Ẹwọn n run nimu Pasitọ Taiwo, ọkunrin lo fipa ba lo pọ l’Ekoo

Spread the love

Ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin ni Pasitọ Taiwo Ọpaleke, ṣugbọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, lo foju ba kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, wọn ni o fipa ba ọmọdekunrin kan ti ko ju ọdun mẹẹẹdogun lọ sun, eyi to tako ofin ilẹ wa. Ẹsun ifipaba ọkunrin lo pọ ni Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, (NAN), sọ pe wọn fi kan an niwaju Adajọ B.O Ọṣunsanmi.

Agbefọba to gbe e lọ si ile-ẹjọ, ASP Ezekiel Ayọrinde, ṣalaye pe ọjọ kẹrinla, oṣu to kọja, ni Taiwo huwa naa nile rẹ, wọn ni ṣe lo gba idi ọmọ naa mu, to si ki kinni abẹ rẹ bọ ọ niho idi. Agbefọba naa ni Pasitọ Taiwo ti kọkọ ni ki ọmọ naa wa si ile oun, ṣugbọn ọmọ yii sọ fun awọn obi rẹ pe oun kọ lọ.

Nigba ti Taiwo reti rẹ ti ko ri i lo lọọ ka a mọ ile awọn obi ẹ, to si ni oun fẹ ki ọmọ naa tẹle oun dele. Lẹyin to mu ọmọkunrin yii dele lo ṣe e bii ọṣẹ ṣe e ṣoju, ko too fi i silẹ pe ko maa lọ. Ọmọdekunrin yii lo royin ohun toju rẹ ri fun ẹgbọn rẹ, ẹni naa lo si fi to ọlọpaa leti ti ọrọ fi ẹ fi kootu.

Adajọ B.O Ọṣusnsanmi ko gba ẹbẹ Taiwo, o ni ki wọn ṣi maa mu un lọ si ọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹfa, oṣu keji, ọdun yii, ti igbẹjọ rẹ yoo maa tẹsiwaju.

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.