Ẹwọn ni Samuel yoo ti ṣọdun keresi, ọlọpaa lo foju jọ Boko Haram

Spread the love

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti n’Ileṣa, B.O Awosan, ti paṣẹ pe ki ọmọ orilẹ-ede Cameroon kan, Samuel Umoru, lọọ ṣẹwọn oṣu meji lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an, ati bi agbẹnusọ ọlọpaa ṣe rojọ tako o pe o foju jọ Boko Haram, bẹẹ naa lo si n huwa bii awọn alakatakiti ẹsin naa. Eyi ṣẹlẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.

Samuel to jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn la gbọ pe o ji aṣọ alaṣọ ka lori ibi ti wọn sa a si, awọn eeyan ka a mọ ibi to ti n huwa laabi naa, wọn si pariwo ole le e lori ko too sa mọ wọn lọwọ. Bẹẹ lo ja wọ inu ile kan lai mọ ẹnikẹni nibẹ, bo si ṣe debẹ lo ti sare gun ori aja ile ọhun lọ ki ọwọ awọn aladuugbo ma baa tẹ ẹ.

Awọn aladuugbo yii pada mu Umoru, wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ lati gbe e wa si kootu. Iroyin ohun ti ọkunrin naa ṣe lasiko ti wọn n le e lo mu ki agbẹnusọ ọlọpaa, Ọgbẹni Jimoh, lo n wo bii Boko Haram, iwa rẹ si jọ tiwọn.

Inspẹkitọ Jimoh ṣalaye siwaju si i pe awọn alakatakiti ẹsin naa ti ya wọ Ileṣa rẹpẹtẹ latari bi awọn ologun Naijiria ati ologun orilẹ-ede to sun mọ wọn ṣe n ran wọn lọwọ lati ṣẹgun awọn Boko Haram yii. O si ṣee ṣe ki Umoru wa laarin wọn, paapaa nigba ti ko lẹni kan to n bọ waa ba n’Ileṣa.

Eyi lo mu Adajọ Awosan paṣẹ ẹwọn oṣu meji fun Samuel, lati fi kọ ọ lọgbọn pe ko daa ko maa mu nnkan ẹlomi-in mọ tiẹ.

 

 

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.