gba iwe lati kootu lati ta wọn. O sọ siwaju pe ẹgbẹrun mẹsan-an Naira lawọn ta awọn iya ewurẹ mẹwẹẹwa.

Onidaajọ Ọlayẹmi beere pe owo ọhun da, agbefọba ni oun ko ko owo naa wa sile-ẹjọ, nitori idi eyi, adajọ ni oun ko le gbe idajọ oun kalẹ lọjọ naa, o sun un si ọjọ kẹta, iyẹn ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ, ọdun yii, o si paṣẹ pe ki agbefọba ko owo naa wa.

Lọjọ idajọ, Fagboyinbo sọ fun kootu pe oun ti ko owo naa wa, lẹyin naa ni adajọ paṣẹ pe ki wọn lọọ san an si asunwọn ile-ẹjọ.

Ni ti awọn olujẹjọ mejeeji, Onidaajọ Ọlayẹmi sọ pe ki wọn lọọ ṣe faaji lọgba ẹwọn fodidi oṣu mẹta tabi ki ẹni kọọkan wọn san ẹgbẹrun marun-un Naira gẹgẹ bii owo itanran.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.