Ẹwọn ni Lekan to ji paali ọti mẹrin l’Abẹokuta yoo ti ṣe Keresi ati ọdun tuntun

Spread the love

Adajọ T.O Ọbasanjọ, ti kootu kẹrin n’Iṣabọ, Abẹokuta, ti paṣẹ pe ki Lekan Famuyiwa, ọmọ ogun ọdun, ṣi wa lọgba ẹwọn Ibara lati ọjọ kẹtala, oṣu kejila, titi di ọjọ kẹjọ, osu kin-in-ni, ọdun to n bọ, nitori ọti paali mẹrin ti wọn fẹsun kan an pe o ji.

Ọjọbọ, ọjọ kẹtala, oṣu yii, ni igbẹjọ waye lori Lekan to n gbe lẹgbẹẹ Sacred Heart Hospital, Lantoro, Abẹokuta. Agbefọba, Idowu Ogunlẹyẹ, fi to kootu leti pe laarin ọjọ kẹrin, oṣu kejila, si ọjọ kẹwaa, oṣu yii, ni Lekan ji paali ọti mẹrin ti ọti wa ninu wọn.

O ni ile ọti to ti n ba wọn taja laduugbo Oke Abẹtu, lo ti dọgbọn ji awọn ọti naa ko, eyi ti i ṣe ọja obinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ogundeyi Bọlanle.

Awọn ọti to ji naa gẹgẹ bi agbẹnusọ ijọba ṣe wi, ni: Paali Gulder marun-un, ẹgbẹrun mẹtadinlogun aabọ Naira (17,500) lo ni iyẹn jẹ. Paali Goldeberg mẹta, ti i ṣe ẹgbẹrun mẹjọ ati ẹẹdẹgbẹrin Naira ( 8,7000), paali Trophy mẹfa, ti i ṣe ẹgbẹrun meje ati irinwo Naira (7,400), pẹlu paali ọti Heinekens marun-un ti iyẹn jẹ ẹgbẹrun mọkandinlogun Naira (19,000).

Yatọ si awọn wọnyi, ofifo igo ọgọrun-un kan ati mejila ni wọn ni Lekan tun ji, nigba ti wọn si ṣi gbogbo owo ọhun pọ, agbefọba Ogunlẹyẹ sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan ati mẹrinlelaaadọrin Naira (174, 000), ni gbogbo ẹ.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Lekan loun ko jẹbi pẹlu alaye.

Adajọ T.O Ọbsanjọ to gbọ ẹjọ rẹ faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (300,000), pẹlu oniduuro meji niye kan naa, bi ko ba ri awọn eto naa ṣe, ki wọn taari ẹ si ọgba ẹwọn Ibara.

Ko si oniduuro kankan to yọju fun ọmọ yii, bẹẹ lo ṣe padanu beeli naa, ti wọn si gbe e lọ sọgba ẹwọn Ibara, nibi ti yoo ti ṣe Keresi ati ọdun tuntun.  

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.